Insecurity in Nigeria: A ó yanjúu gbogbo àwọn tó ń kọlu àgọ́ àwọn ọlọ́pàá láìpẹ́ - Lai Mohammed

Oríṣun àwòrán, @thebridgenewsng
Ijọba apapọ ti sọ pe awọn ti ṣetan laati bẹrẹ si n gbogun ti gbogbo awọn to n ṣekọlu si agọ awọn ọlọpaa ni Naijiria.
Minisita fun eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed lo fi ọrọ naa lede nibi ipade awọn akọroyin kan to waye niluu Eko.
O juwe oniruru ikọlu ti awọn agbebọn kan n ṣe si agọ awọn ọlọpaa, paapaa lagbegbe ila orun gẹgẹ bii ikọlu si Naijiria gẹgẹ bii orilẹ-ede.
O ni "gbogbo ikọlu ti ẹnikẹni ba n ṣe si awọn agbofinro wa jẹ ikọlu si orilẹ-ede Naijiria, o si jẹ igbogunti orilẹ-ede yii."
Lai sọ pe irọ pata ni ọrọ ti awọn kan n sọ kiri pe ijọba Naijria ko lagbara lati yanju eto abo to mẹhẹ.
O ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe lootọ ni Naijiria n dojukọ oniruru isoro, paapaa nipa ti eto abo, ṣugbọn awọn araalu yoo ri awọn igbesẹ ti ijọba n gbe lati koju awọn iṣoro naa laipẹ.
Lai Mohammed pari ọrọ rẹ pe awọn adari ijọba ti fẹnuko lori awọn ohun to yẹ ki wọn ṣe lati koju gbogbo iwa ọdaran to n fi ojojumọ peleke sii ni Naijiria.
Lara awọn ohun ti wọn fẹnuko le lori naa ni pe Naijiria nilo atunto ni kankan, dipo ipinya ti awọn kan n pariwo.
Bakan naa ni wọn tun fẹnuko pe ki awọn ijọba ipinlẹ ṣe atilẹyin fun agbekalẹ ọlọpaa agbegbe ko le rọrun lati koju iṣoro tie to abo n dojukọ.

Oríṣun àwòrán, Lai Mohammed
Ìjínigbé àti ìdigunjalè kò sí ní ìkáwọ́ ìjọba àpapọ̀ - Lai Mohammed
Mínísíta ọ̀rọ̀ tó n lọ àti àṣà, Lai Muhammed ti ni ọ̀rọ̀ ijinigbe àti ìdigunjalè kò si ni ìkáwọ́ ìjọba àpapọ̀.
Lai Muhammed ni awọn iwa ọdaran bii idanilọna, idigunjale ati ijinigbe kii ṣe ẹṣẹ to wa ni ikawọ ijọba apapọ lati mojuto, o ni "ẹsẹ to yẹ ki ijọba ipinlẹ mojuto ni".
Minisita sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi fesi fun ẹgbẹ alatako People's Democratic Party (PDP) to fẹsun kan pe ijọba All Progressive Congress ko se nkankan lati mu idigunjale ati ijinigbe wa si opin ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Lai Mohammed
Gẹgẹ bi Lai Mohammed se sọ, iwa igbesumọmi nikan ni o jẹ amojuto ijọba apapọ, ijọba apapọ si ti ṣe gudugudu meje lati rii daju pe wọn gbe awọn Boko Haram ti ọwọ tẹ lọ si ile ẹjọ ni Kaiji.
Saaju ni ijọba apapọ ti kilọ fun awọn olori ẹsin yala musulumi tabi kristẹni ati awọn adari awujọ kan to n pinu lati da orileede Naijiria sinu laasigbo ki wọn lọ so ewe agbejẹ mọwọ.
O ni awọn si n gbe awọn ọdaran lọ si ile ẹjọ sugbọn nkan ẹyọkan to ku bayii ni ki awọn agbẹjọro ati awọn adajọ fọwọsowọpọ nile ẹjọ lati se idajọ awọn ti awọn mu.
- Ẹ̀wọ̀n gbére tàbí ọlọ́dún mẹ́ta, méje, àtàwọn ìjìyà tó ṣééṣe kí Bàbá Ijeṣa jẹ rèé - Ìjọba ìpínlẹ̀ eko
- Mo bẹ Baba Ijesha wò l‘àhámọ́, ẹ́ gbọ́ wirínwirìn ọ̀rọ̀ nílé ẹjọ́ - Yomi Fabiyi
- Agbébọn tú alápatà mẹ́ta tí wọ́n jí gbé sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó
- Ayé ń pè wá ní 'Yeyebrity' torí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha, nǹkan bà wá lágbo tíátà Yoruba"
Ninu atẹjade ọhun bakan naa, minisita sọ pe o ba oun lojiji pe ẹgbẹ oselu to ti dari ilu fun ọdun mẹeindinlogun ko mọ pe ijinigbe ati idigunjale kii se ẹsẹ si ijọba apapọ bi ko se ti ijọba ibilẹ."
O ni awọn ẹgbẹ alatako kan n wa ẹni ti wọn yoo da ẹbi ọrọ ru ni, ki wọn maa dẹbi ru awọn gomina ipinlẹ to fi mọ awọn eyi ti ẹgbẹ wọn n dari lati mu awọn ọdaran to ba ji eniyan gbe lo si ile ẹjọ.















