Tinubu yóhùn padà lórí fífún àwọn tálákà ní ₦8,000, kéde ìgbésẹ̀ tuntun

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ní ìṣèjọba òun yóò ṣàtúngbéyẹ̀wò ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà tí wọ́n ń gbèrò láti máa fún àwọn tálákà kan nítorí ìrànwọ́ orí epo tí ìjọba yọ.

Èyí ń wáyé lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ òkò ọ̀rọ̀ sí ìjọba pé kò sí nǹkan tí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà fẹ́ dà fún àwọn ènìyàn lásìkò yìí.

Ṣáájú ni Ààrẹ Tinubu tí kéde pé ìjọba òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí pín ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ náírà sí ìdílé mílíọ̀nù méjìlá lójúnà àti mú ìṣòro tí wọ́n ń kojú díkùn látàrí bí ìjọba ṣe yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù.

Bákan náà ni ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC náà fárígá pé ìgbésẹ̀ tí ìjọba fẹ́ gbé yìí kò ní so èso rere kankan fún ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀.

Ẹ̀wẹ̀, àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ Tinubu, Dele Aláké fi síta lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ìjọba ti ní kí wọ́n tún àgbéyẹ̀wò ìgbésẹ̀ náà ṣe kí wọ́n tó ṣe àmúṣẹ rẹ̀.

Àtẹ̀jáde náà ni ohun tó fà èyí kò sẹ́yìn bí àwọn ènìyàn ṣe bù àtẹ́ lu owó náà.

Tinubu fi kun nínú àtẹ̀jáde ọ̀hún pé gbogbo ohun tí ìjọba ń gbèrò láti ṣe láti mú ìgbé ayé rọrùn fún àwọn ènìyàn ni wọn yóò fi léde ni kíákíá.

Bákan náà ló pàṣẹ pé kí wọ́n fún àwọn àgbè àtàwọn ìdílé tó tó àádọ́ta mílíọ̀nù ní ajílẹ̀ àti àwọn oúnjẹ oníkóró tí wọ́n lè gbìn.

Káàkiri ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tó wà ní Nàìjíríà tó fi mọ́ olú ìlú Naijiria, Abuja ni Tinubu ní kí wọ́n pín àwọn ajílẹ̀ náà sín.

Ó tún ṣàlàyé pé gbèsè bílíọ̀nù lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà tí wọ́n ti ṣáájú gbà tẹ́lẹ̀ ni àwọn yóò ṣe àmúlò rẹ̀ dáadáa.

Ààrẹ tún ṣèlérí pé òun máa ma tẹ́tí sí gbogbo nǹkan tí àwọn ará ìlú bá ń fẹ́.