NIN Registration App: Má lu jìbìtì ayélujára, wo bo ṣe le dá ojúlówó àti ẹbu áàpù NIMC mọ̀

Oríṣun àwòrán, NIMC
Ajọ to n mojuto iroyin nipa kaadi idanimọ awọn ọmọ Naijiria ti kede laipẹ yii pe, ki awọn ọmọ Naijiria tara sasa lọ gba nọ́mba idanimọ NIN wọn ki wọn ba maa padanu opo ibaraẹnisọrọ wọn.
Amọ pẹlu ikede yi naa ni wọn fi ọna tawọn eeyan yoo fi le ri nọmba yii, paapa fawọn to ba fẹ so nọmba siimu ibaraẹnisọrọ wọn miran mọ eyi ti wọn fi ṣe iforukọsile NIN.
Labẹ anfaani yii, wọn ni ki wọn gba appu NIMC kan ti yoo jẹ ki isopọ awọn siimu mii mọ akọkọ yii rọrun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, ohun tó pa ẹ̀gbọ́n àti àbúrò Orisabunmi rèé - Mọ̀lẹ́bí gbarata
- Àmúlò ẹ̀rọ POS fun òwò ṣíṣe, ṣé ó tọ̀nà nínú Islam àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
- Ìjọba ń ṣapá rẹ̀ lórí ìdènà Covid-19 àmọ́ àwọn awakọ̀ Eko ya aláìgbọràn - Ìjọba
- N kò jà fún ìṣọ̀kan Yorùbá láti wá ipò tàbí orúkọ - Sunday Igboho
- "Ẹ̀yin tẹ̀ ń parọ́ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà mọ́ Amotekun Oyo, Seyi Makinde lẹ̀ ń dojú ìjà kọ"
- Afurasí agbébọn 47 bọ́ sọ́wọ̀ ikọ̀ ‘Operation Burst’ l‘Oyo
- Iye àwọn tó ń ní Covid-19 ti ń pọ̀ ju ilé ìwòsàn lọ, tó bá yá ọwọ́ wa ò ní ka mọ́ - NCDC
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
Ohun to fọwọ kan ni lẹmi ni pe, awọn obilẹjẹ eeyan kan ti n fi ayederu aappu sita lati maa fi se ijamba fawọn ti ko ba mọ.
Bawo wa lo se le da appu to jẹ ojulowo mọ?
A beere lọwọ onimọ kan nipa igbekalẹ appu orisirisi ti a mọ si app developer.
Arakunrin Olamiji Gabriel ba BBC Yoruba sọ pe, nkan ti ijọba Naijiria se ni pe wọn ti so nọmba siimu onikaluku mọ nọmba NIN rẹ.
O ni awọn to lọ forukọsilẹ lati gba nọmba NIN laipẹ yii yatọ si awọn to ti ni tẹlẹ, wọn beere nọmba BVN wọn lọwọ wọn ki wọn ba le so awọn nọmba yi papọ.
O ni nitori eyi, bi eeyan ba fẹ download appu NIMC yii, ko ri pe eyi to wa lati ọdọ ijọba lo download bi bẹẹ kọ, awọn alaburu le lo aapu ayederu yii lati fi wọ owo inu akanti wọn, ti wọn yoo si se ipalara fun wọn.
''Gbogbo awọn ti wọn ti lọ download ayederu appu, nkan ti wọn yoo bi wọn ni pe, ki wọn san owo ki wọn baa le ri nọmba NIN wọn. Ijọba ko si ni ki wọn maa gba owo kankan lati fi gba nọmba yii''
Olamiji tẹsiwaju pe, nitori pupọ awọn eeyan wa ni Naijiria ni kii fẹ se suuru, ẹlomii yoo san owo yii lati le fi tete ri nọmba NIN gba.
Ki ni ipalara to le ba ọ, ti o ba gba gbarọguduaapu?
O ni aburu to wa nibẹ kii se ti owo perete ti eeyan ba san, bi kii se pe awọn obilẹjẹ yi le lo ọna eru lati wọ inu akanti eeyan nigba ti wọn ba ti mọ nọmba BVN ati NIN.
O ni wọn yoo dahun awọn ibeere kọọkan ti ile ifowopamọ ba bi wọn, ti yoo le jẹ ki wọn gba owo jade ninu akanti eeyan.
''Ti wọn ba ti le ri ọjọ ibi eeyan, Date of birth tabi BVN eeyan, wọn le fi gba owo ninu akanti eeyan''
''Se ẹ ri token ti wọn maa fi n sọwọ si ori nọmba foonu ẹni to ba ni akanti, dipo ko lọ si ori foonu yin, ọdọ awọn to se appu ayederu yii ni yoo lọ si.
Bi wọn ba ti ni BVN yin, token ati ọjọ ibi yin, ọrọ ti bu se ni yẹn''
Nipa nkan to yẹ ki awọn eeyan wo, ki wọn to le gba ojulowo aapu NIMC, o ni ko si bi eeyan ti se le da wọn mọ yatọ afi ki ijọba apapọ sọ fun awọn ọmọ Naijiria, eyi to jẹ ojulowo tabi ayederu.
''Ayafi ki ijọba jade sita lati fi oju opo ti wọn gangan han araalu, ki wọn si fi ami idanimọ to yatọ fun araalu si oju opo tawọn eeyan mọ wọn si lọna abayọ.
Bi bẹẹ kọ awọn obilẹjẹ yii yoo tun se ẹda aapu ti ijọba, ti wọn yoo si maa fi se ijamba fara ilu''.



















