Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì mú ẹ̀mí aláboyún àti èèyàn 29 míì lọ ní Cameroon

Oríṣun àwòrán, MICHEL MVONDO/BBC
O kere tan, ọgbọn eeyan lo ti jade laye lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riri ‘landslide’ kan to waye latari ojo arọrọrada kan niluu Yaoundé, to jẹ olu ilu orilẹ-ede Cameroon.
Ileeṣẹ redio abẹle kan sọ pe ogoji eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ, ati pe ọpọ awọn eeyan mii ni wọn ṣi n wa wa bayii.
Agbara ojo to waye lẹyin ojo to rọ niluu ọhun mu ko nira fun awọn adoola ẹmi lati yọ awọn eeyan, eyii to mu ki awọn araalu naa maa fi ọwọ ara wọn fa oku jade ninu ẹrọfọ.

Oríṣun àwòrán, MICHEL MVONDO/BBC
Ojo naa to rọ mu ki odo Mefou ya lọjọ Aiku, eyii to bo awọn agbegbe to sunmọ odo ọhun mọlẹ.
Agbegbe Mbankolo, ti awọn ti ko rọwọ họri n gbe ni iṣẹlẹ naa pa lara julọ, ti awọn ile atawọn igi ọgẹdẹ to wa lagbegbe ọhun si n wu ti gbongbo.
Ọkan lara awọn to fara gba ninu iṣelẹ naa, Ymele Guy sọ fun BBC pe oun padanu ọmọ oun ninu iṣẹlẹ naa.
O ni “Oju mi lo ṣe, nigba ti mo n ṣi n sọ fun iyawo mi nipa bi iṣelẹ naa ṣe buru to ni emi atawọn ọmọ mi bẹrẹ si n ri laarin iṣẹju aaya.”
“Mo doola iyawo mi ati o kere tan, ọmọ mẹta.”
“Ojo naa gbe ọmọ mi kẹrin lọ... ojo lo gbe ọmọ naa lọ.”
Ẹlomiran ti ọrọ naa tun kan, Jouego Cathérine ni aburo oun ri si abẹ ilẹ naa pẹlu oyun ninu.
Iroyinni nnkan bi ile marundinlọgbọn ni ojo arọrọda naa gbe lọ.












