NIN-SIM link deadline: Mínísítà ìbaraẹnisọ̀rọ̀ ti sún ìsopọ̀ NIN mọ SIM sí June 30

Oríṣun àwòrán, Others
Eto siso nọmba idanimọ NIN papọ mọ nọnmba ipe to n lọ lọwọ ni ni wọn ti sun siwaju titi di ọgbọn ọjọ, osu kẹfa ọdun 2021 gẹgẹ bi mínísíta ọrọ ibanisọrọ ati idokoowo ori ayelujara Isa Pantami se sọ.
Eyi jẹyọ ninu atẹjade ti adari eto awujọ ile ișẹ NCC Ikechukwu Adeinde ati olori ibanisọrọ nile isẹ NIMC Kayode Adegoke jọ fi ọwọ si.
Pantami ti ọpọ ọmọ Naijiria ti n bu ẹnu atẹ lu lati ọjọ diẹ sẹyin nitori pe o n gbe ti awọn alakatakiti Taliban ati gbogbo awọn ọrọ to ti sọ, salaye o le ni eniyan mẹrinlelaadọta lo ti gba nọmba idanimọ NIN ni Naijiria.
- Ǹkan márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa NIN àti BVN
- Àfàìmọ̀ ká máa dá ìforúkọsílẹ NIN dúró tórí ewu coronavirus- Mamora
- Wo àdánù tó wà nínú gbígba ayédèrú áápù fún ìforúkọsílẹ̀ NIN lórí ayélujára
- Ìjọba Nàìjíríà ti sún ọjọ́ ìforúkọsílẹ káàdi ìbánisọ̀rọ̀ síwájú síi
- Gbogbo ẹ̀yin tí 'SIM Card' yín tí sọ̀nú, ẹ wo ọ̀nà tí ẹ lè fi gbà á padà!
Akọle atẹjade naa "ni iforukọsikẹ NIN eniyan milionu 54 lo tiforukọsilẹbi ìjọba apapọ se buwọlu ogbọn ojọ osu kẹfa ọdun 2021 gẹgẹ bi gbendeke fun iforukọsilẹ."
O ni awọn gbe igbesẹ naa nibi ipade ori ayelujara ri awọn se ti minista naa si Peju bakan naa ni alaga ajọ NIMC AdeoluAkande wa nikalẹ to fi mọ awọn eekan ajọ to ku.
"Isunsiwaju yii ko ṣẹyin bi awọn ti ọrọkan ṣe n bẹbẹ fun titi di ọgbọn ọjọ, ati lati mu nkan rọrun fun awọn ara ilu ati awọn alejo
Ọjọ karundinlogun oṣù Kejila ọdun 2020 ni ijọba pe lẹyin ogbọn ọjọ oṣù kejila ọhun gbogbo eni ti ko ba so nọmba ipe rẹ mọ ti NIN ko ni ṣiṣẹ mọ ati pe awọn ile ișẹ to n ri si ipe yoo ti pa loju opo wọn
Nigba ti o se wọn tun sun ogbọn ojoosu kejila yii siwaju nigba ti gbkgbo awọn eniyan n naka alebu si, eyi lo mu ki wọn fi ọsẹ mẹta sun siwaju ti o si di ọjọ kọkandinlogun osu kini osun 2021.
Fun awọn ti ko ni NIN rara ofun wọn di ọjọ keji osu keji ọdun 2021 lati lọ gba NIN ki wọn si so mọ nomba ipe wọn.
Ọpọ ile isẹ lo ti pe fun ki wọn sun ọrọ NIN siwaju ki awọn òṣìṣẹ́ won le se nkan to yẹ kí wọ́n ṣe.
- Haram ni kí èèyàn máa san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé - Sheikh Ibrahim Maqari
- Ìdí rèé tí ìgbéyàwó ọdún 27 tú ká láàárín Bill àti Melinda Gates
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ lónìí láàrin ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna àtàwọn tó jí akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Greenfield gbé?
- Microsoft gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè iṣẹ́ 27,000 fún àwọn ọmọ Naijiria















