Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ YORNCA ní ìjọba ti kùnà lórí ìpèsè ààbò, Yorùbá fẹ́ ààbò nílànà ìbílẹ̀

Oloye Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday_Igboho/Instagram

Wọn ni ta ba dakẹ, tara ẹni maa n ba ni dakẹ ni, ma fi oko mi se ọna, ọjọ kan soso si ni eeyan maa n kọ.

Eyi lo mu ki ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi, Musulumi ati ti ẹsin abalaye to n beere fun idasilẹ Yoruba Nation (YORNCA) se n lọgun fun idande oloye Sunday Adeyemo Igboho ni ahamọ to wa ni ọgba ẹwọn Cotonou lorilẹede Benin.

Ẹgbẹ naa ke gbajare bẹẹ lọjọ Ẹti nibi ipade akọroyin ti wọn se nilu Ibadan, ti wọn si n ke tantan pe bi wọn se ju Igboho si ahamọ lodi sofin, o si yẹ ko gba idande kiakia.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho‘s Birthday: Àwọn olólùfẹ́ Igboho rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Benin láti túu sílẹ̀,

Sunday Igboho ko da ẹsẹ kankan, ẹ tu silẹ ni ahamọ:

Ẹgbẹ YORNCA wa ke sawọn oriade, awọn asaaju oloselu atawọn eekan miran nilẹ Yoruba lati tete wa bi Sunday Igboho yoo se ri idande gba lọgan.

Wọn ni Igboho ko da ẹsẹ kankan labẹ ofin Naijiria tabi ti awujọ agbaye lati jẹ ki wọn fi si ahamọ, o si ti foju han pe ahamọ to wa tako ofin il yii ati ti agbaye.

Ẹgbẹ́ YORNCA wa leri leka pe oun yoo bẹrẹ ipolongo yika gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba fun idande Sunday Igboho ni ahamọ titi ti wọn yoo fi tu silẹ.

Ẹ fun wa lasẹ lati daabo bo ara wa nilana ti ibilẹ - YORNCA

Aarẹ ẹgbẹ YORNCA ni ijọba apapọ labẹ aarẹ Muhammadu Buhari ko le pese eto aabo to yẹ fun ẹmi ati dukia nitori aikaato awọn ileesẹ agbofinro wa gbogbo.

Ẹgbẹ naa wa n beere asẹ lati daabo bo ilẹ Yoruba lati ipasẹ awọn alaabo ibilẹ laisi abuku, ọyaju, ifiyajẹni tabi idunkooko mọni lọdọ awọn osisẹ agbofinro ti ijọba.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Ki lo sẹlẹ sẹyin:

Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho lo n jija gbara fun ilẹ Yoruba, to si n doju kọ awọn afurasi darandaran to n jinigbe, paniyan ati afipabanilopọ.

Amọ nigba to ya, o n beere fun agbekalẹ orilẹede Yoruba, to si ni ọpọ eeyan to n tle lẹyin.

Ni ọjọ kinni osu Keje ọdun 2021 ni awọn osisẹ agbofinro DSS lọ sile rẹ ni oru nilu Ibadan, ti wọn si se ikọlu si nipa biba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ, ti eeyan meji si ku.

Lẹyin eyi ni wọn ri Igboho ni papakọ ofurufu nilu Cotonou ni ọjọ Kẹrindinlọgbọn osu Keje ọdun 2021, to ni oun fẹ lọ gba itọju lorilẹede Germany amọ ti wọn mu si ahamọ.

O yọju sile ẹjọ amọ wọn ko gba idande rẹ, lati igba naa si lo ti wa ni ahamọ ni ọgba ẹwọn naa, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ si ti n pe fun idande rẹ.