Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

Àkọlé fídíò, Babatunde Adejumo: Ọdún méje ní mi fi sá kúrò nídìí iṣẹ́ aṣerunlọ́sọ̀ọ́ àmọ́ mo padà

Ko si ohun ti ọkunrin n se, ti obinrin ko le se, bẹẹ naa si ni ko si ohun ti obinrin n se, ti ọkunrin ko le se.

Bayii lo se ri fun Adejumo Babatunde, ẹni to yan isẹ aserunlọsọ laayo bi o tilẹ jẹ pe ọkunrin ni, to si kẹkọọ jade nile ẹkọ giga.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori ohun to gbe de idi isẹ naa, Babatunde ni oun nifẹ si isẹ naa, ni oun se yan laayo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, 'Láti kékeré mo ti ní ọjọ́ kan lèmi náà ọ́ kọ́ Mọ́sálásí kékeré bíi àwọn bàbá wa'

O salaye pe ile ẹkọ giga ni oun wa ti oun ti bẹrẹ isẹ naa, ti ọpọ obinrin si maa n nifẹ si pe ki oun ba wọn se irun.

Amọ o ni baba oun korira isẹ ti oun yan laayo naa nitori pe o kawe pupọ, to si nifẹ si isẹalakọwe.

Lara ipenija ti mo koju ni pe awọn eeyan ro pe n ko le se rere ninu isẹ onidiri:

Nigba to n mẹnuba awọn ipenija to koju rẹ, koto lu aluyọ, onidiri igbalode naa ni oju abuku tawọn eeyan fi maa n wo isẹ naa nipa lara oun.

“Ọdun meje ni mo fi sa kuro nibi isẹ onidiri igbalode nitori pe mo tẹti si ohun tawọn eeyan n sọ.

Amọ nigba tawọn ọrẹ mi to n se isẹ miran sọ isoro ti wọn n koju, ti wọn si ni isẹ temi dara, mo tun pada sidi rẹ.

Obinrin kan ti mo lọ ba se irun gan bi mi lọjọ kan pe se mo si lero pe mo le de ibi giga nidi isẹ onidiri ti mo yan laayo naa.

Ọrọ yii fa ironu si mi lara amọ mo dupẹ lonii pe isẹ naa ti n mu owo gidi wa, to si ti di nnkan nla.”

Gbogbo nnakan ni ayika mi lo maa n fun mi ni imisi lati ya batani irun:

Adejumọ Babatunde, nigba to n salaye awn ohun to n fun ni itọni tabi imisi lati gbe batani irun to rẹwa joko, o ni imisi nla ni.

O salaye pe awọn ihun to wa ni ayika oun lo maa n se atọna bi batani irun toun fẹ se lọsọ yoo se ri.

O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ọkunrin to jẹ onidiri ko pọ nigba ti oun bẹrẹ isẹ amọ wọn ti pọ nidi isẹ naa bayii.

O wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe isẹ ti awọn eeyan korira tẹlẹ ti wa di itẹwọgba, to si ti n mu owo nla wle fun oun.