Amope Onibata: Kìí ṣe gbogbo ọkùnrin ló gbà kí ń ṣe bàtà fún àwọn

Àkọlé fídíò, Amope Onibata: Kìí ṣe gbogbo ọkùnrin ló gbà kí ń ṣe bàtà fún àwọn

Ori lo mọ isẹ asela, ohun ti ọkunrin ba si se, obinrin naa le se daradara nigba mii.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu akẹkọjade fasiti ipinlẹ Ekiti, Olamide Adeyemi, ti ọpọ eeyan mọ si Amope Onibata.

Olamide, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe iyansẹlodi ẹgbẹ awọn olukọ fasiti lo mu ki oun gbero lati kọ isẹ bata sise, ti oun si le se oniruuru bata bayii.

O ni oun kọkọ bẹrẹ isẹ naa nipa biba awọn ọlọpa dan bata wọn pẹlu pọlisi, ti oun si n ri owo nibẹ

Amope Onibata ni oun maa n se idanilẹkọ fun awọn obinrin ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ lọfẹ fun ọsẹ meji tabi ju bẹẹ lọ lati se iwuri fun wsn nipa isẹ bata sise.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Akẹkọjade fasiti naa wa rọ awọn obi lati jẹ kawọn ọmọ wọn kọ isẹ ọwọ mọ iwe, ki wọn si tun se iwuri fun wọn lori isẹ ti wọn ba yan laayo naa.