Pools Betting: Lisa Walker ní òun ta ilé láti fi ta tẹ́tẹ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ owó ńlá, tí òun kò sí rí ilé gbé

Lati igba to ti wa ni ẹni ogun ọdun le diẹ, ni Lisa Walker ti bẹrẹ si ni ta tẹtẹ diẹdiẹ.
Nigba ti yoo si fi pe ọgbọn ọdun, tẹtẹ tita di aigbọdọ ma ṣe fun lẹyin to jẹ owo nla kan.
Ni alẹ ọjọ kan lo jẹ ẹgbẹrun mẹtadinlaadoje Pọun. Amọ dipo ki inu rẹ o dun, Arabinrin Lisa sọ pe ọjọ naa ni ọjọ to buru ju lọ ni igbesi aye oun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọbabìnrin Elizabeth kéde pé kí Camilla di ayaba tí ọkọ rẹ, Charles bá gun orí ìtẹ́
- Jaigbade Alao, àgbà ọ̀jẹ̀ olórin dadakuàdà tó fiṣẹ́ orin sílẹ̀ ní Ilorin lẹ́ni ọgọ́fà ọdún
- ''Àwa ẹgbẹ́ Agbekoya ṣetán láti tú Sunday Igboho sílẹ̀ lẹ́wọ̀n pẹ̀lú agbára àwọn àgba''
- Ènìyàn 24 dágbére fáyé, 9 farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abuja, Yobe
- Ìdíje fún sísọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá nílé ẹ̀kọ́ girama dí "Millionaire" lọ́dọọdún gbéra sọ- Yoruba World Centre
- Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ ilẹ̀ America fi sún ọjọ́ ìdájọ́ Hushpuppi síwájú
- Dominic Adigezi àti ọmọ rẹ̀ mẹ́ta kú sínú oko ní Abuja, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Kilo fa ogun sinu aye ololufẹ tẹtẹ tita?
Lisa sọ pe owo iyebiye ti oun jẹ nidi tẹtẹ lọjọ naa lo pilẹ bi oun ṣe di ogbontarigi onitẹtẹ, to si di nkan ti oun ko le ṣai ma ṣe.
"Ile tẹtẹ ti mo ti ta fẹ ki n pada wa. Koda, wọn sọ pe gbogbo nkan ti mo ba fẹ ni awọn yoo fun mi - ounjẹ ọfẹ, nkan mimu.
O ni oun ma n lọ sibẹ ni gbogbo igba, ti oun yoo si ma a paara gbọngan ti wọn ti n ta tẹtẹ titi yoo fi darapọ mọ wọn.
"Ọpọlọpọ igba ni ma a dede ronu pe mo fẹ ta tẹtẹ, ti ma a si ta. O de ipele pe ko si owo ti mi o le fi ta tẹtẹ bo ti wu ko pọ to."
Ni igbẹyin, Lisa padanu gbogbo owo to jẹ. Koda, o padanu ile rẹ lẹyin to ta ile naa lati fi ta tẹtẹ.
Iṣẹlẹ naa sọ oun ati ọmọ rẹ mejeeji di alainilelori. Awọn ọmọ naa ko ju ọdun mẹwaa ati mọkanla lọ lasiko naa.
Tẹtẹ ni Lisa n fi gbogbo owo rẹ ta titi to fi pe ẹni ọdun marunlelogoji.

Oríṣun àwòrán, Lisa
Ní alẹ́ ọjọ́ ìgbéyàwó mi, mo fi ọkọ mi sil lati lọ ta tẹ́tẹ́:
Iwa yii buru debi pe ni alẹ ọjọ igbeyawo rẹ, o fi ọkọ silẹ sile, o si lọ si ile tẹtẹ.
Igba to pada sile ni iye rẹ ṣi pe o nilo iranlọwọ nitori pe ko si ironu kankan to n ro ju tẹtẹ tita lọ.
Eyi lo mu ko darapọ mọ ajọ kan to n sẹ ayipada ọkan fun awọn to ti sọ tẹtẹ tita di baraku.
Lọwọlọwọ, Lisa ti n gba itusilẹ diẹdiẹ, ti oun naa si ti di ẹni to n polongo ikiyesara fun tẹtẹ tita.
O ni "Tẹtẹ tita lori ayelujara lo tubọ mu ko di baraku fun ọpọlọpọ eniyan, nitori pe anfaani wa fun wọn lati ta a ni igba to ba wu wọn."
Awọn eeyan bi Lisa pọ kaakiri agbaye.
Onimọ kan nipa bi tẹtẹ tita ṣe ma n di baraku fun awọn obinrin ni UK, Liz Karter, sọ pe ọna ọtọ ni ẹmi tẹtẹ fi ma n jẹyọ lara awọn obinrin ju ọkunrin lọ.
O ni bo ṣe ti rọrun bayii lati ta tẹtẹ lori foonu ti mu ko wu ọpọ obinrin, nitori pe wọn o ri ohunkohun to buru ninu rẹ.
"O dabi nkan ti ko buru rara, bi igba ti eeyan n gbá geemu lori foonu ni."
O ni ireti owo rẹpẹtẹ tun jẹ nkan pataki to n mu ki tẹtẹ wu eeyan lati ta.
O ni bo tilẹ jẹ pe tẹtẹ tita ko lewu, ṣugbọn o ṣe pataki ki awọn obinrin mọ pe ewu ti wa nigba ti wọn ba ti n jẹ gbese nitori tẹtẹ. Tabi ti wọn ba ti n fi tẹtẹ tita pa ironu iṣoro wọn rẹ.
Ni orilẹ-ede UK, ipolongo ti n lọ lati ṣe irapada awọn obinrin to le ni miliọnu kan, ti tẹtẹ tita ti di aigbọdọ ma ṣe fun.
Awọn apẹẹrẹ pe tẹtẹ tita ti fẹ ṣe ijamba fun ọ:
- Tita tẹtẹ ju iye ti agbara rẹ ka
- Yiya owo lati ta tẹtẹ
- Nini ipaya tabi idalẹbi nipa tẹtẹ
- Fifi tẹtẹ ti o n ta pamọ fun awọn to sunmọ














