Herbal medicine: Àjọ NAFDAC pè fún ìrànwọ́ owó fún ìdàgbàsólè òògùn ìbílẹ̀ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC ti pe fun iranwọ owo fun idasoke oogun ibilẹ.
Ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita.
Ọrọ jẹyọ ninu ọrọ apilẹkọ ki Ọjọgbọn Adeyeye sọ nibi ifilọlẹ ajọ ti yoo maa ṣe iwadii idagbasoke oogun ibilẹ, Africa Centre of Excellence for Drug Research, Herbal Medicine Development and Regulatory Science (ACEDHARS) ni fasiti UNILAG niluu Eko.
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin méjì tó ń fa shisha l'Ogun ti padà sílé ẹ̀kọ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ lọ rọ́kùn ńlé
- Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah Agboluaje, akẹ́kọ̀ọ́ tó kú sí Ukraine ní ọjọ́ kejì tó dé ibẹ̀
- Tí òògùn owó bá wà nínú Ifa ni, n kò bá ti kọ́ ilé ńlá fún ara mi- Babaláwo
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti sàfihàn àwọn òníjàgídíjàgán méjìdínlọ́gọ́rùn ún lónìí ní Ado Ekiti
- Ìdí rèé tí Yahaya Bello fi gbọdọ̀ dá Amotekun sílẹ̀ ní Kogi- Gani Adams
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ọdún 15 mẹ́ta lásìkò tí wọ́n fẹ́ fi èèyàn ṣe òògùn owó
Ọga agba NAFDAC ni gbigbaruku ti iwadii ati idagbasoke oogun ibilẹ lo le jẹ ki eto ilera to peye wa fun gbogbo eeyan.
Ọjọgbọn Adeyeye ni ''eleyii yoo tun jẹ ki ọrọ aje ileeṣẹ ipoogun gberu sii ni Naijiria.
Oogun ibilẹ ṣe pataki gan an si eto ilera tonile talejo ni Naijiria.
Ọrọ ọga agba ajọ NAFDAC sọ ree
''Bo tilẹ jẹ pe, ọpọ eeyan lo n lo oogun ibilẹ fun itọju ara wọn, ko tii wa ninu eto ilera ọpọ orilẹede ni Afirika eyi ti Naijiria jẹ ọkan lara wọn.
Ohun to n kọ awọn akọṣẹmọṣẹ nipa ninu ipoogun lominu ni bi ọpọ eeyan ti n lo oogun ibilẹ lai sẹ iwadii lori awọn oogun ti wọn n lo.
A ni nilo idokowo ninu oogun ibilẹ fun gbogbo awọn to n lo o, ati ijọba fun ra rẹ.
Ọna yii ni a le fi jẹ anfaani awọn ewe ati egbo ti Eleduwa fi jinki wa lorilẹede Naijiria,''ọga agba NAFDAC lo sọ bẹẹ.
- Bí ayẹyẹ ìsìnkú Alao Akala yóò ṣe lọ rèé
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
- Èèyàn méjì dèrò ọ̀run nínú ìkọlù ọlọ́pàá àtàwọn afurasí akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn Kwara Poly
- Musulumi àti Kristẹni lo ṣe àdúrà níbi ètò ìsìnkú Timothy Adegoke lónìí
- Nkan dẹnu kọlẹ̀ ní àwọn agbègbè kan ní America nítorí ìjì líle
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba
- Àwọn ọmọbìnrin oníwọ́kuwọ́ ló mú kí ń yẹ̀bá nídìí iṣẹ́ tíátà
Iṣepataki ajọ ACEDHARS ti yoo maa ṣe iwadii lori oogun ibilẹ
Ọjọgbọn Adeyeye ni ''ifilọlẹ ajọ ACEDHARS sẹ pataki ni Naijiria fun idagbasoke oogun ibilẹ oogun ibilẹ ati lilo rẹ.
Ajọ yii yoo maa ṣe iwadii to muna doko lori oogun ibilẹ ki o te le di lilo fawọn eeyan.
Ọpọ oogun ibilẹ lo n wọ ọja lai ṣe iwadii kankan lori wọn lati mọ bo ya oogun naa lewu tabvi ko lewu lati lo ti wọn fi n loo.
Mo rọ awọn oloogun ibilẹ lati maa lo ajọ ACEDHARS fun idanilẹkọ ati imọ sii lori ṣiṣe oogun ibilẹ.''
Ẹwẹ, ọga agba fasiti UNILAG naa to sọrọ nibi ifilọlẹ ọhun, Oluwatoyin Ogundipe, ṣalaye pe orilẹede Naijiria ni lati imọ awọn oloogun ibilẹ fun eto ilera to peye.
Ọjọgbọn Ogundipe ni o yẹ kawọn eeyan mọ pe oogun ibilẹ dara fun lilo ati pe o yẹ ki Naijiria ṣe amulo ọpọlọ ti Eledua fawọn oniṣegun ibilẹ.
O ni awọn oogun ibilẹ le wo awọn arun kan ṣugbọn iṣoro to wa nibẹ ni pe gbogbo arun ni wọn n fi awọn oogun naa wo eleyii ti Yoruba n pe ni ''gbogbo nṣe.''
Ọjọgbọn Ogundipe ni awọn oloogun ibilẹ ni lati bẹrẹ si ni lo imọ ẹrọ ode oni lati maa fi ṣe oogun ibilẹ.


















