O ní ohun tí mo ń bá Peter Obi jà sí -Lamidi Apapa, alaga ẹgbẹ́ òṣèlú LP

Àkọlé fídíò, O ní ohun tí mo ń bá Peter Obi jà sí -Lamidi Apapa, alaga ẹgbẹ́ òṣèlú LP
O ní ohun tí mo ń bá Peter Obi jà sí -Lamidi Apapa, alaga ẹgbẹ́ òṣèlú LP
Aworan Apampa ati peter Obi

Oríṣun àwòrán, BBC/Peter obi

Ọkan lara awọn adari ẹgbẹ oṣelu Labour lorilẹede Naijiria, Alhaji Lamidi Apapa ti sọ pe ko si ipinya kankan lẹgbẹ oṣelu naa gẹgẹ bi awọn iroyin kan ṣe n gbe e.

O ni ohun to n waye laarin ẹgbẹ oṣelu LP ni pe oludari pe meji nibẹ.

“Ọkan gba lati tẹle ofin, ọkan ko gba lati tẹle ofin. Ti ẹni ti ko tẹle ofin ba ti kuro, awn eeyan a rii pe ẹgbẹ oṣelu Labour ko pe meji.”

Ohun to fa awuyewuye lẹgbẹ oṣelu Labour lẹyin ibo apapọ ọdun 2023 ni Naijiria

Alhaji Apapa ṣalaye siwaju pe ohun to fa awuyewuye lagbo ẹgbẹ oṣelu Labour party lẹyin ibo apapọ ọdun 2023 lorilẹede Naijiria, ni idajọ ile ẹjọ giga kan nilu Abuja to paṣẹ pe ki alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu naa nigba naa, Amofin Julius Abure atawọn mẹta miran dẹkun pipe ara wọn ni adari ẹgbẹ oselu Labour lorilẹede Naijiria.

Awọn oloye to ku ninu ẹgbẹ oṣelu naa gba pe ki oun maa ṣe akoso ẹgbẹ oṣelu naa di igba ti wọn ba yanju ọrọ.

‘Emi ati Peter Obi o ni ija kankan’

Alagba Apapa ṣalaye sii pe ko si gbungbungbun kankan laarin oun ati oludije ẹgbẹ oselu LP, Peter Obi.

O ni ilepa oun naa ki ẹgbẹ oṣelu LP ṣe akoso orilẹede Naijiria fun anfani ifidimulẹ ireti awọn to ni igbagbọ ninu ẹgbẹ oṣelu naa.

Amọṣa aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu LP naa ṣalaye siwaju sii pe ohun to mu ki awọn koro oju si iwa Peter Obi ni bi o ṣe tubọ n ba awọn ti ile ẹjọ yọ nipo ṣe pọ lasiko naa.

O ni ara ohun ti wọn n sọ fun oun nipe aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Tinubu loun n ṣe iṣẹ fun ti oun si ti ni ki wọn lọ mu ẹri wa.

O ṣalaye pe pe ohun ati Aarẹ Tinubu ko ni adehun tabi ajọṣepọ kankan lori eto oṣelu tabi idibo to kọja ni Naijiria.