Oduduwa Nation: Ẹgbẹ ọmọ Yorùbá YAF ṣèwọ́de tako ìyapa Nàíjíríà

Oríṣun àwòrán, The Nation
Se ni ohun gbogbo pakasọ nilu Ado-Ekiti l‘Ọjọbọ nigba ti ẹgbẹ ọmọ bibi ilẹ Yoruba kan, Yoruba Appraisal Forum, YAF, se iwọde tako ipinya Naijiria.
Deedee aago mẹsan owurọ ni iwọde na ti bẹrẹ, ti wọn si korajọ pọ si gbagede Adekunle Fajuyi, nibi ti wọn ti gbera lati bẹrẹ iwọde yika ilu Ado Ekiti.
Lara awọn eeyan to se iwọde naa la ti ri awọn ọlọkada, ẹgbẹ ọdọ lorisirisi ati ẹgbẹ awọn ọlọkọ ero ti wọn gbe oniruuru akọle lọwọ.
- Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, "Doughnut", ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin
- Mo dákú rangbọndan lẹ̀yìn tí amúgbálẹ́gbẹ gómìnà Akeredolu fún mi ní ìgbájú olóyì - Aláboyún
- Ìyàtọ tàbí àfiwé wo ló wà láàrin Sunday Igboho, Nnamdi Kanu àti Asari Dokubo?
- Ẹgbẹ́ tó ń fẹ́ Oduduwa Republic kọ̀wé ẹ̀hónú sí UN, EU, AU àti ìjọba Gẹ̀ẹ́sì
- Àwọn tí àkóso ìjọba bọ́ lọ́wọ́ wọn ló ń ti Igboho lẹ́yìn lórí ìdásílẹ̀ Oodua Nation - YWG
- Àìgbọ́ra ẹni yé ẹ̀yà Yoruba ló ń ṣe ìdíwọ́ fún òmìnira wa - Àkójọpọ̀ ẹgbẹ́ Yoruba l'àgbáyé
- Ohun tí ìyàwó Adeboye ṣe ní ìgbà akọkọ tó fojú hàn lẹ́yìn ikú ọmọ wọn Dare
Ohun to wa ninqu akọle naa ni ‘A gbagbọ ninu orilẹede Naijiria to wa ni ọkan soso, Orilẹede Naijiria se koko, ẹ jẹ ka jọ wa papọ ka si nifẹ ara wa.‘
Bakan naa ni awọn akọle miran sọ pe ‘ko si ba se le duro bii orilẹede lai si isọkan, ikan omi ni wa ni ẹyọ kọkan amọ okun nla ni wa ta ba wa papọ.‘

Oríṣun àwòrán, The Nation
Alakoso fun ẹgbẹ YAF, Adesina Animashaun, lasiko to n ba awọn oluwọde naa sọrọ tako Sunday Igboho ati bo se n pe fun iyapa Naijiria.
O wa sapejuwe iwa naa gẹgẹ bii eyi to fẹ gba akoso ijọba orilẹede yii, ti ko si tun safihan ẹni to ni ifẹ ilẹ baba rẹ.
Bakan naa ni Animashaun tun koro oju sawọn igbesẹ Nnamdi Kanu ati ẹgbẹ rẹ, IPOB, lati pin orilẹede yii niya, ati iwa ipaniyan ati idaluru ti wọn n se nitori ipe fun iyapa.

Oríṣun àwòrán, The Nation
Ẹgbẹ YAF wa ke si awọn oriade nilẹ Yoruba lati mase gba Nnamdi Kanu laaye pe ko tọwọ bọ ọpọlọ wọn tabi bọ si aarin wọn nitori ẹri to daju ti fihan pe rogbodiyan lo fẹ da silẹ.
"Ẹ ma jẹ ka sọ Naijiria da bi orilẹede Somalia se da nitori ogun abẹle, n ko tiẹ fẹ ni iriri ogun jija titi aye mi nitori a mọ nnkan ta padanu lasiko iwọde EndSARS to kọja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹbí Fela Anikulapo yarí fún APC àti Tinubu torí èròjà ìpolongo ìbò
- Wo ọjọ́ gangan tí Pásítọ̀ Dare Adeboye ti jáde láyé, ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Pásítọ̀ RCCG kéde
- Èèyàn kan kú nínú ìjà tó n wáyé ní Mile 12 láti bíi ọ̀sẹ̀ kan
- NECO gbé èsì ìdánwò ọdún 2020 jáde!
- Ganiyu fẹ́ na pápá bora lẹ́yìn tó gún ìya ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ pa lọ́sàán àwẹ, ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- Àwọn agbébọn tún ti jí ènìyàn tó lé ní 100 gbé lọ ní Nàìjíríà
Awa bii ọmọ ẹgbẹ Yoruba Appraisal Forum, a n fi ikilọ sita pe a ko ni gba ki ẹlẹgbẹjgbẹ tabi ẹnikẹni sọ ẹkun iwọ oorun Naijiria di ibudo ogun."
Ẹgbẹ YAF wa n ke si ileesẹ ọlọpaa, awọn ọtẹlẹmuyẹ DSS, awọn ologun atawọn ileesẹ agbofinro gbogbo lati ji giri si ojuse wọn, ki wọn si da awọn ajijagbara to n wa iyapa Naijiria lẹkun.



















