Pistachio Green Puppy: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí òun sì jẹ́ aláwọ̀ ewé

Àkọlé fídíò, Pistachio Green Puppy: Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ aláwọ̀ funfun, tí òun sì jẹ́ aláwọ̀ ewé

Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, ti eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibilẹ jẹun.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọmọ aja kan ti wọn n pe ni Pistachio, ẹni to gbe awọ eweko pọnbele wa sile aye.

Awọn akẹẹgbẹ rẹ ti wọn dijọ bi wọn saye ni ọjọ kannaa ni awọn funfun amọ oun nikan lo ni awọn eweko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

N jẹ ki lo de ti eyi fi ri bẹẹ?

Iwadii BBC fihan pe ọmọ aja alawọ eweko naa lo fi ara kan ile ọmọ iya rẹ, pẹlu ẹran ara rẹ.

Awọn awọ ewe si han ketepe lara ọmọ aja naa nigba ti wọn bi saye sugbọn o ti n parẹ bayii.

Bi o tilẹ jẹ pe olowo aja naa ta awọn akẹẹgbẹ Pistachio to ku, amọ o kọ lati ta sita nitori awọ eweko to ni.

Igbagbọ rẹ ni pe awọ ewe jẹ apẹẹrẹ ireti nigba isoro.