Dare Adeboye burial: Pásítọ̀ Adeboye bẹ̀bẹ̀ fún àdúrà fún ìdílé rẹ̀ àti ẹbí olóògbé Dare Adeboye

Oloogbe Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, @pdee

Oludari ijọ Redeem(RCCG), Pasitọ Enoch Adejare Adeboye ti bẹbẹ adura fun idile rẹ nigba to n sọrọ nibi eto isinku ọmọkunrin rẹ, Pasitọ Dare Adeboye to d'oloogbe.

Baba Adeboye sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan nibi eto isinku naa to wa ni ọgba ''Redeem camp'' to wa ni opopona ilu Eko si Ibadan.

Alufaa Adeboye sọ pe ikku ko mọ ọmọde, bẹẹ ni ko mọ agba nitori bi ọmọde ṣe n ku naa ni awọn agbalagba n ku.

''Iku ko niiṣe pẹlu ọjọ ori eeyan, ṣugbọn ẹ dẹkun lati maa gbadura fun mi.

Ẹ maa gbadura fun iyawo mi, ẹ maa ranti aya oloogbe atawọn ọmọ rẹ naa ninu adura yin.

Dare

Oríṣun àwòrán, @Dare Adeboye

Eleyii to ju gbogbo rẹ lọ ni pe e maa gbadura fun ara yin ki ẹyin naa le pari irinajo yin laye yii daradara,'' Pasitọ Adeboye lo sọ bẹẹ.

Baba Adeboye ṣalaye pe ko si ọna ti aye yii fi le da bi ọrun laelae.

''Mo mọ ohun ti mo n sọ nipa rẹ tori pe mo rii fun ra mi.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Ti ẹ ba ri mi ti mo n ṣiṣẹ takuntakun fun Oluwa, nitori mo mọ pe ere mi n duro de mi lọrun ni.

Mo rọ yin wi pe ki ẹ tẹsiwaju ninu ereeje igbagbọ.

Ohun ti mo mọ nipe iyanu nla ti iru rẹ ti aye ko tii ri ri yoo ṣẹlẹ ninu aye yin laipẹ,'' Pasitọ Adeboye lo sọ bẹẹ.

Baba Adeboye tun sọ pe oun yoo tubọ tẹra mọ ọrọ awọn ọdọ ninu ijọ RCCG ju ti atẹyinwa lọ.

Awọn agbokujo

Oríṣun àwòrán, BBC/screenshot

Àwọn àwòrán láti ibi ètò ìsìnkú olóògbé Dare Adeboye ni Redemption Camp

Eto isinku oloogbe Dare Adeboye, to jẹ ọmọ kẹta to tun duro fun ọmọkunrin keji adari ijọ Redeemed Christian Church of God, RCCG, Pasito Enoch Adejare Adeboye ti bẹrẹ.

Bayii ni awọn eeyan ṣe pejọ sibi ti ayẹyẹ isinku naa yoo ti waye
Àkọlé àwòrán, Bayii ni awọn eeyan ṣe pejọ sibi ti ayẹyẹ isinku naa yoo ti waye

Gbogbo ẹbi, ara ọrẹ ati ojulumọ ni ireti wa pe wọn yoo peju pesẹ sibi isin naa loni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu karun un, ọdun 2021.

Pẹlu Hashtag #PDee ati #NotTodaySatan, I'm not leaving God, ni wọn n lo lati fi aworan wọn sita pẹlu bi wọn fa irun wọn lori ayelujara.

Lana ni wọn ti kọkọ ṣe isin idagbere ni ile ijosin House of Favour ni Redemption Camp ni Mowe ni ipinlẹ Ogun.

Eyi si waye leyin isin iyẹ oloogbe si to kọkọ waye ni ọjọ Aiku nil ipinlẹ Akwa Ibom ti oloogbe ti ṣiṣẹ iranṣẹ gbẹyin ki ọlọjọ to de.

Awọn ọmọ ogun igbala naa ko gbẹhin nibi eto naa. Tilu-tifọn ni wọn fi gbe oku Dare Adeboye lọ si ibi ti isinku yoo ti waye
Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ogun igbala naa ko gbẹhin nibi eto naa. Tilu-tifọn ni wọn fi gbe oku Dare Adeboye lọ si ibi ti isinku yoo ti waye

Ọjọ Isẹgun ọjọ Kọkanla osu Karun ọdun 2021:

Isin idagbere yoo waye ni aago mẹwa owurọ ni ibudo awọn ọdọ, Youth Centre, to wa ni Redemption Camp ni Mowe, nipinlẹ Ogun.

Lẹyin naa ni wọn yoo sin oloogbe Dare Adeboye si ibẹ.

Dare Adeboye

Oríṣun àwòrán, @PDEE

Lẹyin isin fun oloogbe ni RCCG House of Favour ni Redemption Camp ni Mowe ni ipinlẹ Ogun laarọ oni ni wọn yoo gbe ara oloogbe Oluwadamilare Temitayo Adeboye lọ si itẹ̀ oku ni Redemption Camp.

Nibẹ ni wọn yoo ti fi eruku fun eruku ati iyẹpẹ fun iyẹpẹ ti wọn yoo si fi ara naa silẹ lọ.

Iyawo kan, Temiloluwa ati ọmọ mẹta, Oluwatise, IreOluwa, ati Araoluwa lo gbẹyin oloogbe naa yatọ si Obi, ẹgbọn, aburo, ara ati ọrẹ.

Àkọlé fídíò, Trade by Barter, Rivers: Mọ̀ síi nípa ọjà ní Esuk Mba, níbití o ti lè fi iṣu gba edé, epo