Èyí n'ìdí tí búrẹ́dì tún se fẹ́ gbówó lórí

Aworan buredi

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ awọn oniburẹdi ni Naijiria, AMBCON ti kesi awọn ọmọ Naijiria lati gbaradi nitori afikun ti yoo ba iye ti wọn n ta burẹdi kaakiri orilẹede Naijiria laipẹ.

Gẹgẹ bi ẹgbẹ naa se sọ, iye tuntun ti wọn n ra burẹdi naa yoo gberasọ ni Ọjọ Kẹrinlelogun, Osu Keje, ọdun 2023.

Ajọ naa ni ọwọngogo epo bẹntirol ati yoo waye naa ko sẹyin bi awọn nkan ti wọn ra gẹgẹ bi eroja se gbe owo lori.

Ajọ naa ni awọn nilo iati se afikun naa nitori ọwọngogo tib a iye ti wọn ta nkan ni ọja, ti ọpọ si ti fi isẹ maa silẹ nitori ọwọngogo.

Yiyọ owo iranwọ bẹntirol ti jẹ ki inira de ba ọpọlọpọ ọmọ Naijiria, ti ati jẹun si ti iṣoro.

Igba kẹta ree laarin ọdun meji ti afikun yoo ba owo owo burẹdi

Eleyii kii se igba akọkọ ti wọn fi owo kun owo burẹdi, lati ọdun 2022 ni afikun yii ti bẹrẹ.

Ni osu Kẹfa, ọdun 2022 ni wọn fi ida ogun kun iye ti wọn n ta owo burẹdi.

Saaju igba naa ni Osu Karun un ni awọn ẹgbẹ oniburẹdi, PBAN kede afikun iye owo burẹdi kaakiri orilẹede Naijiria.

Awọn onimọ ni kii se ẹbi awọn oniburẹdi naa nitori ohun gbogbo lo tig be owo, to fi mọ iye ti wọn n ta flour ati awọn eroja burẹdi.

Amọran ni pe ki ij̣ba wa ọna lati se adikun iye owo ori ti awọn eniyan n san ki iye ti wọn n ta awọn nkan le dikun lawujọ.

‘’Mi o le ra burẹdi jẹ mọ fun awọn mọlẹbi mi’’

Aworan burẹ ti wọn to sori atẹ

Oríṣun àwòrán, others

Arakunrin kan ni ilu Kano ti ni oun ko to ẹni to n ra burẹdi gẹgẹ bi ounjẹ aarọ fun mọlẹbi oun mọ.

Mallam Ado Yahaya sọ ọrọ yii ni ilu Kano pe lati igba to ti wọn koko ni awọn ko lee jẹ burẹ̀i bii ti tẹlẹ mọ, nitori oun nilo 2000 naira lojumọ lati fi ra burẹdi fun oun ati mọlẹbi oun fun ounjẹ aarọ.

O ni igba ti oun jẹ kẹyin ni aarọ ọjọ kan lẹyin ti awọn ọmọ oun lọ si ileẹkọ nitori oun ko lee jẹ ni oju wọn, ki awọn naa ma ba sọ pe awọn yoo jẹ.