Timipre Sylva kò ní ẹ̀tọ́ láti du ipò gómìnà ní Bayelsa – Ilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, @todaysplash
Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti paṣẹ pe oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Bayelsa, Timipre Sylva ko lẹtọọ lati du ipo gomina ninu eto idibo ti yoo waye lọjọ kọkanla, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii.
Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa, Demesuoyefa Kolomo lo tako bi ẹgbẹ ọhun ṣe fa Sylva kalẹ gẹgẹ bi oludije fun ẹgbẹ naa ninu iwe ẹsun ti nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/821/2023.
Ninu ẹsun naa lo ti rọ ile-ẹjọ lati ṣagbeyẹwo Sylva boya o lẹtọọ lati du ipo gomina ninu eto idibo to n bọ lọna yii abi ko lẹtọọ.
Eredi ipẹjọ naa ko ṣeyin pe Sylva ti ṣe gomina Bayelsa laaarin ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2007 si ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2008.
Bakan naa lo tun sọ pe Sylva ṣe gomina laaarin ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2008 si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2012, eyii to fi n sọ pe ọdun marun un gbako ni Sylva ti lo lori ipo gomina ipinlẹ naa ṣaaju.
Kolomo ni bi Sylva ba tun gbe apoti gomina, to si wọle, yoo tako iwe ofin ipo oṣelu orilẹ-ede Naijiria ti ọdun 1999, ti wọn ti ṣe agbeyẹwo rẹ, eyi to sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ lo kọja ọdun mẹjọ lori ipo gomina.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ adajọ Donatus Okorowo sọ pe Sylva yoo tako iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 bi wọn ba faaye gba a lati tun pada si ipo gomina, nitori pe ẹẹmeji ọtọọtọ ni wọn ti bura fun un gẹgẹ bi gominn to si lo ọdun marun un.
Okorowo ṣalaye pe Sylva yoo lo ju ọdun mẹjọ to wa ninu iwe ofin orileede Naijiria lọ ti wọn ba faaye gba a lati dije, to si tun wọle.
O ni awọn to ṣagbeyẹwo iwe ofin Naijiria sọ nibẹ pe ko si ẹni ti wọn yoo bura fun kọja igba meji, to si sọ pe awọn igun mejeeji lo gba wi pe igba meji ni wọn ti dibo yan Sylva.
Nigba to n ṣapejuwe idajọ ile-ẹjọ to ga julọ lorileede Naijiria, nipa ẹjọ Marwa ati Nyako wi pe ko si ẹni to gbọdọ lo kọja ohun ti iwe ofin sọ fun idi eyi, o ni bi wọn ba gba ọkunrin naa laaye, o tumọ si pe eeyan le gbe apoti ni iye igba to ba wu u.
A máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn – APC
Nigba ti wọn n sọrọ lori idajọ naa, igbimọ to n ri sọrọ ipolongo idibo gomina lẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Bayelsa sọ pe idajọ naa kii ṣe ohun ti wọn le bẹru tabi foya le lori, nitori pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun.
Alakoso eto iroyin ati ipolongo igbimọ naa, Perry Tukuwei ninu atẹjade to fi tako idajọ ọhun lọjọ Iṣẹgun ni idajọ ọhun kan waye lati gba ẹtọ araalu kuro lọwọ wọn ni.
O ni eredi iwadjọ ọhun ko ṣeyin pe nnkan ti foju han pe Sylva ni yoo jawe olubori nibi eto idibo ọhun.
O ni awọn ti fi to awọn agbẹjọro wọn leti lati pe ẹjọ kotẹmilọrun, pẹlu igbagbọ pe awọn yoo pada bori ninu idajọ ti yoo ba tun waye.
O ni “abala kọkandinlọgbọn ati ikẹrinlelọgọrin ninu iwe ofin eto idibo sọ pe ẹni to ba gbe apoti ninu eto idibo abẹle ninu ẹgbẹ oṣelu nikan lo lẹtọọ lati pe ẹjọ lati tako idibo to gbe adije wọle.
“Ẹjọ ti ẹnikan ti wọn pe ni Oloye Demesuoyefa Kolomo, ti kii ṣe ọmọ ẹgbẹ APC, ti ko si gbe apoti idibo gomina abẹle pe ko ni ẹsẹ kankan nilẹ ninu ọrọ yii.
“Abala 285 ninu iwe ofin orileede Naijiria faaye gba ẹgbẹ lati pe ẹjọ laaarin ọjọ mẹrinla ti idibo ba waye, ṣugbọn ẹjọ yii ni wọn pe lọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2023.”
“Eyii to jẹ pe ajọ eleto idibo INEC ti gbe orukọ oludije sipo gomina ipinlẹ Bayelsa, Imo ati Kogi jade lọjọ kejila, oṣu Karun un, ọdun 2023.












