Insecurity in Nigeria: Àwọn gómìnà ẹkùn Gúúsù fòfin de dída màálù ní gbangba

Awọn gomina apa gusu Naijiria

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun MFR

Awọn gomina ilẹ Yoruba, ilẹ Ibo ati awọn ẹkun Niger Delta ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati b'awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori eto abo to ti polukurumusu ni Naijiria bayii.

Awọn mẹtadinlogun lapa gusu orilẹede Naijiria kede ọrọ naa lẹyin ipade ti wọn ṣe lọjọ Iṣẹgun ninu Asaba, nipinlẹ Delta.

Koko mejila lawọn gomina naa fẹnu ko si eleyii ti alaga wọn, Gomina Rotimi Akeredolu ipinlẹ Ondo ka jade.

Awọn gomina naa sọ pe awọn eeyan apa gusu Naijiria ṣi n wa iṣọkan orilẹede yii niwọn igba ti ododo, aiṣegbe lẹyin ẹnikan ati alaafia ba ti wa laarin awọn ọmọ Naijiria.

Awọn ẹkun gusu ko ṣai fi aidunnu wọn han lori eto abo to mẹhẹ bayii.

''A ṣe akiyesi pe awọn darandarn, awọn ọdaran atawọn janduku to n wa si ẹkun gusu ni Naijiria ti ṣakoba fun eto abo awọn eeyan wa.

Eku ko ke bi eku mọ, bẹẹ ni ẹyẹ ko ke bi ẹyẹ mọ, awọn eeyan ko le gbe ni alaafia mọ.

Gbọgbo nkan yii lo si ti ṣokunfa ọwọngogo ounjẹ bayii.

Fun idi eyi, a ti fofin de dida maalu kiri ni gbangba kaakiri apa gusu Naijiria,'' Akeredolu lo sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita.

Akeredolu ni ''a tun fẹnuko pe ijọba ni lati gbe igbesẹ ni kiakia lati lati ṣe atunto Naijiria lori ọrọ ọlọpaa ipinlẹ atawọn atunto ileeṣẹ ijọba kan.

A tun fẹ ijọba apapọ ṣe agbekalẹ ifọrọwerọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria lati le sọ ohun to n kọ wọn lominu gan an.

Ijọba tun gbọdọ tun ero rẹ pa lori ofin konle-o-gbele to da pada tori ajakalẹ arun covid-19 nitori akoba to le ṣe fun ọrọ aje.