Ikú Djxgee: DJsosogee ní olóògbé fẹ́ràn ẹbí àti ọmọ

Oríṣun àwòrán, @djxgee
Lẹyin ti okiki kan pe gbajugbaja aforin-danilaraya nibi ayẹyẹ, DJ Seun Ọmọgaji, ti ọpọ mọ si DJXGee ti gbẹmi ara rẹ lẹyin wakati diẹ to fi atẹjade kan sita lori ikanni ayelujara Instagram rẹ ni ọjọru, ọpọ awọn ilumọọka adanilaraya ni wọn ti n ṣe idaro rẹ.
Ninu awọn to ti ṣedaro rẹ ni awọn adẹrin poṣonu bii Alibaba, Bovi, Seyi law, Ushbebe ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Amọṣa, ọkan lara awọn ọrọ rẹ, Moshood Abiọdun, ti ọpọ eeyan mọ si DJ Sosogee, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe, eeyan ti o fẹran lati maa mu inu awọn eeyan to wa layika rẹ dun ni Djxgee.
O fikun pe o fẹran lati maa 'fi ibanujẹ ara rẹ sẹgbẹ kan lati mu inu awọn eeyan ti o ba ba pade dun.'
Sosogee ni oun ko ri idi kan fun Djxgee lati pa ara rẹ nitori iṣẹ to fẹran naa lo n ṣe, ti o si jẹ awokọṣe fun ọpọlọpọ awọn eeyan, paapaa julọ awọn aforin-danilaraya nibi ayẹyẹ, iyẹn DJ ẹgbẹ rẹ.
Amọ ju gbogbo rẹ lọ, DJ Sosogee ni ohun kan ti ko ṣee gbagbe ni pe, oloogbe DJXgee jẹ ẹni ti o fẹran awọn ọmọ rẹ gidigidi ti ko si fi ẹbi rẹ ṣere rara.
" O fẹran awọn ọmọ rẹ, bi ẹ ba wo awọn oju opo ayelujara rẹ gbogbo, ẹ o ba aworan awọn ọmọ rẹ nibẹ, bẹẹ naa lo jẹ ẹni to fẹran ẹbi, iyawo ati ọmọ rẹ gidigidi."
Amọṣa, DJ Sosogee ni oun ko lee sọ boya 'nitori iyawo rẹ fi ile silẹ tabi nitori awọn ẹbi rẹ toju bọ ọrọ wọn' lo ṣokunfa bi o ṣe gbẹmi arar rẹ.
Bakan naa, ninu ọrọ tirẹ, Afọlabi Ọlalekan to ni oun jẹ ọkan lara awọn akẹkọ to lọ si ileewe kan naa pẹlu oloogbe naa ṣalaye pe, eeyan ti o fẹran lati maa saapọn fun igbayegbadun awọn eeyan to ba wa ni ayika r ni Djxgee jẹ.
Olalekan sọ pe, DJXgee ni 'baba isalẹ' iyẹn 'School father' fun oun lasiko ti wọn wa ni ile iwe girama.
Ẹwẹ, awọn sanmọri lagbo idanilaraya lorilẹede Naijiria pẹlu ti sọrọ nipa rẹ lori ikanni ayelujara.
Basket mouth to ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii 'ẹjẹ'rẹ ati 'ọrẹ'rẹ sọrọ nipa awọn asiko manigbagbe ti wọn jumọ ni.
Bakan naa Seyilaw sapejuwe rẹ gẹgẹ bii ọrọ ti wọn jumọ lọ si ile iwe ti iṣẹ amuludun si tun pa wọn pọ daro rẹ. O ni awọn ṣi jọ wa pọ ni ọjọ abamẹta.
Djxgee kede iku ara rẹ lori Instagram ko to gbe majele jẹ
Adura gbogbo ọmọ Naijiria ni pe ki Ọlọrun da ẹmi awọn si lati se ọpọ ọdun laye ni kete taa wọ inu ọdun tuntun 2019.
Amọ eyi ko ri bẹẹ fun ọkunrin kan to gbajugbaja ninu isẹ gbogbo elere fun orin taka-sufe, Seun Ọmọgaji, taa mọ si DJ Xgee.
Ọjọ keji ọdun tuntun ni ọkunrin naa ge okun ẹmi ara rẹ kuru, to si gbe oogun apakokoro jẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹni to lee sọ pato ohun to mu ko pa ara rẹ gẹgẹ bi o se kede lori Instagram, iroyin sọ pe iyawo rẹ, lo sadede ko kuro ninu ile fun-un, eyi to sokunfa orisun ibanujẹ nla fun.
Sugbọn ohun ara meeriri ti Djxgee se, ko to ki aye pe o digbose ni pe, o lọ si oju opo ikansira ẹni rẹ loju opo Instagram, to si kọ sibẹ pe, asọ funfun ni ohun fẹ kawọn eeyan wọ fi se ọfọ oun, tori oun ko nifẹ asọ dudu rara, o ni o duro fun asọ ọfọ.
Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to ti mu kii ẹrin pa ẹẹkẹ rẹ latẹyinwa, , to si tun n ki awọn ọmọ rẹ ni ọkọọkan pe oun nifẹ wọn, to fi mọ iya to bii.

Oríṣun àwòrán, @djxgee
"Iyatọ yoo ba ọna tawọn eeyan fi maa n se ẹyẹ ikẹyin fun ololufẹ wọn to ba rekọja lọ.... Asọ dudu duro fun ibanujẹ, sugbọn fun ti emi, asọ funfun ni kẹ wọ, tori mo nifẹ asọ funfun pupọ̀.
Fun gbogbo ẹyin ti mo ti pa rẹrin ri, ati ẹyin ti mo ti mu binu, ẹ gba pe ẹlẹran ara ni mi. Ẹnikorewa, mo nifẹ rẹ pupọ, Ẹniayọ, orukọ rẹ ti salaye ọrọ, iwọ gan ni orisun ayọ mi.
Ọmọbọlanle Ajọkẹ, se o mọ pe mo naani rẹ..... Moradekẹ iya mi, Ọlọrun yoo wo ọgbẹ ọkan yin san ati awọn ana mi. Ki Ọlọrun bu kun yin ni gbogbo igba."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post















