Ẹ̀ẹ̀mejì péré lọ́sẹ̀ ni kí ẹ máa lọ síbi iṣẹ́ - ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ COEASU

Oríṣun àwòrán, COEASU
Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni (COEASU) ti darí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ láti máa lọ sí ibi iṣẹ́ ni ẹ̀ẹ̀mejì péré lọ́sẹ̀.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí àlékún tún ṣe bá owó epo bẹntiróòlù láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Ẹgbẹ́ náà ní àlékún tó bá owó epo bẹntiróòlù náà ti ṣokùnfà kí àlékún bá iye owó ọkọ̀, oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì tó ṣe kókó fún ìgbé ayé ọmọnìyàn.
Ààrẹ ẹgbẹ́ COEASU, Smart Olugbeko nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́rú ní ìlú Abuja ní ìpalára ọ̀wọ́n gógó náà ti pọ̀jù fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn àti pé awọ kò ká ojú ìlù fún wọn mọ́.
Olugbeko ní nígbà tí ìjọba kọ́kọ́ yọ ìrànwọ́ orí epo, àwọn lérò wí pé ìpalára rẹ̀ kò ní pẹ́ tí ara máa fi dẹ ará ìlú àmọ́ kàkà kó dẹ̀ níṣe ló ń le si.
Ó ní ọwọ́ ìrètí pé ìjọba máa fi owó kún owó oṣù àwọn òṣìṣẹ́ láti mú àdínkù bá ìnira tí wọ́n ń kojú ni ni owó epo tún gbówó lórí si.
Ó ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ló ń kọminú lórí àlékún yìí, èyí ló sì mú àwọn pinnu pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn máa lọ sí ibi iṣẹ́ ní ẹ̀ẹ̀mejì péré lọ́sẹ̀.
Bákan náà ló ní àwọn máa pe ìpàdé àpapọ̀ gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ láìpẹ́ láti fẹnukò lórí àwọn ọjọ́ tí yóò jẹ́ pàtó tí àwọn òṣìṣẹ́ yóò fi máa lọ ibi iṣẹ́ náà.
Olugbeko tún tẹ̀síwájú pé láti ọdún 2010 ni wọ́n tí buwọ́lu owó oṣù tí àwọn ń gbà báyìí ní èyí tó túmọ̀ sí pé owó oṣù tí àwọn ti ń gbà láti ọdún mẹ́tàlá sẹ́yìn ni àwọn ṣì ń gbà títí di àsìkò yìí pẹ̀lú gbogbo bí nǹkan ṣe gbówó lórí.
Ó wá rọ Ààrẹ Tinubu láti tètè wá bí wọ́n ṣe máa ṣe àgbéyẹ̀wò owó oṣù àwọn olùkọ́ náà tí wọn kò bá fẹ́ rí ojú pípọ́n àwọn òṣìṣẹ́.
NLC fọnmú lórí èlé owó epo, ó ní ìjọba ń gbowó lọ́wọ́ Tálákà fún àwọn Ọlọ́rọ̀ ni
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ọ̀gá àgbà àjọ Iléeṣẹ́ tó ń rí sí epo bẹntiróòlù ní Nàìjíríà, NNPCL, Mallam Mele Kyari ti ní bí ọ̀rọ̀ ọjà epo bẹntiróòlù ṣe ń lọ sí ló fa àlékún tó bá owó epo bẹntiróòlù lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Kyari nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó ṣèpàdé pẹ̀lú igbákejì Ààrẹ, Kashim Shettima ní Aso Rock, Abuja.
Ó ṣàlàyé pé pẹ̀lú àyípadà tó bá ẹ̀ka epo rọ̀bì báyìí, bí ọjà bá ṣe ń lọ sí ni àyípadà yóò ṣe máa bá iye owó epo bẹntiróòlù.
Ó ní nígbà mìíràn ó ṣeéṣe kí owó náà gbé ẹnu sókè, ó sì lè já wálẹ̀.
Ọ̀gá àgbà NNPCL náà tún ṣàlàyé pé àlékún tó bá owó jálá lítà epo kan láti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà sí ẹgbẹ̀ta náírà lé díẹ̀ sọ àrídájú rẹ̀ pé epo bẹntiróòlù wà nílẹ̀ jaburata àti pé kìí ṣe àìsí epo ló fa àlékún tó bá owó epo.
Ó ní epo bẹntiróòlù tó wà ní Nàìjíríà báyìí máa tó àwọn ọmọ Nàìjíríà fún ọgbọ̀n ọjọ́ nítorí náà kí àwọn ènìyàn má fòyà.

Oríṣun àwòrán, COLLAGE
ìjọba àpapọ̀ ń gbà lọ́wọ́ àwọn aláìní láti fi bùn kún àwọn ọlọ́rọ̀ - NLC
Ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba àpapọ̀ lórí bí àlékún tún ṣe bá owó epo bẹntiróòlù lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
NLC nínú àtẹ̀jáde kan tí Ààrẹ wọn, Joe Ajaero fi léde fi ẹ̀sùn kan ìjọba àpapọ̀ pé níṣe ni wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn aláìní láti fi bùn kún àwọn ọlọ́rọ̀.
Ajaero ní ìgbésẹ̀ ìjọba láti tún fi kún owó epo bẹntiróòlù tún ti mú àlékún bá ìṣòro tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú.
Ó ní ó jọ wí pé àwọn kan ń tan Tinubu tí kò fi mọ àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ lásìkò tó yẹ ní èyí tó ń kó ìpalára gidi bá àwọn ará ìlú.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní ó jẹ́ ohun tó ń bá àwọn lọ́kàn jẹ́ pé ìjọba kọ̀ láti ṣe ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ń fẹ́ tí wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ apàṣẹ wà á lórí àwọn ìpinnu tó ń mú ìnira bá ará ìlú.
Bákan náà ni wọ́n tún bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba lórí ìpinnu rẹ̀ láti máa fún àwọn tálákà ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà lóṣù fún oṣù mẹ́fà nítorí ìrànwọ́ orí epo tí wọ́n yọ.
Ajaero tẹ̀síwájú pé tí kìí bá ṣe pé ìjọba kò nání ará ìlú, wọn ò ní gbèrò láti máa fún odidi ìdílé kan ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà lóṣù àmọ́ kí wọ́n fẹ́ fún àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní àádọ́rin bílíọ̀nù náírà.
Ó ní àwọn ìgbésẹ̀ yìí fi hàn pé ìjọba kò mọ irú ìṣòro tí àwọn ènìyàn ń kojú láti bí oṣù méjì tí ìjọba tuntun ti wà lórí ipò.















