Sunday Igboho Àlàyé rèé lórí í ìdí tí Buhari fi ń wá mi kiri-Sunday Igboho

Sunday Igboho Àlàyé rèé lórí í ìdí tí Buhari fi ń wá mi kiri-Sunday Igboho

Kìí ṣe ìròyìn mọ́ pé, àwọn ikọ ọ̀tẹlẹmúye ìjọba Nàìjíríà ṣe ìkọlu sí ilé ajàfẹ́tọ ọmọ Yorubà, Sunday Adeyemo ti gbogbo ènìyàn mọ sí Sunday Igboho.

Nǹkan tó jẹ́ tuntun ni pá Sunday Igboho ti fi àtẹjáde síta pé ìrọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni àjọ DSS sọ nínú ìròyìn pé ilé mi ni wọn ti kó àwọn ìbọn ti wọn pàtẹ nínú ìròyìn.

Nínú àtẹjáde tí agbẹnusọ rẹ̀, Olayomi Koiki fi síta lọsàn ọjọ Ẹti ló ti ṣàlàyé pé, ó ṣe pàtàkì fún òun láti ṣàlàyé bi ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan fún gbogbo ọmọ Nàìjíríà àti àwọn ilẹ̀ òkèrè tó n rí gbogbo nǹkan tó ṣẹlẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igboho ni sáájú kí DSS to ya wọ ilé òun , wọn ko ránṣẹ́ pè òun tàbí fi ìwé pè, bákan náà ni wọn kò sí mú ìwé aṣẹ láti yẹ ilé mi wò dání wá sí ilé mí.

Ó ni lójiji ni wọ́n já wọ inú ilé òun, tí wọn pa ènìyàn, ti wọ́n sì tún jí àwọn dúkía òun lọ.

Sunday Igboho ni gbogbo ọmọ Nàìjíríà ló rí akitiyan àti ìgbìyànjú òun láti dẹ́kun gbogbo ìwà ìjínígbe, ìpànìyàn àti ìfipábánilòpọ̀ ti àwọn Fulani darandaran n ṣe ni ìhà gúúsù Nàìjíríà.

Gbogbo ìwà àìbikíta ààrẹ Muhammadu Buhari àti ìjọba rẹ, ló mú kí òun dide láti gbèjà ìràn òun.

Oloye Adeyemo ni kò sí àsìkò kankan tí ìgbésẹ̀ òun tàbí ìwọ́de tí òun ṣe mú ìtàjẹ̀sílẹ̀ ẹnikẹni dáni tàbi pa ẹnikànkan lára.

Àkọlé fídíò, Olowo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tún yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn

Ìdí tí Buhari ṣe ń wá mi

"Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbìyàjú ìjọba láti so mi pọ mọ́ ìwà ọ̀daràn kankan, ti wọn kò rí, ni wọ́n ṣe fẹ́ fi tipa pa mí lẹ́nu mọ́"

Sunday Igboho ni ìjọba rí òun gẹ́gẹ́ bi ìdènà sí ìpinu ààrẹ láti fún àwọn Fulani láàyè láti gba ilẹ̀ onílẹ̀ àti láti tẹ̀síwájú níńu iṣẹ́ ìpànìyàn, ni wọ́n ṣe ń wá ẹmi òun.

Oloye ni kí ni ìdí tí àwọn DSS yóò ṣe wá sí ilé òun láàrín orún, tí wọ́n sí ba gbogbo kamẹra to wá nínú ilé òun jẹ́, bákan náà ni wọ́n ba gbogbo dúkíà òun jẹ́.

" Tí kìí bá ṣe pé wọ́n ni ìpinnu ti wọ́n fẹ́ ṣe , kín ní ìdí tí wọ́n fi kọkọ bá àwọn kámẹ́rà ilé òun jẹ́ kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ibi wọn?

" Kín ni ìdí tí àwọn DSS kò ṣe lo kámẹ́rà tí wọ́n ń so mọ́ ara kí wọn to ṣíṣẹ wọn?

" Wọ́n pa àwọn ènìyàn, wọ́n sì tún gbé òkú wọn lọ.