Ṣé o ti pàdé àwọn agbowó òde tí wọ́n ń fi ipá gba owó lọ́wọ́ àwọn ọlọ́kọ̀, aráàlú rí?

Aworan

Ọpọlọpọ igba ni awọn araalu ti ma n ke irora nitori awọn agbowo ode ti wọn ma n gba owo ori lọwọ awọn eniyan.

Ti o ba n lọ ni oju popo, waa ri awọn ọdọ pẹlu igi ti wọn n gba owo lọwọ awọn awakọ.

Iru eniyan bayii ni arakunrin Nwokuha to n gba owo ode fun awọn ọlọla ati ilumọọka ni ilu Port harcourt.

Nwohaka ni oniroyin BBC, Nduka Orjinmo ṣapejuwe pe o jẹ ẹni ti o ni ẹru lara, ti o si n rin kaakiri pẹlu igi ni ọwọ rẹ ni opopona nibi to ti n gba owo ode lọwọ awọn araalu.

Iṣẹ kan ṣoṣo ti arakunrin naa to jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ọun n ṣe ni lati gba owo ori lọwọ awọn araalu, paapaa awọn awakọ taxi ati awọn awakọ bọọsi elero mejidinlogun(18-seater) ti wọn n ṣiṣẹ ni ilu naa.

Awọn agbowo ode yii ni wọn ni wọn n ṣiṣẹ fun awọn mọlẹbi ọlọla ni Naijiria to n ṣiṣẹ ni agbegbe wọn.

Arakunrin Nwohuka ni o kere tan oun gba to ẹgbẹrun marun naira si ẹgbẹrun meje naira lọwọ awọn araalu ni ojumọ.

Nwokuha yoo gba ni ara owo naa, ti yoo si kọ awọn yoku fun bii mọlẹbi marun un to lẹnu ni agbegbe naa.

Amọ ti ko si ẹni to lee sọ bi wọn ṣe n na owo naa.

Aworan
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn wọnyii ni wọn n ṣiṣẹ to yẹ ki ijọba ibilẹ ṣe, amọ ti wọn ki n ṣe oṣiṣẹ taara.

Nwokuha ni iṣẹ ti oun n se n pese aabo fun awọn araalu nitori oun ma n pari ija laarin awọn ọlọkọ ti wọn ba n ba ara wọn ja.

Onimọ nipa eto owo ori ton sisẹ fun ijọba tẹlẹ, Michael Ango ni awọn agbowo ode yii ma n yọ owo ori naa ki wọn to kọ lọ si apo ijọba.

Ninu ọrọ rẹ Nwokuha ni awọn to ma n wa si agbegbe Rumuola ko ni ẹtọ lati wa si ibẹ, nitori naa wọn gbọdọ san owo ori ki wọn to ṣiṣẹ ni agbegbe naa.

Igba miran ti awọn awakọ yii ba kọ lati san owo, ni wọn ma n fọ gilaasi ọkọ wọn abi ki wọn yọ ‘’plate number wọn’’.

Ti wọn ba si gbiyanju lati ja, nise ni Nwokuha ni ohun yoo la igi mọ wọn lori.

Awakọ ọkọ nla kan sọ fun BBC pe awọn agbowo ode yii ma n gba ẹgbẹrun lọna ọgọrin naira lọwọ wọn nigba miran, ti awọn ba n kọja lọ.

Ko tan sibẹ, awọn awakọ fun ileeṣẹ to n ko eru ni owo ori ti awọn n san ko kere rara, ti awọn si san ni orisirisi ti wọn ba ka si ilẹ fun wọn.

Awọn awakọ naa ni eyi ko dara rara nitori oun fa ifaṣẹyin fun awọn ati pe ko jẹ ki wọn ni owo lọwọ.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Laipẹ yii ni ijọba Tinubu ni awọn yoo fopin si awọn ti wọn n gba owo ode lọwọ awọn araalu lọna aitọ.

Ti wọn si ni awọn yoo pese ọna to igbalode ti awọn eniyan yoo maa gba lati san owo ori wọn

Nibayii, sisan owo ori ni ijọba Tinubu si n gbajumọ lọwọ, to fi mọ Value-Added Tax (VAT).

Ijọba ni awọn yoo lo awọn ẹgbẹ awọn ọlọja lati maa gba owo ori lọna igbalode, ti ko ni si awọn agbowo ode yii mọ.

Ti eyi ba ṣeese, yoo fun awọn araalu ni aaye lati san owo ori wọn ni ọna ti ko kọni lominu, ti awọn ijọba ibilẹ naa yoo si mọ iṣẹ bii iṣẹ.