Iye owó nǹkán l'ọ́jà tún lọ sókè pẹ̀lú ìdá 22.79% - Àjọ Aṣèṣirò NBS

Aworan afihan awọn ólọja

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àjọ aṣeṣiro lorileede Naijiria ti kéde alekun lori iye owó ọjà ni Naijiria losu kẹfa ọdun.

Ninu atẹjade ti wọn fí sita lọjọ Aje àjọ naa sọ pe alekun ìdá 22.41% lo wa tẹlẹ ṣugbọn o ti lekun si ida 22.79 bayii.

Alekun yii jasí pe ida 0.38% lo fi lekun sí losu kẹfà ti a ba wo eleyi pẹlu ti oṣù kàrún ọdún 2023,

Ni ti iye owó tí ọja fi gbowó lori ni asiko yii lọdun to kọja àjọ naa sọ pe owo ti ọdún yii ti lekun sii ju ti ọdun to kọja lọ.

Alekun yii jẹ nkan to n de ba araalu lasiko ti ijọba yọ ẹdinwo kuro lori iye owó bẹntiróò.

Ọjọ Aje kanna ti wọn kede ọrọ yii naa ni iroyin gbòde pe ileeṣẹ to n mojuto ọrọ epo NNPCL tun ti fi kun iye owó jaala epo bẹntiróò lati 515 sí nkan bí 617 láwọn ipinlẹ kan.

Asiko yii fẹ dabi ẹni pe o le diẹ fun ọpọ araalu lorileede Naijiria.

Ọwọngogo nkan gbẹnu soke lati igba ti ijọba yọ ẹkunwo lori iye owo bẹntiroo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Koda nkan naa le de ibi pe banki apapọ mu alekun ba iye owo ele rẹ ti eleyi si jẹ afikun to ga julọ lakọsilẹ lati nkan bi ogun ọdun sẹyin.

Losu kaarun ọdun yii lo gbe igbesẹ mimu alekun ba iye owo ele lori owo yiya lọ si ida 18.5%.

Lọpọ idile lawọn eeyan ti n da orisi ọgbọn lati le ri nkan diẹ ra ninu owo to ṣe pe ko ka nkankan fun ọpọ mọlẹbi.

Iye owo ounjẹ to gbowo lori yii mu ki aarẹ tuntun Bola Ahmed Tinubu kede ilu o fararọ lẹka ounjẹ to si kede awọn iogbesẹ kọọkan lati mu ki nkan rọgbọ.

Ipenija aabo wa lara nkan to mu ki iye owo ounjẹ wọn ni Naijiria nitori pupọ agbẹ ni ko le lọ soko nitori ibẹru foya awọn ajinigbe ati janduku.

Ireti wa wi pe awọn ilana ti ijọba fẹ gbe yoo mu iyipada ba iye owo ounjẹ lọja ṣugbọn ki eleyi to le waye, ọpọ n reti awọn igbesẹ mimu idẹkun ba araalu taa mọ si "palliatives".

Ijọba fẹ pin ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira fawọn ti nkan nira fun julọ ni Naijiria.

Amọ isiro owo naa to jẹ ẹgbẹrun mẹjọ Naira loṣu jẹ nkan ti ọpọ sọ pe ko to lati fi gbọ bukata lasiko ti ọwọngogo nkan wa lode yi