Mile 12: Èèyàn kan kú nínú ìjà tó n wáyé ní Mile 12 láti bíi ọ̀sẹ̀ kan

Oríṣun àwòrán, Twitter/@Mr_JAGs
Ọrọ di bo o lọ, yago fun mi ni agbegbe Mile 12 nipinlẹ Eko nitori ija igboro to n waye laarin awọn janduku.
Iroyin to jade si ori ayelujara ni ọsan Ọjọbọ ni pe niṣe ni awọn janduku n kọlu awọn eeyan, ti wọn si n ba dukia jẹ.
Ija yii ni ẹlẹẹkeji ti yoo waye ni adugbo naa laarin ọjọ mẹta.
A gbọ pe ni adugbo Gengere ni agbegbe Mile 12 ni ija naa ti n waye. Eyi to mu ki kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu paṣẹ pe ki awọn ọlọpaa mu eeyan mẹtala to jẹ olori awọn ẹgbẹ to n ja.
Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹnusọ gomina Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko, Gboyega Akosile fi sita, ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin ni wahala ti bẹrẹ.
O ni iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fihan pe awọn janduku bẹrẹ wahala lẹyin ti wọn fi ẹsun kan olori igbimọ eto aabo ni adugbo Gengere, Alhaji Alidu Mohammed, pe o fi abuku kan Anọbi Mohammed, to si tun sọ ọrọ odi si.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@mr_jags
Ibinu si ọrọ to sọ ni awọn janduku fi ya sita, ti wọn si dana sun ọkọ ayọkẹlẹ rẹ meji, wọn tun kọlu ọkan lara awọn ile rẹ.
Bakan naa ni wọn dana sun ile ile kekere kan to jẹ ti ẹlomii, Alhaji Mamuda.
Yatọ si eyi, iṣẹlẹ naa mu ẹmi eeyan kan, Papa Mohammed, lẹyin ti wọn fi nkan gun ni ọjọ naa. Ọjọ kinni, oṣu Karun-un si lo dagbere faye nileewosan.
Nibayii, a ko ti i le sọ boya ija to bẹrẹ lati ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin lo tun fa ti ọsan oni, tabi nkan mii.
Awọn oṣiṣẹ alaabo si ti de si ibẹ lati mu ki alaafia jọba.












