Ọmọ onílé márùn-ún yìnbọn mọ́ ọlọ́pàá l‘Eko, iléẹjọ́ fi wọ́n pamọ́ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Lagos state task force
Igbimọ amusẹya to n gbógun ti fifi tipátipá gba ilẹ ni ipinlẹ Eko ti mu eniyan marun-un lori ẹsun fifi tipa tikuuku gba ilẹ lọna aitọ.
Alaga igbimọ amusẹya naa, Shola Jejeloye ṣalaye pe awọn afurasí naa, ninu ẹ̀yi ti obinrin wa lara wọn, ni wọn maa n daamu awọn agbegbe bi Sangotedo, Lakowe, Abijo atawọn agbegbe mii ni aadugbo Ibeju Lekki.
Jejeloye ṣalaye pe ọpọ igba ni awọn kilọ fun awọn ti wọn pe ni "ọmọ-onilẹ " láti dẹ́kun iwa ọwọ́ wọn.
Alaga igbimọ amusya ọhun ni bi o tilẹ jẹ pe wọn yinbọn lu awọn ọlọ́paa, sugbọn agbara awọn ọlọ́paa bori wọn.
A ri ìbọn, ada, oogun abẹnu gọngọ ati awọn ohun ija oloro mii gba lọwọ awọn afurasi - Ọlọpaa
Lara awọn eroja ti ileesẹ ọlọpaa ri gba lọwọ awọn afurasi naa ni ìbọn, ada, oogun abẹnu gọngọ ati awọn ohun ija oloro mii.
Jejeloye wa rọ awọn olugbe ipinlẹ Eko lati dẹkùn sisan owo aitọ, ki wọn sì fi ẹjọ́ awọn ọmọ onílẹ tó ikọ agbofinro leti.
Awọn afurasí marun-un naa ti fi oju ba ile ẹjọ́, tì ile ẹjọ si pasẹ pe ki wọn fi wn pamọ si àtìmọ́lé nilu Badagry.











