Kàyéèfì! Halima ní ìpèníjà ojú, àmọ́ iṣẹ́ alásè ló yàn láàyò
Halima Usman Jubrin jẹ ọdọbinrin to ni iran to ga pupọ, ṣugbọn ipenija oju jẹ oun kan to ni nitori pe ko le riran.
Amọṣa, Halima ko jẹ ki ipenija airiran yii di i lọna afojusun rẹ lati jẹ akọṣẹmọṣẹ alase igbalode.
Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Halima, aisan corneal ti wọn bii pẹlu lo gba oju lọwọ rẹ.
O ni igba ewe loun ti ni ifẹ si ounjẹ sise, ti awọn iya oun ati ẹgbọn oun si maa n ran oun lọwọ lati da ina nigba naa.
Bawo lo ṣe le n dana lairiran?

Haliman ni oju ita ni ko si, oju inu oun duro deede. Nitorina o ni oju inu loun maa n lo fi da inaounjẹ gbogbo ti oun n se.
Oun si maa n lo awọn ẹya ara oun yoku lati mọ iyatọ laarin awọn elo gbogbo ti oun nlo fi dana.
“Mo maa n fi ọwọ kan wọn, mo maa n gbọ oorun wọn , mo dẹ tun maa n tọ wọn wo lori ahọn.
Ni ọdun 2022 ni Halima bẹrẹ si ni fi awọn fidio ase rẹ si ori ayelujara.
O ni oun fẹ ki gbogbo awọn eeyan o mọ pe ko si aleebu kankan ninu jijẹ akanda.
Ohun gbogbo ti abarapa n ṣe naa niakanda ẹda naa le ṣe.















