Lady Driver: Obìnrin awakọ̀ èrò ní òun fẹ́ figa-gbága pẹ̀lú ọkùnrin lòun ṣe ń wa dáńfó
Yoruba ni oun ti ọkunrin le se, obinrin gan le se dara ju ọkunrin lọ.
Eyi gan lo mu ki obinrin kan to n wa ọkọ ero danfo nigboro Eko, Yetunde Amole Muhammed, fi gba idi isẹ awakọ ero danfo lọ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Yetunde ni ọkọ oun gan kọkọ n beere pe bawo ni oun se fẹ se e amọ o ni oun mọ pe obinrin bi ọkunrin ni oun.
Obinrin awakọ danfo naa ni ero ọpọ ọkunrin ni pe awọn obinrin ko le se ọpọ isẹ ti awọn n se, eyi ti ko ri bẹẹ rara.
Àwọn iròyin iṣẹ́ akọ táwọn obìnrin ń ṣe tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ebi sọ ìyá àgbà di awa kẹ̀kẹ́ Maruwa ní Ibadan, 'Grandma' ní wọ́n kọ̀ láti máa ṣagbe jẹun!
- Kí inú màmá mi le dùn ni mo ṣe kọ́ iṣẹ́ ọkọ̀ kíkùn - Modupe Olagunju
- Ọkọ̀ dáńfó tí mò ń wà ní mo fi kọ́lé, rán ọmọ mẹ́ta ní fásitì - Obìnrin àkọ́kọ́ tó ń wa dáńfó l‘Eko
- Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú kí n máa pọ́líìṣì bàtà ní N30, mo ti kàwé gboyè pẹ̀lú ẹ̀ báyìí - Amope Onibata
- Aṣọ ni mò ń tà tẹ́lẹ̀, ìgbélé Covid-19 ló sọ mí di awakọ̀ kabúkabú - Adebunmi Adeyeye
Bakan naa lo salaye pe o ti to ọdun mẹfa si meje ti oun ti wa nidi isẹ awakọ ero naa, kẹkẹ maruwa si ni oun fi kọkọ bẹrẹ.
O ni oun tun bọ si ori wiwa ọkọ korope, ki oun to wa bọ sori wiwa ọkọ Danfo.
Awọn ọkunrin maa n pe mi ni aṣẹwo, fọwọ rọ mi sẹyin nidi isẹ awakọ ero – Yetunde Muhammed
Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Yetunde sọ ọpọ ipenija to n ba pade lọdọ awọn ọkunrin ti wọn dijọ n sisẹ ni gareeji danfo.
Obinrin awakọ ero naa ni se ni awọn ọkunrin maa n pe oun ni asẹwo nitori pe oun n ba wọn sisẹ awakọ ero.
Koda, o ni ọkan ninu wọn gan sọ fun oun pe oun ko le fi ara mọ pe ki obinrin maa figa gbaga pẹlu oun lẹnu isẹ naa.
“Awọn ọkunrin tun maa n tabuku mi lẹnu isẹ awakọ yii, wn yoo pe mi ni asẹwo, wọn si tun n fi ọwọ rọ mi sẹyin nitori pe mo jẹ obinrin’
Awọn miran ninu wọn gan maa n fẹ ti mi sinu gọta nitori pe mo jẹ obinrin to n wa danfo loju popo.
Amọ mo maa n jẹ ki wọn mọ pe ọpọlọ ti wọn fi gba asẹ iwe irinna, naa ni emi naa lo lati gba ti emi.
Bakan naa ni awọn ero ọkọ maa n sọrọ sakasaka si mi amọ o yẹ ko ye wọn pe kii se gbogbo onidanfo lo jẹ alaimọkan tabi ọmuti”
Yetunde ni ero awọn ọkunrin naa ni pe ki ile idana lo yẹ ki obinrin wa, kii se ko wa maa se awọn isẹ tawọn ọkunrin n se.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo gbìyànjú láti ṣẹ́yún àkọ́bí mi saájú ìgbeyàwó - Iyabo Ojo
- Ohun tí ojú mi rí rèé lọ́wọ́ àwọn amojúẹ̀rọ lásíkò yíya sinimá - Adunni Ade
- "Aṣọ ni mo fẹ́ máa tà tẹ́lẹ̀, ọkọ́ mi ló ní kí ń kọ́ iṣẹ́ Káfíńtà àmọ́ ń kò kábàmọ́ọ̀"
- "Bàbá mi lòdì sí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ tí mò ń ṣe àmọ́ lónìí, ó ń mú owó ńlá wá fún mi"
- N kò fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ló mú mi máa wa ọkọ̀ taxi - Obìnrin tó ń wa ọkọ̀ èrò
‘Lara awọn aseyọri mi ni pe mo n ran ọkọ mi lọwọ, mo ti ra ilẹ, mo si n kọ ile lọwọ nidi isẹ awakọ danfo’
Nigba to n salaye awọn aseyori rẹ nidi isẹ awakọ danfo to yan laayo, Yetunde ni oun n ran ọkọ oun lwọ lati gbọ bukata to ba suyọ lori awọn ọmọ awọn.
O ni oun tun n ran ọkọ oun lọwọ lati sanwo ile, ti oun si tun n ko ọpọ ipa ribiribi ni awujọ ti oun wa nitori ọkọ nikan ko le da gbọ bukata lori idile.
Bakan naa lo sọ pe oun ti ra ilẹ, ti oun si tun ti n kọ ile sori rẹ, eyi ti oun gbagbọ pe yoo pari laipẹ.
Obinrin awakọ danfo naa ni awọn akẹkọọ mejidinlọgbọn ni oun maa n gbe lọ sile ẹkọ ni araarọ.
O fikun pe oun tun maa n gbe awọn ero mii lọ sibi isẹ, to si ni oun se ọpọ aseyọri pupọ nidi wiwa ọkọ danfo ti oun yan laayo.
‘Mo n rọ awọn obinrin to n joko sile lai sisẹ lati wa nnkan se’
Yetunde Amole Muhammed wa gba awọn obinrin nimọran pe ọkunrin ko le da gbogbo isẹ ile se.
O ni o yẹ ki obinrin fi ọwọ sowọpọ pẹlu ọkọ rẹ ni lati gbọ bukata to ba wa ninu ile.
Yetunde ni “Gbogbo obinrin ti kii ba sisẹ owo, amọ ti wọn n joko sile ki ọkọ mu owo wale, lo yẹ ki wọn tun ero wọn pa.
Se lo yẹ ki wọn lọ wa isẹ se, wọn lee maa ta omi inu ọra, sisẹ sise bata tabi se ọsẹ lati pawo wọle.
Emi tẹ n wo yii gan, mo tun n se ọsẹ ti wọn fi n fọ mọto fun awọn to n fọ ọkọ.”




