Ìjọba Nàìjíríà ti dá ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ Israel dúró báyìí

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ajọ ti o n ri si irinajo lọ si ilẹ mimọ Israel ati Jordan ti da irinajo si orilẹede naa duro bayii latari ogun to bẹ silẹ laarin Israel ati Palestine lopin ọsẹ to kọja.
Ajọ naa ti kede pe oun ti fagile irinajo awọn ọmọlẹyin Kristi si Israel ati Jordan to yẹ ko waye lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹwaa oṣu Kẹwaa ọdun 2023 yii titi di ọjọ mii ọjọ ire.
Oludari eto ilanilọyẹ fun irinajo silẹ mimọ fun ajọ naa, Ọgbẹni Sunny Udeh sọ fun BBC pe ogun to bẹ silẹ naa ti ṣakoba fun erongba ajọ naa lori ati rinrin ajo lọ si ilẹ mimọ loṣu Kejila ọdun yii.
Ọgbẹni Udeh ni adura ajọ naa ni pe alaafia yoo jọba laarin Israel ati Palestine ki ọdun 2923 yii to pari.
Ko din ni ẹgbẹrun mejidinldogun awọn kristẹni ni Naijria to maa n rinrin ajo lọ si ilẹ mimọ ni Israel ati Jordan lọdọọdun.
Ajọ naa sọ pe oun yoo maa tẹsiwaju lati maa ṣe akiyesi ohun to n ṣẹlẹ ni orilẹede Israel nitori aabo ọmọ Naijiria lo jẹ ajọ naa logun.
Ẹwẹ, irinajo lati Naijiria si papakọ ofurufu ilu Tel Aviv ni Israel ṣi n lọ lai si idaduro rara bo tilẹ jẹ pe ogun n lọ lọwọ laarin Israel ati Palestine.
Lọjọ Abamẹta to lọ ni ileeṣẹ ologun Hamas ṣe ikọlu si orilẹede Israel ti awọn ọmogun rẹ si yawọ awọn awujọ to sun mọ ẹkun Gaza.
Ẹgbẹlẹgbẹ eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ ti wọn si ji ọpọ eeyan gbe, igbesẹ yii lo si ti mu ki Israel naa gbẹsan pẹlu jiju oriṣiriiṣi ado oloro si ẹkun Gaza.
Ijọba orilẹede Naijiria ti kepe orilẹede Israel ati Palestine pe ki wọn jẹ ki ogun o mi, ati pe ki wọn gba alaafia laaye nipa yiyanju aawọ to wa laarin wọn ni itubi-inubi.
Èèyàn tó lé ní 1,750 pàdánù ẹ̀mí wọn bí Israel àti Palestine ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí ara wọn

Kò dín ní ẹgbẹ̀rún kan ọmọ Israel tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn láti ọjọ́ Àbámẹ́ta tí ìkọlù ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wáyé láàárín orílẹ̀ èdè Palestine àti Israel.
Ilé iṣẹ́ Israel sí Amẹ́ríkà tó fi ọ̀rọ̀ yìí léde ní àwọn ènìyàn 3,418 míì ló farapa níbi ìkọlù náà.
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní orílẹ̀ èdè Palestine ti lé ní 750.
Àtẹ̀jáde kan láti Iléeṣẹ́ ètò ìlera ní Gaza èyí tí àwọn Hamas ń ṣe àkóso rẹ̀ ní ènìyàn 765 ló ti jáde láyé, tí àwọn 4,000 sì farapa.
Ìròyìn ní àwọn ará ilẹ̀ òkèrè méjì mìíràn tún pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù tí wọ́n ṣe sí agbègbè Eskhol.
Àjọ tó ń rí sí ètò ààbò ní Israel ní àdó olóró ń dún kíkankíkan ní Tel Aviv àti káàkiri Israel.


Oríṣun àwòrán, Reuters
Ṣáájú ni Hamas ti dúnkokò láti ṣe ìkọlù sí ìlú Ashkelon lẹ́yìn tí orílẹ̀ èdè Israel ṣe ìkọlù sí Gaza.
Àtẹ̀jáde kan tí Hamas fi sórí Telegram ní kí àwọn olùgbé agbègbè náà kó kúrò kí ó tó di aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́.
Wọ́n ní Israel kò ṣe ìkìlọ̀ kí wọ́n tó ṣe ìkọlù sí ìlú Khan Yunis ní alẹ́ ọjọ́ Ajé àti pé ojú títì ni àwọn ènìyàn ń sùn sí lẹ́yìn ìkọlù náà.
Musheir El-Farra, tó ń gbé ní agbègbè Sheffield ní UK sọ fún BBC pé àdó olóró tí Israel jù sí agbègbè àwọn se àkóbá fún ilé àwọn.
El-Farra ní kò dín ní ènìyàn mẹ́ta tó fi mọ́ àwọn ọmọdé mẹ́ta ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà.
Ó ní àwọn ìbátan òun méjì ló bá ìkọlù náà lọ àti pé ènìyàn mọ́kànlá ni òun pàdánù níní ìkọlù tó wáyé lọ́dún 2014.
Aṣojú Israel sí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, Gilad Erdan ní kò dín ní ọgọ́rùn-ún sí àádọ́jọ ènìyàn tó jẹ́ ọmọ Israel ni Gaza ti fi sí àhámọ́ láti ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Àjọ ọmọ ogun Israel ní àwọn ti bá díẹ̀ lára àwọn ẹbí àwọn tí wọ́n jí gbé náà sọ̀rọ̀.
Ismail Haniyeh, olórí ikọ̀ òṣèlú Hamas ní àwọn kò ní sọ̀rọ̀ lórí ìtúsílẹ̀ àwọn tó wà ní àhámọ́ àwọn àyàfi tí ìjà bá dópin.
Ó ní àwọn ti sọ fún gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn lórí àwọn tó wà ní àhámọ́ àwọn àti pé àwọn kò ṣetán láti sọ̀rọ̀ lórí wọn títí tí ogun yóò fi dópin.














