Zamfara Bandits Attacks: Agbébọn pa ogún èèyàn torí wọn kò rí N40m ìsákọ́lẹ̀ abúlé wọn san

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army HQ
Se ni ipinlẹ Zamfara kan gogo lọjọ Ẹti nigba ti awọn gende agbebọn gbẹmi eeyan to le ni mẹtalelọgbọn ti wọn ji gbe ni awọn ọpọ abule.
Ọ́pọ awọn eeyan ti wọn pa naa si lo jẹ obinrin, ti wọn si ji pupọ ninu wọn gbe kaakiri awọn abule to wa nipinlẹ Zamfara.
Gẹgẹ iroyin naa se wi, awọn agbebọn naa dana ibọn fun awọn eeyan to le ni ogun ni abule Nasarawa Mai Fara.
- "Sunday Igboho yóò jáde ní àhámọ́ láìpẹ́, ariwo ayọ̀ yóò sọ nílẹ̀ Yorùbá"
- ''Ọjọ́ ti mo jẹ́ £127,000 nídìí tẹ́tẹ́, ni ogun ọjọ́ pípẹ́ bẹ̀rẹ̀ nínú ayé mi''
- Mọ̀lẹ́bí kéde ìsìnkú Tafa Oloyede, bí yóò ṣe lọ rèé
- Ta ni yoo gba ife ẹyẹ AFCON laarin Mane ati Salah?
- Ọbabìnrin Elizabeth kéde pé kí Camilla di ayaba tí ọkọ rẹ, Charles bá gun orí ìtẹ́
- Ènìyàn 24 dágbére fáyé, 9 farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abuja, Yobe
- Jaigbade Alao, àgbà ọ̀jẹ̀ olórin dadakuàdà tó fiṣẹ́ orin sílẹ̀ ní Ilorin lẹ́ni ọgọ́fà ọdún
Ki ni awọn eeyan naa se ti awọn agbebọn fi pa wọn:
Idi ni pe wọn ni awọn eeyan naa kuna lati san ogoji miliọnu ti awọn agbebọn ọhun n beere fun gẹgẹ bii owo isakọlẹ ti wọn n beere fun ni abule wọn.
Iwe iroyin Premium Times ni gbajumọ baalẹ awọn agbebọn kan, Ada Aleru lo gbe owo isakọlẹ naa le awọn abule yii lori ati ni apakan ipinlẹ Katisina.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, ara abule kan ni aile san owo isakọlẹ naa lo mu ki awọn agbebọn yii fi ibinu ran awọn eeyan to wa nigbekun wọn sọrun ọsan gangan.
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe ogun eeyan ni wọn pa lọjọ Ẹti nikan.
Nibo ni eto aabo ẹkun ariwa Naijiria de duro?
Ipinlẹ Zamfara to wa ni ẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria lo n fi oju wina ipenija eto aabo gẹgẹ bi awọn ipinlẹ yoku lapa Oke Ọya.
Awọn agbebọn lo n fi ojoojumọ ji awọn araalu gbe lapa ariwa Naijiria, wọn n fi tipa ba awọn obinrin lopọ, digunjale tabi gba owo itusilẹ lọwọ awọn ti wọn ji gbe.
Awọn isẹlẹ yii lo si n peleke si, ti aayan awọn alasẹ ati osissẹ agbofinro lati wa ọwọ iwa buruku yii wọlẹ, ko si fi bẹẹ ni ipa lori wọn.
Ọkẹ aimọye awọn eeyan ni awọn agbebọn yii ti ji gbe lọ lagbegbe naa laarin ọdun 2021, ti wọn si n pa ọpọ wọn tabi gba owo itusilẹ lori wọn.
Ni aarin ọsẹ mẹta akọkọ ninu ọdun 2022, o le ni eeyan bii ọrinlenirinwo ati mẹfa tawọn olubi ẹda yii ti ran sọrun ọsan gangan ni orilẹede Naijiria.
Idaji awọn agbebọn to n paayan kiri yii si lo tẹdo si ẹkun iwọ oorun ariwa ati ipinlẹ Niger.
Ijọba apapọ Naijiria si ti kede awọn agbebọn naa bii agbesunmọmi tabi adunkookomọni.

Ènìyàn 24 dágbére fáyé, 9 farapa níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abuja, Yobe

Oríṣun àwòrán, @FRSC
Kò dín ní ènìyàn mẹ́fà tó ṣe kòńgẹ́ ọlaja wọn n'bi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní agbègbè Tungan Maje, olú ìlú ilẹ̀ wa ni Abuja.
Bákan náà ni ènìyàn mẹ́sàn-án tún farapa níbiìjàmbá ọkọ̀ náà tó wáyé ní nǹkan bí aago mẹ́wàá òwúrọ̀, ọjọ́ Ẹtì.
Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ṣojú rẹ̀, Austin sọfún àwọn akọ̀ròyìn pé ìjàmbá náà wáyé bí ọkọ̀ ńlá kan ṣe pàdánù ìjánu rẹ̀ lásìkò tó wà lórí eré tó sì kọlu ọkọ̀ akérò kan.
Austin ní ojú ẹsẹ̀ ni àwọn márùn ún jẹ́ Ọlọ́run ní pè tí ẹni kan sì tún papòdà nígbà tí wọ́n ń gbe lọ sí ilé ìwòsàn.
- Ìdíje fún sísọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá nílé ẹ̀kọ́ girama dí "Millionaire" lọ́dọọdún gbéra sọ- Yoruba World Centre
- Wo àwòràn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Abeokuta lásìkò ikú Rofiat tí Soliu àti Mustaqim pa
- Jaigbade Alao, àgbà ọ̀jẹ̀ olórin dadakuàdà tó fiṣẹ́ orin sílẹ̀ ní Ilorin lẹ́ni ọgọ́fà ọdún
- Dominic Adigezi àti ọmọ rẹ̀ mẹ́ta kú sínú oko ní Abuja, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Àwọn ẹbí Rahmon Adedoyin àti Timothy Adegoke ju òkò ọ̀rọ̀ lu ara wọn nílé ẹjọ́
- Wọ́n ti ri ẹni mẹ́wàá tó di àwátì nínú oko tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Abamẹ́ta tó kọjá ní Ondo
- Òògùn ìbílẹ̀ nílò ìrànwọ́ owó láti gbèrú síi, àjọ NAFDAC ké gbàjarè
Bákan náà ló ní àwọn mẹ́ta ni orí kó yọ tí wọn kò farapa rárá níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ọ̀gá àgbà àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó FCT, Ogar Ochi ní nínú àwọn ènìyàn méjìdínlógún tó wà nínú àwọn ọ̀hún, àwọn mẹ́sàn án ló farapa tí wọ́n sì ti ń gba ìtọ́jú.
Kini o ṣokunfa ijamba ọkọ mejeeji?
Ochi ní eré àsápajúdé ló ṣokùnfà ìjàmbá náà.
Ní ìpínlẹ̀ Yobe bákan náà, ènìyàn méjìdínlógún ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan ṣe kọlu ọkọ̀ èrò ní òpópónà márosẹ̀ Potiskum.
Agbẹnusọ àjọ ẹ̀ṣọ́ ojú pópó ìpínlẹ̀ Yobe Hussaini Haruna ní eré àsápajúdé àti lílòdì sí òfin ìrìnnà ló ṣokùnfà ìjàmbá náà.
Ní ọdún tó kọjá, kò dín ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ènìyàn tó pàdánú ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀, tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n sì farapa nínú ìjàmbá ọkọ̀ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.




















