"Ẹgbẹ́ òṣèré tíátà ń palẹ̀mọ́ fún ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún 100 Olumo Agbako"

Mr Latin kede ayẹyẹ ọjọ ibi fun baba Agbako

Oríṣun àwòrán, Mr Latin 1510/Instagram

Ẹgbẹ awọn oṣere tiata Yoruba, TAMPAN ti n mura lati ṣe ayẹyẹ ọgọrun un ọdun agba oṣere ni, Charles Olumo, ti ọpọ eeyan mọ si Agbako.

Ọpọ araalu atawọn oṣere tiata Yoruba lo ti ki Agbako fun ayẹyẹ ọjọ ọgọrun un ọdun rẹ to waye ninu ọdun 2023 yii.

Ninu atẹjade kan loju opo Instagram ni Aarẹ TAMPAN, Bolaji Amusan ‘Mr. Latin’, ti fi iwe pe awọn ololufẹ ọṣere naa sibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ ọhun ti wọn fẹ ṣe fun un.

Atẹjade naa ni “Ore ọfẹ nla ki eeyan wa laaye lati ṣe ayẹyẹ ọgọrun un ọdun loke eepẹ.”

Mr Latin kede ayẹyẹ ọjọ ibi fun baba Agbako

Oríṣun àwòrán, mrlatin1510/Instagram

“Ore ọfẹ ni ki eeyan gbe nile aye fun ọgọrun un ọdun pẹlu oniruru iriri ti yoo kun ọpọlọpọ oju ewe ninu iwe.”

“Olori to ṣe e mu yanga ni ọ, ẹni to yẹ ki eeyan joko ti lati kọgbọn lọdẹ rẹ si ni ọ pẹlu.”

“Adura wa ni pe ki Eledumare lọra ẹmi rẹ... o ku oriire ọjọ ibi.”

Gẹgẹ bii atẹjade ti Mr Latin fi lede, ogunjọ, oṣu Keje yii ni ayẹyẹ ọjọ ibi naa yoo waye niluu Abeokuta, nibi ti Mr Latin funra rẹ yoo ti jẹ olugbalejo agba.

Awọn araalu n sọko ọrọ si Mr Latin

Ẹwẹ, igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti ọpọ eeyan bu ẹnu atẹ lu Mr Latin ati ẹgbẹ TAMPAN pe wọn ko ṣe ayẹsi fun agba oṣere naa bi awọn ṣe lero.

Wayi o, lẹyin ti Mr Latin kede ayẹyẹ ọjọ ibi yii, awọn eeyan ṣi n tẹsiwaju lati maa bu Mr Latin.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe igbeṣe naa dara, lawọn mii n sọ pe ko yẹ ko duro ki awọn eeyan bu awọn oni tiata ki wọn to ṣe ayẹsi awọn agbagba oṣere.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ẹnu ọjọ mẹta yii lawọn eeyan bẹrẹ si n sọrọ si Mr Latin gẹgẹ bii Aarẹ TAMPAN latari bi awọn agba oṣere kan ṣe n bere fun owo ati ọkọ lori ayelurjara.

Eyii ko ṣẹyin fidio ifọrọwerọ Mr Latin pẹlu BBC Yoruba, nibi to ti sọ pe o ṣoro lati ṣeranwọ fun awọn onitiata ti ko si ninu ẹgbẹ TAMPAN, ati pe onikaluku lo mọ bo ṣe n na owo rẹ.

Charles Olumo Agbako

Oríṣun àwòrán, Kemity TV

Ta ni Charles Olumo Agbako?

Ọdun 1923 ni wọn bi alagba Charles Olumo nipinlẹ Ogun, ti orukọ abisọ rẹ si jẹ Abdulsalam Sanyaolu.

O lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ niluu Egba-Owode, ko to lọ silu Abeokuta nibi to ti kẹkọ nile ẹkọ girama Lisabi Grammar School.

Lẹyin ọdun 1990, irawọ Agbako bẹrẹ si n tan lagbo oṣere tiata Yoruba.

Laipẹ yin ni agba osere tiata naa kede pe aisan n se oun, ti ara oun ko si le eyi ti BBC Yoruba gbe jade.

Bakan naa lo fara han ninu sọọsi kan nil;u Ibadan lati se ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọrun ọdun rẹ

Lara awọn sinima to lamilaka ti Agbako ti kopa ni Saworo Ide, Taxi Driver, Jagun, Amin Orun, Aiye, Jayesinmi, Igbo Dudu sti bẹẹ bẹẹ lọ.