Charles Olumo Agbako ń ṣe àìsàn ńlá, ó ní ara ń ni òun

Charles Olumo Agbako

Òdú ni gbajúgbajà òṣèré tíátà nnì, Abdulsalam Ishola ẹni tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ sí Charles Olúmọ Àgbákò lagbo tiata.

Láàárín ọdún 1990 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2000, àwọn ipa líle tí Charles Olúmọ Àgbákò máa ń kó nínú eré jẹ́ kó di ìlú mọ̀ọ́kà láàárín àwọn àgbà òṣèré.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, gbajúmọ̀ òṣèré yìí gba ikọ̀ BBC Yorùbá ní àlejò, tí baba naa sì ṣàlàyé bí ìrìnàjò wọn nínú eré sinimá ṣe bẹ̀rẹ̀.

Bakan naa lo tun salaye àwọn ipa ribiribi to ti ko sẹyin ninu eré sinimá nínú ìgbésí ayé wọn.

Kódà bàbá Charles Olúmọ Àgbákò fi yé wa nígbà náà wí pé, kokoko ni ara ọta oun le.

Agbako ni oun ṣì lè ṣeré tíátà ti wọ́n bá pe oun sí iṣẹ́ pẹ̀lú bí ọjọ́ orí oun ṣe ti ń súnmọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún lọ.

N kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀, ara ń ni mí - - Charles Agbako

Eyi lo mu ko jẹ ìyàlẹ́nu nla fún BBC Yoruba nígbà tí a gbọ́ wí pé bàbá tó ń fò sókè ní bi oṣù mélòó kan sẹ́yìn ni òjòjò ń ṣe Ògún rẹ̀ báyìí.

Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí ilé bàbá Charles Olúmọ Àgbákò láti mọ ipò ìlera tí bàbá náà wà, àgbà òṣèré náà ṣàlàyé bí àárẹ̀ tó ń ba jà ṣe bẹ̀rẹ̀ ní bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

Àgbákò ṣàlàyé pé ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni òun ṣàdédé ri wí pé òun kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀ ní ìrọ̀rùn.

Ó ní èyí ló mú kí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ òun gbé òun lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú, tí àwọn dókítà sì ní iṣẹ́ abẹ ló le tán ìṣòro ohun tó ń bá òun fínra lọ́dún náà.

Ó fi kun pé, lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ náà tán, ni ojú ọgbẹ́ ibi tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ abẹ ọ̀hún máa ń da òun láàmú tí òun sì tún padà lọ sí ilé ìwòsàn náà.

"Nígbà tí mo padà lọ sí ilé ìwòsàn, wọ́n fún mi ní àwọn òògùn àti nǹkan mìíràn láti máa lò láti fi tọ́jú ibi ojú ọgbẹ́ náà"

Àkọlé fídíò, Charles Agbako: N kò le yàgbẹ́ tàbí tọ̀, ara ń ni mí

"Dókítà ní ìfun mi ti já sínú ẹpọ̀n mi - oògùn lásán kò le ràn mí mọ́"

Charles Olumo agbako

‘Dokita ni isẹ abẹ akọkọ ko jinna wọnu lo fa ailera mi’

Charles Olúmọ Àgbákò tẹ̀síwájú pé, lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni òun tún ń ri pé àti yàgbẹ́ àti tọ̀, tún bẹ̀rẹ̀ sí ní di ìjọ̀gbọ̀n.

Ó ní dókítà ní ó jẹ́ kí ó yé òun wí pé, iṣẹ́ abẹ ọjọ́ kìíní kò jìnà wọnú èyí ló sì fa àìlera gbogbo ìgbà tó ń bá òun fínra báyìí.

Bákan náà ló ní wọ́n jẹ́ kó yé òun wí pé ìfun òun ti já sínú ẹpọ̀n òun tí àwọn sì nílò láti ko kúrò níbẹ̀, ko le bọ́ sí àyè tó yẹ kó wà gangan nínú ikùn.

Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn dókítà ní òun kò le ṣe iṣẹ́ abẹ bíi ti ìgbà àkọ́kọ́ mọ́, àwọn ìgbésẹ̀ wà tí wọn yóò gbé láti mú kí ìfun náà padà sí ààyè rẹ̀, kí ìnira tí ó ń kó bá òun náà dínkù jọjọ.

"Nígbà tí mo dé ilé ìwòsàn, dókítà ní mi ò le ṣe iṣẹ́ abẹ mọ́, wọ́n ní ki n ṣáà ma lọ lo oògùn, gbogbo ògùn tí wọ́n ń kọ fún mi ni mò ń rà, tí àwọn ènìyàn mi dẹ̀ ń rà fún mi."

‘Ọjọ́ mẹ́ta-mẹ́ta ni mò ń gba abẹ́rẹ́, kò sí owó kankan mọ́’

Àgbákò ní lóòótọ́ ni àwọn ògùn tí àwọn dókítà kọ fún òun ń ṣiṣẹ́ àmọ́ ọjọ́ mẹ́ta mẹ́ta ni òun gba abẹ́rẹ́.

O ni awọn abẹrẹ yii lo wa láti fi mú àdínkù bá ìnira tí àìlera ọhun ń kó bá òun.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó ni àwọn ń run sórí àwọn ògùn àti abẹ́rẹ́ yìí, tó sì jẹ́ wí pé kò sí òkun àti ìlera pípé fún òun láti lọ sí oko eré sinimá mọ́.

Agbako ni ọ̀wọ́ nǹkan tí àwọn ènìyàn fi ń ran òun lọ́wọ́ nikan lo ku, ti oun n jẹ.

Charles Olumo Agbako

Baba Agbako n tọrọ iku fun ara rẹ nitori ara to n ni wọn - aya ọmọ Charles Olumọ

Ìyàwó ọmọ Charles Olúmọ Àgbákò, Olamide tó ń tọ́jú bàbá ṣàlàyé fún BBC News Yorùbá pé láti nǹkan bí oṣù mẹ́fà sẹ́yìn, tí ara bàbá kò ti yá, ni òun ti wà pẹ̀lú wọn.

Olamide ní ó jẹ́ ohun tó máa ń ba òun àti àwọn ọmọ bàbá lọ́kàn jẹ́ nígbà tí bàbá bá ń tọrọ ikú fún ara wọn nítorí bí ara ṣe ń ni wọn.

Ó ní lóòótọ́ ni pé bàbá Àgbákò ti dàgbà, àmọ́ àwọn ò mọ iye ọdún tí Ọlọ́run kọ fún wọn nítorí náà kò ní wù wá kí wọ́n lo ìgbésí ayé wọn tó kù nínú ìnira.

Ó fi kun pé ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà ni bàbá Àgbákò nílò lásìkò láti fi bọ́ lọ́wọ́ ìnira tí bàbá náà ń kojú lásìkò yìí.

Fidio yii ni Charles Olumo Agbako se pẹlu BBC Yoruba nigba ti ara rẹ le koko

Àkọlé fídíò, Charles Olumo Agbako: Ọjọ́ tí ìyá mi kú jẹ́ kò ṣeé gbàgbé-