Ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa ìkọlù láàrín Hamas àti Israel

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ikọ agbebọn Palestinian, Hamas ti ṣe ikọlu si orilẹede Isreal, wọn ya wọ awọn agbegbe kan ni Gaza, ti wọn si ṣeku pa ọpọ eeyan, ti wọn si tun ji awọn miiran gbe lọ.
Eyi ni awọn nnkan ti o ni lati mọ nipa ikọlu naa ati awọn eeyan to wa ni di rẹ.
Ki ni itumọ Hamas?
Hamas jẹ ikọ agbebọn Palestine to n dari Gaza. Hamas ti leri pe awọn ko ni jawọ ikọlu si Israel, ti awọn mejeeji si ti ja ọpọlọpọ ogun lati igba ti wọn ti gba isakoso Gaza lọdun 2007.
Laarin awọn ogun yii, wọn yi ado oloro tabi fun awọn ikọ agbebọn mii ni anfanni lati yin ado oloro si orilẹede Israel, ti wọn si tun ti ṣe ọpọlọpọ ikọlu alagbara. Israel, bakan naa ti ṣe ikọlu si Hames pẹlu ado oloro ati pẹ pẹlu ajọṣepọ Egypt wọn ti dena Gaza Strip lati 2007, nnkan ti wọn o waye nitori lati da bobo ara wọn.
Hamas ni apapọ, tabi ni Israel ri gẹgẹ bi ikọ agbebọn pẹlu orilẹede Amẹrika, ajọ European Union, Ilẹ UK pẹlu awọn orilẹede alagbara mii. Hamas ni Iran n ṣe atilẹyin fun, ti wọn si n pese ohun ija ati idanilẹkọ fun.
Ki ni a n pe ni Gaza Strip?
Gaza Strip jẹ ala oni kilomita mọkanlelogoji lo wa laarin Israel, Egbpt ati Okun Mediterranean. Eeyan toto milọnu meji lo n gbe ni bẹ, to si jẹ agbegbe ti ero pọju lagbaye.
Israel n dari oju ofurufu Gaza , ti n apa lori bi ọja ṣe n wọle jade ni ẹnu ala naa bakan pẹlu Egypr pẹlu ẹnu ala Gaza.
Ki lo fa ija laarin Israel ati Hamas?
Ija laarin Israel ati Hamas ti wa ti pẹ sugbọn ikọlu awọn agbegbọn yii lo waye lọjọ Satide lairo tabi ki kilọ saaju. Ogunlọgọ ado oloro ti Hamas ran si Isreal, ti ọpọ awọn ologun si yawọ wọle lati ẹnu ibode, ti wọn si wọle si awọn agbegbe Israel, ṣekupa ọpọlọpọ eeyan, ti wọn si tun ji ọpọ gbe lọ.
Israel na fọnu pada pẹlu ado oloro ofurufu, wọn ni awọn fi ransẹ si ibudo ologun ni Gaza
Ki lo le waye lọjọ iwaju?
Ọga ikọ agbebọn ologun Hamas, Mohammed Deif ti kesi awọn eeyan Palestinians ati awọn orilẹede Arab mii lati darapọ mọ wọn lori igbinyanju wọn lati le Israel kuro ni agbegbe wọn.
Ibeere ti ọrọ kan bayi ni boy awọn eeyan Palestin to wa ni ẹgbẹ omi West Bank ati ila oorun Jerusalem yoo gbọ si wọn lẹnu, gẹgẹ bi akọroyin BBC ni Jerusalem, Yolande Knell ṣe sọ.
Ko si aniani pe Israel ri apeere pe o seese ki ogun waye . Ọkan lara nnkan to le waye ni pe ogun le fa ikọ agbebọn miiran, Hezbollah wọlee.
Ileeṣẹ ologun Israel ti pa lasẹ pe ki wọn bẹrẹ igbanisisẹ awọn ologun ni kiakia. Bakan naa ni wọn ti pinnu lati kọlu Gaza lori ilẹ yatọ si pe bi wọn ṣe n ju ado oloro ranṣẹ sibẹ lọwọlọwọ.












