Ogun murder: Ganiyu gún ìya ìyàwó rẹ̀ lọ́bẹ pa lọ́sàán àwẹ, ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police
Ọwọ́ ọlọ́pàá tipinlẹ Ogun ti tẹ Ganiyu tó fẹ na pápá bora lẹyìn tó gùn iya ìyàwó rẹ lọbẹ pa lọsan àwẹ.
Ọwọ palaba arakunrin naa to gun iya iyawo rẹ lọbẹ pa ninu àwẹ segi nipinlẹ Ogun.
Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa Ogun DSP Abímbólá Oyeyemi fi sita, o ni nise ni Opeyemi Adeola Ganiyu gbiyanju lati sa lọ lẹyìn tó gun iya iyawo rẹ arabinrin Abosede Oyewole lọbẹ pa.
O ni lọjọ Aje ni awọn ri afurasi ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa mu.
Gẹgẹ bí alaye rẹ, eeyan kan Odunayo Mathew lo mu ẹjọ wa sí agọ ọlọpaa to wa ni Atan Ota pe Ganiyu pa iya iyawo rẹ to ni ko jáwọ lati maa lu iyawo rẹ tii ṣe ọmọ rẹ.
Alukoro ọlọpaa ni ẹni tó fẹjọ sun ni gbogbo igba ni afurasi naa maa n lu iyawo bi ọrọ ba fi le pa wọn pọ pẹrẹn, Oyeyemi ni ".
Lọjọ tá n wí yìí, o lu iyawo rẹ to sí da ọgbẹ síi lara. Eyi lo mu ki àna rẹ wà kìlọ fún un pe ko ye lu ọmọ oun mọ"."Riri ti Ganiyu yoo ri ana rẹ, nise lo lu u bi ẹni lu bara kí o to gun un lọbẹ".
Ẹ̀sùn gbígbìyànjú láti wọ́lé sí ojú ara ọmọdé pẹ̀lú ìpá àtàwọn ẹ̀sùn mìí tí Baba Ijesha yóò jẹ́ rèéO tẹsiwaju pe ara adugbo sáré gbe e lọ sile iwosan ṣugbọn o pada gbẹmi mi.
Gbigbọ ti afurasi naa gbọ pe ana re ti dakẹ, nise lo na papa bora lọ sí Ikorodu ṣugbọn awọn ọlọpaa ọtẹlumuyẹ tọ pinpin rẹ ti ọwọ sí tẹ ẹ laipẹ.
Iwadii t'awọn ọlọpaa ṣe fi hàn pé ọmọ ẹgbẹ okunkun ni afurasi naa ati pe o wa lara awọn to dana sun agọ ọlọpaa Atan Ota lasiko ìwọ́de Endsars nibi ti wọn ti pa ọlọpaa kan.















