Online Banking: Wo awuyewuye tó súyọ lórí ìhà tí ẹ̀sìn Islam kọ sí lílo POS fun òwò ṣíṣe?

POS

Oríṣun àwòrán, Google

Lilo ẹrọ POS fun owo ṣiṣe ni Naijiria, yala nipa fifi owo ranṣẹ tabi gbigba owo, ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ laarin awọn Musulumi kan ni Naijiria.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe Haramu ni ki ẹni to ni ẹrọ POS naa maa gba ele owo lọwọ awọn onibara rẹ, nitori ẹsin Islam kii ṣe ẹsin to maa n ni eeyan lara.

Amọ awọn eeyan miran n sọ pe ko si ohun to buru nibẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ariyanjiyan yii lo waye lẹyin iwaasu ti onimọ nipa ẹsin Islam kan ṣe ni ipinlẹ Adamawa, iyẹn Sheikh Abubakar Muktar se lori amulo ẹrọ POS.

Malamai

Oríṣun àwòrán, Malamai

Sheikh Abubakar sọ pe, ko ba ofin ẹsin Musulumi mu ki awọn oniṣowo POS maa gba ele owo lori iye owo ti wọn ba fi ranṣẹ, tabi san fun onibara wọn lati fi jere.

Bo tilẹ jẹ pe o ni kii ṣe ẹṣẹ ki awọn onile itaja igbalode lo ẹrọ POS, ti ọrọ naa si da fakinfa silẹ lori ayelujara.

Idi ree ti BBC ṣe kan si awọn onimọ ijinlẹ nipa ẹsin Islam, lati mọ ni pato ohun ti ẹsin naa sọ nipa lilo POS.

POS

Oríṣun àwòrán, Google

Agba onimọ kan, Sheikh Aminu Daurawa sọ pe lilo POS jẹ idokowo lọna to ba ofin mu, nitori naa ko si ohun to buru ninu ki eeyan jere lori owo to ba n ṣe.

O ni "ti eeyan ba fẹ lọ gba owo nile ifowopamọ, yoo na owo ko to de ibẹ, nitori naa ko buru ki eeyan san owo perete lati gba owo niwaju ile rẹ lọwọ onisowo ẹrọ POS nirọrun.

Ni ti Sheikh Bashir Aliyu Umar, to jẹ Imamu Mọṣalaṣi Al-Furqan, to tun jẹ onimọ ijinlẹ nipa ile ifowopamọ, o ni aṣiṣe nla ni ki eeyan tako lilo POS gẹgẹ bii Musulumi.

Àkọlé fídíò, LASU Best Graduating Student: Wákàtí kan péré ni mo fi ń kàwé lójúmọ́, èmi kìí ṣe igi ìwé

Sheikh Bashir sọ pe awọn oniṣowo POS jẹ aṣoju banki, nitori naa ko buru ti wọn ba n jere kekeke lori iṣẹ ti wọn n ṣe.

Nigba to n da si ọrọ naa, Sheikh Ibrahim Khali to jẹ olori ẹgbẹ awọn Musulumi ni Kano sọ pe, awọn oniṣowo POS dabi oṣiṣẹ ijọba to n gba owo oṣu ni.

O ṣalaye pe owo ti wọn n ja lori idunadura kọọkan jẹ ere wọn.

O ni "iṣoro ti a ni nilẹ yii ni pe irufẹ nnkan bayii ṣe ajoji si awọn eeyan wa, ṣugbọn ko si ohun to buru ninu ki oniṣowo POS gba owo lọwọ onibara rẹ fun iṣẹ to ṣe fun.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Sheikh Nuru Khalid, naa ṣọrọ, o ni ohun to dara ni POS jẹ nitori o mu aye dẹrun fun ọpọ eeyan, o si ti ṣe ọpọ awọn Musulumi ni anfani ti ko ṣe fẹnu sọ.