Oyetola gba olùkọ́ 1000 ṣíṣẹ́ si, Adeleke fọnmú

Adeleke ati Oyetola

Gomina Adegboyega Oyetola ti Ipinle Osun ti fọwọsi gbigba afikun awọn olukọ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́jọ lati di aalafo to wa ni ẹka eto ẹkọ ni ipinlẹ naa.

 Igbesẹ igbanisisẹ yii lo tẹle igbanisiṣẹ akọkọ nibi ti wọn ti gbawọn olukọ ẹgbẹ̀rún eyi to waye ni ibẹrẹ ọdun yii.

Igbanisiṣẹ tuntun yii mu iye awọn olukọ ti ijọba Osun labẹ Gomina Adegboyega Oyetọla gba di ẹgbẹrun meji ati aabọ.

Komisona feto iroyin ati ilaniloye ipinlẹ Osun, Funke Egbemode lo fi iroyin naa lede lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Osun.

Egbemode ṣalaye pe awọn agbegbe igberiko ni ipinlẹ Osun naa yoo ri ninu awon olùkọ́ titun yii.

Wọ́n fẹ́ dojú ìjọba tó ń bọ̀ bolẹ̀ ní àkọ̀tun ìgbaniṣíṣẹ́ olùkọ́ - Adeleke

Igbimọ to risi igbakoso ijoba, ti Ademọla Adeleke gbe kalẹ ti ṣapejuwe igbanisiṣẹ iṣẹju to kẹhin ti ijọba Oyetọla bẹrẹ, gẹgẹ bi ete lati fa ọwọ ijọba to n bọ sẹ́yìn.

Atẹjade kan ti Olawale Rasheed, Alaga igbimọ eto iroyin fun Ademola Adeleke gbe jade, ṣalaye pe igbimọ naa ṣe akiyesi pe ni oṣu meji sẹhin, iṣakoso Oyetola ti gba ẹgbẹẹgbẹrun oṣiṣẹ láìṣe akiyesi òṣùwọ̀n ijọba ipinlẹ Ọṣun.

 Rasheed wa rọ awọn to n wa iṣẹ lati yago fun iru isẹ yii nitori ijọba Ademọla Adeleke ri igbanisiṣẹ yii gẹgẹ bii ọna lati sakoba fun ijọba to n bọ.