Ìjọba Singapore kéde ìwé ẹ̀rí tí iye owó rẹ̀ lé ní ₦81m fún ẹnikẹ́ni tí yóò bá ra ọkọ̀ tuntun

Oríṣun àwòrán, getty images
Lati di ẹni to n ra ọkọ nla ti yoo gba iwọ ati gbogbo mọlẹbi rẹ lorilẹ-ede Singapore bayii, o gbọdọ ni owo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹrindinlaadọjọ owo dọla ti wọn n na lorileede naa, (S$146,000).
Owo yii lo jẹ $106,619 owo dọla ilẹ Amẹrika ati £87,684 owo ilẹ yuroopu.
Owo naa lo jẹ miliọnu mọlọkanlelọgọrin le diẹ owo naira (81,122,000).
Ọdun 1990 ni ijọba Singapore fi iwe ẹri naa ti wọn pe ni ‘Certificate of Entitlement’ lọlẹ.
Wọn kede pe gbogbo ẹni to ba fẹ ra ọkọ nibẹ yoo lo iwe ẹri ọhun fun ọdun mẹwaa gbako, ko to di pe wọn tun gba iwe miran.
Igbesẹ yii lo waye lati din bi awọn eeyan ṣe n lo ọkọ ku, lọna ati gbogun ti sunkẹrẹ ati fakẹrẹ ọkọ loju popo.
A gbọ pe ọsẹ meji-meji ni ijọba maa n gbe iwe yii jade f’awọn eeyan ni owo pọọku, lati le maa mojuto bi awọn eeyan ṣe n gba a.
Pẹlu gbogbo owo ori ati iwe aṣẹ ori mọto to n wọle s’orilẹede naa, eto yii ti jẹ ki Singapore jẹ orilẹ-ede to ṣoro julọ lagbaye lati ra ọkọ.
Fun apẹẹrẹ, lati ra ọkọ Toyota Camry Hybrid tuntun, o gbọdọ ni owo dọla Singapore ti ko din ni S$250,000, ti owo iwe ẹri COE naa si ti ba a wa, eyi ti wọn sọ pe o gbowo lori ju iye ti wọn n ta ọkọ ọhun lọ ni Amẹrika.
A gbọ pe oriṣiriṣi iwe ẹri COE yii lo wa fun awọn ọkọ kekeke, kẹkẹ maruwa ati awọn ọkọ ti wọn fi n ṣe kabukabu.












