Ibarapa security: Agbébọn tú alápatà mẹ́ta tí wọ́n jí gbé sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó

Aworan awọn agbebọn kan

Oríṣun àwòrán, other

Awọn agbebọn tun ti ṣọṣẹ lagbegbe Ibarapa ni ipinlẹ Ọyọ nibi ti wọn ti ji awọn eeyan gbe.

Iroyin sọ pe agbegbe Idi pẹ nitosi Igangan ni wọn ti ṣọṣẹ lọtẹ yii.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, akọwe awọn agbẹ ni Ibarapa, Ọgbẹni Taiwo Adeagbo ṣalaye pe alapata ni awọn mẹta ti wọn ji gbe naa ati pe wọn tan wọn pe ki wọn wa ra malu ni owo pọọku ni ki wọn to kugiri si wọn jiwọn gbe loju ibọn.

Akọwe awọn agbẹ ni Ibarapa naa kede orukọ awọn ti wọn ji gbe naa gẹgẹ bii Ọlagunju Gafari ti inagijẹ rẹ n jẹ Soka, Jimoh Kabiru ti inagijẹ rẹ n jẹ Ọmọ Iya ati Fasasi Kareem lati idile ọba Asawo ni ilu Ayetẹ.

O fi kun pe ni ọjọ Aje, ọjọ kẹta oṣu kẹrin ọdun 2021 ni wọn tu wọn silẹ lẹyin ti wọn gba owo ẹgbẹlẹbẹ lọwọ wọn.

Ni ọjọ Aiku ọjọ kẹta oṣu kẹrin ọdun 2021 ni wọn ji awọn eeyan naa gbe.