Bola Tinubu Certificate: Ṣé lóòtọ́ ni Tinubu lo ayédèrú ìwé ẹ̀rí? Ìwádìí BBC jáde lórí rẹ̀

Bola Tinubu
    • Author, Chiagozie Nwonwu & Fauziyya Tukur & Olaronke Alo
    • Role, BBC Disinformation Team

Ko si ẹri pe ayederu ni iwe ẹri ti aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu fi silẹ niwaju ajọ eleto idibo Naijiria, gẹgẹbi iwadii ikọ adamọlẹkun iroyin ofege nileeṣẹ BBC, BBC's Global Disinformation Team ṣe fi idi rẹ mulẹ.

Awọn ifisun kan n waye lori ayelujara pe iwe ẹri ofege ni Aarẹ Tinubu lo fun idibo to koja lẹyin ti fasiti Chicago State University, CSU kede esi ẹkọ rẹ lọsẹ to kọja.

A ti gbe lara awọn ohun ti awọn eeyan n sọ yẹwo.

Ọrọ gbigbe esi ẹkọ aarẹ jade si gbangba waye lori ipẹjọ ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar pe tako ibo to gbe aarẹ wọle.

Atiku Abubakar n fẹ ki ile ẹjọ wọgi le ibo to gbe Tinubu wọle lori ẹsun pe ayederu iwe ẹri imọ nipa akoso okoowo (Bachelor of Science in Business Administration) to gba ni ọdun 1979 lo gbe ka iwaju ajọ Inec.

Lati gba ẹri fun ẹsun yii, Atiku Abubakar gba ile ẹjọ kan ni orilẹede Amẹrika lọ loṣu kẹjọ lati beere fun iwe ẹri ẹkọ Tinubu.

Awọn agbẹjọro Tinubu tako eyi labẹ awijare pe igbesẹ yii lodi si ẹtọ gedegbe ni mo wa (Privacy), amọṣa ile ẹjọ ni ki wọn tẹsiwaju.

Awọn iwe ti Atiku Abubakar beere fun niwọnyii:

  • Ẹda iwe ẹri ti CSU fun awọn akẹkọọ lọdun 1979
  • Ẹda iwe ẹri ti CSU fun Tinubu lọdun 1979
  • Awọn ẹda iwe ẹri to ni ọwọ kikọ, olu ati ibuwọlu kan naa ti wọn fun awọn akẹkọọ miran to fi ara pẹ eyi ti wọn fun Tinubu lọdun 1979
  • Awọn iwe lati fasti CSU ti Jamar Orr, to jẹ oṣiṣẹ fasiti naa nigba naa, buwọ lu laarin oṣu mejila, bẹrẹ lati ọjọ kini oṣu kẹjọ ọdun 2022

Ninu esi rẹ si ibeere akọkọ, fasiti CSU ko iwe ẹri meje fun oniruuru imọ ẹkọ, wa si ile ẹjọ naa ti wọn si bo orukọ awọn akẹkọọ to ni wọn.

Gẹgẹbi akọwe agba ileẹkọ naa ṣe sọ, awọn akẹkọọ to ni wọn ko tii wa gba wọn ni.

Ni idahun si ikeji, CSU ni oun ko le ri eyi ti wọn fun Tinubu lọdun 1979 mọ nitori pe wọn kii ni ẹda iwe ẹri ti akẹkọọ ba ti wa gba mọ.

Ni idahun si ibeere kẹta, CSU ni awọn fun Tinubu ni aarọ iwe ẹri rẹ ti wọn kọ ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹfa ọdun 1979 si. Ileẹkọ naa si tun gbe ẹda iwe ẹri ti wọn fun awọn akẹkọọ miran pẹlu oolu ati ontẹ kan naa pẹlu eyi ti wọn fun Tinubu jade.

Ni idahun si ẹsun kẹrin, fasiti CSU gbe awọn iwe miran ti ọgbẹni Orr bu ọwọ si jade.

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Atiku Abubakar is challenging Bola Tinubu's election as president after coming second in the February 2023 polls

Ni ibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ naa, agbẹjọro fun Atiku, Angela Liu fi ọrọ wa Caleb Westberg, akọwe agba ile ẹkọ CSU bayii lẹnu wo.

Agbẹnusọ fun Atiku, Phrank Shaibu fun BBC ni anfani si akọsilẹ ifọrọwanilẹnuwo naa.

Awọn eeyan kan lori ayelujara lorilẹede Naijiria fi n gbe ifisun kiri pe ifọrọwanilẹnuwo ati iwe ẹri ti CSU gbe sita fihan pe ayederu iwe ẹri ni Tinubu gbe kalẹ siwaju ajọ Inec. Bakan naa ni agbẹjọro Atiku Abubakar, Kalu Kalu pẹlu sọ eyi nibi ifọrọwerọ pẹlawọn akọroyin lọsẹ to kọja.

Iwadii wa lori eyi fihan pe ko si ẹri kankan lati fi idi eyi mulẹ.

Ohun ti eeyan kan fi si oju opo X rẹ

Fasiti CSU fun awọn akẹkọọ ni oriṣiriṣi iwe ẹri laarin ọdun 1979 si 2003. A si ṣe ayẹwo gbogbo wọn:

  • Akọkọ to gba lọdun 1979, eyi to ni o sọnu nigba ti oun lọ ṣe atipo
  • Ikeji to gbe kalẹ niwaju Inec - gẹgẹ bi arọpo to gba lati fasiti CSU (Eyi ri bakan naa pẹlu gbogbo awọn ti fasiti naa fi sita lawọn ọdun 1990s.
  • Ni afikun, CSU ṣi tun fun Tinubu ni iwe ẹri ipaarọ miran eyi to jẹ laarin ọdun 2000s

Awọn ifisun ori ayelujara da lori awọn afiwe iwe ti Tinubu gbe siwaju Inec ati eyi ti CSU fun un ni ọdun 1979.

Nigba ti wọn n fi ọrọ wa Ọgbẹni Westberg lẹnuwo, agbẹjọro fun Atiku dojule ẹda iwe ẹri ti aarẹ Tinubu fun ajọ eleto idibo Naijiria, pẹlu ariyanjiyan pe ko da bi eyikeyi ti fasiti CSU gbe sita.

Westerberg ni lootọ ni ko farajọ awọn ti wọn fi sita lọdun 1979, amọ o fi ara jọ ọkan lara awọn abala ẹda iwe ẹri ti wọn ko fun Atiku. Ayẹwo wa pẹlu si tun fi idi eyi mulẹ.

Ohun ti o ṣẹlẹ ni pe iyatọ to wa laarin awọn ẹda naa ni pe awọn kan jẹ aarọ ti wọn fi rọpo lọdun 1990s fun awọn ti wọn ti kọkọ gbe sita fun awọn akẹkọọ.

Ọgbẹni Westberg ni ẹda iwe ẹri CSU ti yi pada lọpọ igba laarin ọdun 1979 si asiko yii. O ni ẹni ba n beere aarọ iwe ẹri bayii yoo ri bi eyi ti wọn n fi sita bayii ni.

Nitori naa, bi Tinubu ba beere fun aarọ iwe ẹri rẹ lọdun 1990s, ohun ti wọn yoo fun un naa ni ẹda to da bi eyi ti ile iwe naa n fi sita nigba naa.

Iwe ẹri CSU

Oríṣun àwòrán, Chicago State University

Mẹta ninu awọn ẹda iwe ẹri ti fasi CSU fi sita lawọn ọdun 1990s ri bakan naa pẹlu ti Tinubu.

Ọkan ninu wọn ti wọn kọ ọjọ kejidinlogun oṣu kejila ọdun 1998 ri bakan naa bi eyi ti Tinubu fun ajọ Inec.

Bakan naa ni Ọgbẹni Westberg tun sọ pe CSU kii ni akọsilẹ iye igba ti akẹkọọ kan beere fun ẹda iwe ẹri rẹ, nitori naa ko si akọsilẹ lori igba ti Tinubu beere fun ẹda iwe ẹri rẹ.

Apa kan aworan idanimọ fasiti CSU ti parẹ ninu Ẹda ti Tinubu fun Inec, ṣugbọn ọgbẹni Westberg sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ igba ti wọn n ṣe ẹda eyi lo ri bẹẹ.

Nigba ti aw yẹ ẹ wo, a rii pe wọn ko fi apa isalẹ iwe ẹri naa si inu ẹrọ aṣẹda iwe (Photocopy machine) nigba ti wọn ṣe ẹda rẹ.

Iwe ẹri ti Tinubu fi ranṣẹ si ajọ Inec

Oríṣun àwòrán, ..

BBC kan si ikọ Tinubu lati gba ẹda iwe ẹri ti a n sọrọ rẹ yii. Wọn fi ẹda iwe ẹri naa ti wọn ni o wa lọwọ wọn ranṣẹ . Ẹda dudu ati funfun (Black and White) ni wọn ṣe e to si ri bakan naa pẹlu eyi ti wọn fun ajọ Inec.

Ẹsun kan ti ajọ kan fi sita ni Naijiria ni pe iwe ẹri ti Tinubu gbe kalẹ fun Inec kii ṣe iwe ẹri CSU nitori pe wọn kii kọ 'with honors' si abẹ imọ ijinlẹ to gba.

BBC fi idi rẹ mulẹ pe bi otilẹ jẹ pe eyi ko si ni awọn iwe ẹri miran ti CSU gbe sita, o wa ninu awọn iwe ẹri ti wọn fi sita laarin ọdun 2000s eleyi to fi idi ọrọ ti Ọgbẹni Westberg sọ lasiko ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun un ni ile ẹjọ.

O ni akọsilẹ "with honors" -eyi to wa ni ibamu pẹlu iwe ẹri ti aarẹ fi si ọdọ Inec.

Iwe ẹri CSU

Oríṣun àwòrán, Chicago State University

Ọgbẹni Westberg ni oun ko le fi idi eyi mulẹ nitori pe o ṣi wa lọdọ awọn, wọn ko tii wa gba

Kii ṣe gbogbo awọn akẹkọọ lo maa n kẹkọgboye pẹlu imọ to ja fafa ni ilẹẹkọ giga fasiti. Ọgbẹni Tinubu, gẹgẹbi awọn alaṣẹ fasiti CSU ṣe sọ ninu ọpọlọpọ awọn iwe ti BBC ri, kẹkọgboye ni CSU pẹlu imọ to ja fafa (with honors).

BBC kan si fasiti CSU pẹlu awọn ibeere nipa iwe ẹri rẹ o si tọ wa si atẹjade kan ti wọn fi sita ninu eyi ti wọn ti sọ pe: "Ọkan wa balẹ nigba gbogbo pe ko si kọnu-n-kọhọ ninu boya Tinubu wa si ile ẹkọ wa to si pari ẹkọ rẹ."

Ẹsun mii to n kaakiri lori ayelujara ni pe obinrin ni Bọla A Tinubu to lọ si fasiti CSU.

Ọgbẹni Tinubu lọ si ile ẹkọ Southwest College (to ti di Richard J. Daley College) ki o to lọ si CSU ni ọdun 1976. Ni iwe akọsilẹ rẹ 'F' to tumọ si obinrin ninu akọsilẹ naa jẹyọ eyi to mu ki wọn maa ro pe obinrin lo lọ si ile iwe naa ati pe Ọgbẹni Tinubu "ji orukọ rẹ ni" Agbẹjọro fun Atiku, Ọgbẹni Kalu sọ eleyi ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin lọsẹ to kọja.

Amọṣa ninu ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fun un ni ile ẹjọ Ọgbẹni Westberg sọ pe ko si wọlukọlu kankan lori boya ọkunrin lo lọ si ile ẹkọ CSU tabi obinrin. O ni ọkunrin ni, ti orukọ rẹ si n jẹ Bọla A Tinubu. Westberg ni fasiti naa lo awọn ọna miran lati fi idi otitọ mulẹ lori ẹni to ni iwe ẹri ọhun.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, nọmba idanimọ araalu, (Social Security number) to wa ninu iwe akọsilẹ ẹkọ ti Southwest College ba awọn ohun to wa ninu awọn iwe akọsilẹ miran mu ninu eyi ti o ti la a yekeyeke pe ọkunrin ni ẹni to ni nọmba idanimọ naa.

Amọṣa, iwe ẹri naa wu awọn ibeere kan jade nipa ọjọ ibi Tinubu ati ile ẹkọ girama to lọ.

Ọkan lara awọn iwe naa fihan pe Ọgbẹni Tinubu lọ si ile ẹkọ girama Government college, Eko ni ọdun 1970, amọ akọsilẹ to wa lori oju opo ayelujara ile ẹkọ naa sọ pe ọdun 1974 ni wọn da ile ẹkọ girama naa silẹ.

Yatọ si ọrọ 'ṣe ọkunrin ni tabi obinrin?', awọn ọjọ ibi to wa ninu awọn iwe naa kan yatọ si eyi ti Ọgbẹni Tinubu n gbe kiri tii ṣe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 1952.

Akọsilẹ iwe ẹkọ rẹ ni CSU sọ pe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 1954 ni wọn bi i. Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 1955 lo wa lori iwe igbaniwọle rẹ.

Agbẹjọro fun Atiku ṣalaye lasiko ifọrọwanilẹnuwo to ṣe fun Westberg pe ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kẹta ọdun 1952 ni Tinubu fi si iwe to gbe ka iwaju Inec.

Amọ Westberg sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ aṣiṣe.

A kan si ikọ Ọgbẹni Tinubu lori aidọgba wọnyii, agbẹnusọ rẹ si dari wa si ọdọ ẹgbẹ oṣelu rẹ - APC.

A tun kan si agbẹnusọ fun ikọ ipolongo Tinubu, Festus Keyamo, to tun jẹ minisita ninu iṣejọba. Ko gbe ipe wa tabi dahun si atẹjiṣẹ ti a fi ranṣẹ sii.

Bakan naa la fi ibeere ranṣẹ si ikọ Ọgbẹni Abubakar. Awọn naa ko dahun.