Á ti palẹ̀ gbogbo agbébọn mọ́ títí oṣù Kejìlá - Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, @raufaregbesola
Ijọba orilẹede Naijiria ti fọwọ sọya pe oun yoo palẹmọ awọn agbebọn mọ, ko to di oṣu kejila ọdun 2022.
Minisita fun ọrọ abẹle, Rauf Aregbesola lo fi ọrọ naa mulẹ nibi ipade kan to waye pẹlu minisita to n risi awọn ọmọ ologun ati ileeṣẹ ọlọpaa.
Aregbesola wa fi da awọn orilẹede Naijiria loju pe, ọrọ eto aabo wọn lo jẹ ijọba apapọ logun pupọ ju.
“Eyin ọmọ Naijiria, a fi da yin loju pe ko si laburu nipa eto abo yin.
Pẹlu asẹ lati ọdọ aarẹ, ko to di oṣu kejila, ọrọ abo to mẹyẹ ni yoo ti di ohun igbagbe lorilẹede Naijiria.
“Pupọ lara awọn to doju kọ wa ro pe awọn ni agbara lati ba orilẹede yii jẹ sugbọn ipinnu wa ni lati yanju gbogbo wọn lapapọ.
Eyi si ni yoo mu ki alaafia pada si Naijiria ko to di inu oṣu kejila ọdun yii."
Ipinnu wa niyẹn, kii se ọrọ awada rara - Aregbesola
“Ọrọ naa dabi awada sugbọn ipinnu wa niyẹn, ti idabobo dukia ati ẹmi awọn eeyan si jẹ wa logun.
Ọrọ ti jade pẹlu asẹ Aarẹ Buhari.”
Aregbesola fikun pe itankalẹ arun Covid 19 wa lara ohun to ṣe okunfa bi eto aabo ṣe mẹyẹ ni Naijiria.
“A ko ni dẹkun didabo bo ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria ati awọn ajoji to wa larin wa.
A ri daju pe alaafia jọba lorilẹede, a ko ni sinmi lati maa palẹ awọn agbebon to wa larin wa mọ.”
Ọ̀pọ̀ agbébọn ti wà lori ere, a ti rẹyin wọn - Lai Muhammed
Bakan naa ni minisita fun eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed ni ipenija eto abo ti di ohun igbagbe lorilẹede yii
O ni eyi ri bẹẹ nitori ijọba apapọ ti ṣetan lati gbogun ti awọn agbegbọn, ti ọpọ wọn si ti wa lo ri ere.
“Gbogbo wa ni a mọ pe ipenija eto abo ti ba ibasepọ awọn ọmọ orilẹede yii jẹ nitori igba ikẹyin ti irufe iṣẹlẹ yii waye ni ọdun 1967 si 1970.
“Ki n ṣe orilẹede Naijiria nikan lo doju kọ ipenija eto abo sugbọn a dupẹ lọwọ Aarẹ Bubari.
“Ni bayi, Mo n sọ fun yii pe gbogbo ikọlu awọn agbegbọn lo di ohun igbagbe lorilẹede Naijiria.
“Ẹ ma si mi gbọ, o sese ki a si ma ri awọn ikọlu sugbọn ko le to ti tẹlẹ mọ.
“Awọn agbebọn yii ko sa mọ wa lọwọ, eyi ti fara han lẹyin ti a mu awọn to ṣe ikọlu sile ijọsin kan ni Owo.”
















