'Èmi Atiku Abubakar náà ni mo ń jẹ́ Sadiq Abubakar, mi ò yí ìwé ẹ̀rí mi rárá'

Aworan Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, X/atiku

Igbakeji aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria to tun jẹ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP lasiko idibo apapọ to kọja, Alhaji Atiku Abubakar ti jade lati kede pe iroyin ofege ni iroyin kan to n lọ kiri pe ayederu ni iwe ẹri girama ti oun nlo.

Atiku, ẹni to gba ẹnu agbẹnusọ rẹ, Oloye Dele Momodu sọrọ salaye loju opo ayelujara X rẹ bi ọrọ ṣe jẹ lori ọrọ iwe ẹri naa.

Atiku ni o ṣe koko ki oun salaye lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu APC fi ẹsun kan oun pe oun yi iwe ẹri girama ti oun gbe silẹ fun ajọ INEC.

APC fi ẹsun kan Atiku pe orukọ to wa lori iwe ẹri naa, Sadiq Abubakar yatọ si orukọ ti igbakeji aarẹ tẹlẹ naa n jẹ, iyẹn Atiku Abubakar.

Ninu alaye ti Dele Momodu gbe sita, o ni oun fi ọrọ naa to Igbakeji Aarẹ tẹlẹri leti, to si fesi ransẹ lori ẹsun naa.

O ni, “Ẹgbẹ oṣelu APC ti gbe awọn iroyin ẹlẹjẹ kan sori ayelujara, ti wọm tun fi ransẹ si mi lori ẹsun kan pe Ọga mi, Alhaji Atiku Abubakar yi iwe ẹri, ti mo si fi ọrọ naa to leti, to ti fesi si ọrọ baa: ‘Bẹẹni, mo lo Sadiq Abubakar lati joko fun idanwo Waec, lẹyin ti mo yege idanwo naa, mo lọ ileẹjọ lo bura pe emi Sadiq Abubakar naa ni Atiku Abubakar.

“Mo lọ ilẹ ẹkọ ABU gẹgẹ bi Atiku Abubakar, tri mo si yege gẹgẹ Atiku Abubakar . Wọn gba mi si ilẹeṣẹ ijọba apapọ ati ẹsọ ibode pẹlu orukọ Atiku Abubakar. Fun idi yii, ni bo ni mo ti yi iwe?’

Èmi ni mo bẹ Obasanjo láti má gba Eko lọ́wọ́ Tinubu - Atiku

Aworan Aarẹ Bola Tinubu ati Igbakeji aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu/ Atiku Abubakar

Igbakeji Aarẹ tẹlẹri, Atiku Abubakar ni o yẹ ki Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ma dupẹ lọwọ oun nitori oun ni rọ Aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijira, Olusegun Obasanjo lati ma gba ipinlẹ Eko lọwọ rẹ.

Obasanjo lo jẹ Aarẹ orilẹeede Naijiria lati ọdun 1999 si 2007 labẹ asia ẹgbẹ òṣelu Peoples Democratic Party ti Tinubu si jẹ Gomina ìpínlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Alliance for Democracy lasiko naa.

Lasiko to ba awọn akorọyin sọrọ niluu Abuja, Atiku ni irọ to jina si otitọ ni pe oun fi obẹ ẹyin jẹ iṣu Tinubu.

"Fun ẹyin ti ẹ ti dagba lati ranti ohun to waye lọdún 2003, PDP borí ni gbogbo ipinlẹ ni guusu ìwọ oorun lẹyin ipinlẹ Eko. Mo duro laarin oun ati Obasanjo pe, rara o le gba ipinlẹ Eko, fi silẹ, Obasanjo si fi silẹ.

"Ọpọlọpọ nnkan miiran lo waye ti n ko le sọ sugbọn iro to jina si otitọ ni pe mo dalẹ Tinubu."

'Nítori emi ati Tinubu jẹ ẹlẹsin kaa naa ni mo fi tako ko jẹ igbakeji mi lọdun 2007'

Atiku Abubakar ni Gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Eko fẹ jẹ igbakeji oun lasiko to n díje dupo fun ipo Aarẹ lọdun 2007 nitorí awọn jẹ ẹlẹsin kan na.

"Bẹẹni, otitọ. Lọdun 2007, a parapọ lati da ẹgbẹ AC silẹ ti mo sì borí gẹgẹ bii oludije fun ipo Aarẹ. Lẹyin tí mo gba tikẹẹti, Tinubu ran eeyan mẹfa to jẹ ọmọ ẹgbẹ sì mi, n ko ni darukọ wọn.

"Wọn wa bami pe Bola fẹ di igbakeji mi. Mo fesi pe gbogbo yín agbalagba ti ẹ sì tun jẹ ẹlẹsin Kristẹni. Bawo ni yoo se ri lara yín pe ẹlẹsin kana lo n dije dupo.

"Gbogbo wọn lo tako aba naa, ti mo sì ní kí wọn lọ sọ fun Tinubu

"Bí ajọsepọ òṣelu ṣe parí nìyẹn. O yabara kuro, o si ṣe atilẹyin fun Umaru Musa Yar'Adua. Bawo ni mo ṣe wa da gẹgẹ bii o ṣe sọ."