Auxilliary fèsì lórí ìkọlù tó wáyé sí ọmọ Aláàfin

Alaga igbimọ to n ṣe akoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, Alhaji Mukaila Lamidi, ti ọpọ mọ si Auxilliary, ti sọrọ lori ẹsun ti ọmọ Alaafin, Akeem Adeyemi fi kan pe o ṣe ikọlu si oun.
Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin wa fun yin laipẹ yii pe awọn janduku kan kọlu Ọmọọba Adeyemi, ti eeyan mẹrin si fara pa.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Adeyemi ni awọn afurasi janduku to kọlu oun wọ asọ awọn ọmọ ẹgbẹ alakoso gareeji nipinlẹ Oyo labẹ Alhaji Mukaila Lamidi.
Idi ree ti BBC Yoruba fi tiraka lati gbọ tẹnu Alhaji Mukaila Lamidi, ti ọpọ eeyan tun mọ si Auxilliary, ko le salaye tiẹ naa lori isẹlẹ yii.
Akeem Adeyemi ko ni ẹri pe wọn se ikọlu si oun nitori ikọlu kankan ko waye - Auxilliary
Auxilliary, ẹni tiamugbalẹgbẹ rẹ, Adekunle Gaisu gba ẹnu rẹ sọrọ ni, irọ to jina si ootọ ni ẹsun naa nitori ko si nkan to jọ mọ bẹẹ.
O ni ko si nnkan to jọ mọ pe awọn ẹgbẹ awakọ tabi olori wọn ṣe ikolu si ẹni kankan.
Gaisu salaye pe ko si ẹri kankan lati fi idi isẹlẹ naa mulẹ tabi pe awọn ọmọ ẹgbẹ Auxilliary lo ṣe ikọlu naa.
“Ti nnkan bayii ba ṣelẹ, o yẹ ki a ri bi nnkan bayii se waye sugbọn ko si nkan to jọ mọ bẹẹ rara.
“Ibi ti wọn ni nkan ti sẹlẹ, ko si nkankan to jọ mọ pe ẹnikẹni ṣe ikọlu si ọmọba Adeyemi nibẹ nitori ko si nkankan nibẹ.
“Ko si ibi nnkan naa maa ṣe ṣelẹ ti ko fi ni da oju ẹni kan mọ."
‘Iwadi ti bẹrẹ lati mọ hulẹhulẹ isẹlẹ naa to ba jẹ pe ootọ lo waye’
“Ọrọ yii dun Auxilliary gan nitori ẹni to ti ni orukọ ti wọn fẹ ba orukọ rẹ jẹ ni .
“Koda, iwadi ti bẹrẹ lori ẹsun naa lati sawari awọn ti wọn n ṣe ikọlu si Asofin ọhun sugbọn awa mọ pe irọ to jina si ootọ ni.”
Ọjọ Satide si ni isẹlẹ naa waye lagbegbe Alakia nilu Ibadan lasiko ti Ọmọọba Adeyemi n bọ lati ilu Ile Ife pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ kan.
Eeyan mẹrin ni asofin Adeyemi sọ pe o fara pa ninu isẹlẹ naa, to si ti gbe wọn lọ sile iwosan.
Àlàyee ree lori bi ọmọọba Akeem Adeyemi se ni awọn agbebọn kọlu ou

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Awọn gende agbebọ̀ọn kan ti kọ lu Họnọrabu Akeem Adeyemi, to jẹ ọmọ Alaafin Ọyọ to waja laipẹ yii.
Adeyemi, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ naa, sọ iriri rẹ nipa awọn agbebọn to kọ lu u.
Adeyemi wa fi ẹsun kan awọn ọmọlẹyin alaga ẹgbẹ to n se akoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo, Alhaji Mukaila Lamidi, ta tun mọ si Auxiliary.
Asofin naa ni awọn ọmọ ẹyin Auxilliary yii lo ṣe ikọlu si ọkọ oun.
Ọjọ Satide si ni isẹlẹ naa waye.
Adeyemi ni awọn eniyan to wa ninu ọkọ oun naa lo fara pa yanna-yanna.
O ni o ṣeeṣe ko jẹ nitori akọle ẹgbẹ oṣelu APC to wa lara ọkọ oun ati aworan Tinubu to wa nibẹ, lo jẹ ki wọn ṣekọlu si oun.
Bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye ree...
Ọmọọba Adeyemi ni awọn n bọ lati ibi ayẹyẹ kan, ni wọn ṣekọlu si awọn ni agbegbe Alakia, bi wọn ṣe n wọnu ibadan lati Ile Ifẹ.
Awọn janduku to fẹsun kan pe wọn ṣekọlu si wọn naa ni wọn yabo wọn pẹlu ọga wọn to wa nibẹ.
Awọn afurasi janduku naa si lo ni wọn wọ asọ awọn ọmọ ẹgbẹ to n se akoso gareeji ọkọ nipinlẹ Oyo to wa labẹ akoso Auxilliary.
‘’N ṣe ni wọn bọ si ori titi, ti wọn si bẹrẹ si sa awọn eeyan mi ni ada.’’
A ti wa ni ibadan tan, ti wọn bẹrẹ si ni pariwo ole! Ole! ẹ pa wọn, ẹ ṣe wọn leṣe’’
‘’Awọn eniyan wa gbiyanju lati sa kuro nibẹ, ki wọn doola ẹmi wọn amọ awọn kan farapa’’
O to eniyan mẹrin ti a gbe lọ si ileewosan nigba ta de Ọyọ.
Bakan naa lo fikun un pe wọn ti fi isẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo leti.
Ki ni alaye Auxilaary lori isẹlẹ yii?
BBC Yoruba tun kan si Auxilaary ti Adeyemi fi ẹsun kan, lati gbọ tẹnu rẹ.
Amọ gbogbo iyanju wa lati pe e lori foonu rẹ lo ja si pabo nitori ko gbe ipe wa.
Ninu ọrọ tirẹ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ to n se akoso ibudokọ gareeji nipinlẹ Oyo, PMS, ni awọn ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ naa.
O ni awọn yoo ṣewadii ni ẹkunrẹrẹ, ti awọn yoo si sọrọ lori rẹ laipẹ.
Bakan naa ni alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo ko gbe ipe wa lati salaye lori isẹlẹ naa.
















