Alao Akala Burial: Wo ìyàtọ̀ tó wà láàrin ètò ìsìnkú Alao Akala sí tí Abiola Ajimobi àti Kolapo Ishola

Aworan ikede isinku Alkao Akala

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government

Lẹyin nkan bi ọsẹ mẹta to jade laye, wọn ti kede eto isinku Gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo , Adebayo Alao Akala, ti ọpọ eeyan n pe ní ‘O Yatọ’

Lọjọ Kejila oṣu Kini ọdun 2022 ni Akala dagbere faye ni ile rẹ to wa ni ilu Ogbomosho.

Ẹni ọdun mọkanlelaadọrin ni Alao Akala ti ọpọ, oloṣelu ati awọn alabasepọ, to fi mọ awọn ọmọ ipinlẹ Oyo si ṣe idaro rẹ.

Ikede isinku rẹ to tẹ wa lọwọ yii fi han pe lọjọ ayajọ awọn ololufẹ taa mọ si Valentine Day ni eto naa yoo bẹrẹ iyẹn ọjọ Kẹrinla oṣu Keji ọdun 2022.

Ọjọ mẹtaa gbako ni wọn yoo fi ṣe eto naa ni ayẹsi ikẹyin agbaọjẹ oloṣelu yi.

Ikede oku Alao Akala

Oríṣun àwòrán, Oyo state government

Ayẹyẹ naa yoo gbera sọ ni ilu Ibadan pẹlu eto imọyi lọjọ Aje ti yoo si pari ni ọjọ Ẹti ni Ogbomosho nibi ti isinku gaan yoo ti waye.

Laarin awọn ọjọ yi, eto titẹ oku ni itẹ ẹyẹ ati eto iṣafihan aṣa to fi mọ alẹ orin iyi naa yoo waye.

Ishola, Ajimobi ati Akala:Iyatọ laarin isinku Gomina mẹta to jẹ ṣaaju Makinde

Kolapo Olawuyi Isola, Isiaka Abiola Ajimobi ati Adebayo Alao Akala wa lara awọn gomina to ti jẹ saaju Seyi Makinde amọ ti wọn ti di oloogbe.

Sugbọn eto isinku ti Akala yii jẹ eleyi to lamilaka labẹ ijọba Gomina Seyi Makinde to ṣe pe awọn Gomina mẹta to ṣe ijọba ṣaaju rẹ ti papoda lẹnu igba to de ori oye.

Ẹni akọkọ ninu wọn ni Kolapo Olawuyi Isola, to ku nigba ti Abiola Ajimobi wa lori aleefa bii gomina nipinlẹ Oyo.

Ọjọ Kẹsan osu Kẹjọ ọdun 2011 ni Ishola ki aye pe o digbose.

Amọ awọn mọlẹbi Isola lo pariwo sita pe ijọba Oyo ko lọwọ ninu eto isinku naa, ti wọn ko si se ẹyẹ fun gẹgẹ bi gomina to ti dari ipinlẹ Oyo ri.

Nigba to ya naa ni Abiola Ajimobi jade laye ni ọjọ Kẹẹdọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2020 nigba ti gomina Seyi Makinde ti wa lori aleefa.

Ọpọ eeyan lo n pariwo pe ijọba ipinlẹ Oyo ko lọwọ si eto isinku Ajimobi, ti wọn ko si se ẹyẹ ikẹyin fun gẹgẹ bi gomina tẹlẹ nipinlẹ Oyo.

Amọ awijare ijọba ni pe ẹbi Ajimobi ko fi aisan ati iku oloogbe to awọn leti gẹgẹ bo se yẹ, ti wn ko si bun awọn gbọ nipa bi isinku rẹ yoo se lọ.

Àkọlé fídíò, 'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'

Ijọba Oyo lọwọ ninu isinku Alao Akala yatọ si ti Ishola ati Ajimobi:

A ri ami idanimọ ijọba ipinlẹ Oyo lori iwe ikede eto isinku Alao Akala ti o si ṣeeṣe ko jẹ pe ijọba naa lo kede isinku yi.

Bi o ba ri bẹ pe ijọba yoo lọwọ si isinku rẹ, o tọ ki a ṣe alaye diẹ lori ohun to le mu ki isinku Gomina tẹlẹ yi yatọ si ẹni to dipo mu lẹyin rẹ.

Ohun ti yoo yatọ laarin isinku Ajimobi ati ti Akala ni pe lasiko isinku Ajimobi awuyewuye waye nigba naa ti ijọba si ni lati fi ọrọ sita lori rẹ.

Ko si sẹyin bi awọn kan ṣe sọ pe ijọba lo fa idiwọ ti isinku rẹ ko fi tete waye.

Musulumi ni Ajimobi ati pe ni ilana ẹsin Islam, ko yẹ ki oku pẹ nilẹ ki wọn to sin. Lẹyin ọjọ mẹrin to ku ni wọn to sin oku Ajimobi.

Koda ọrọ ibi ti wọn yoo sin Ajimobi si nigba naa di fa ki n fa nitori awọn mọlẹbi fẹ sin oku rẹ sori ile ti ẹjọ wa lori rẹ ni Agodi.

Asẹyinwa aṣẹyinbọ, wọn pada sinku Ajimobi si ile rẹ to wa ni Oluyole.

Lọjọ isinku yii, igbakeji Gomina ipinlẹ Oyo ko ribi wọle, ti eleyi naa si mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Ko daju pe iru nkan bayii yoo ṣẹlẹ lasiko isinku Adebayo Alao Akala nitori ireti wa wi pe ijọba yoo ko ipa ribiribi ninu eto yi.

Àkọlé fídíò, Nigeria 2019 Elections: Akala ní APC kò tó bẹ́ẹ̀ láti yọ ọmọ òun nípò alága

Ta ni Adebayo Alao-Akala:

Otunba Christopher Adebayo Alao Akala jẹ ọga kan lẹnu isẹ ọlọpaa ko to fẹyin ti, to si di gbajumọ oloselu nilu Ogbomoso ati ipinlẹ Oyo lapapọ.

O ti jẹ alaga ijọba ibilẹ tẹlẹ ni Ogbomoso, ko to wa jẹ gomina ipinlẹ Oyo laarin ọdun 2007 si 2011.

Bakan naa lo ti jẹ igbakeji gomina fun gomina tẹlẹ, Rashidi Adewolu Ladoja.

Ọjọ Kejila osu Kinni ọdun 2022 ni Alao Akala dagbere fun aye pe o digbose.