Sunday Igboho: Mo fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó jà fún ilẹ̀ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Instagram/sunday_igboho1
Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan mọ si Sunday Igboho ti ke si awọn ọmọ Yoruba lati ṣe sisẹ fun isọkan ilẹ Yoruba
Igboho lo kede bẹẹ ninu fidio kan to ṣẹyọ nibi ayẹyẹ ti wọn ti ṣe ami ẹyẹ ami ẹyẹ fawọn ogo ọmọ Yoruba, to waye niluu Ibadan.
Nibi ayẹyẹ naa ni Igboho ti sọ pe akoko ti to fun awọn ọmọ Yoruba lati parapọ sisẹ ni ọkan soso.
- Miyetti Allah ní kí wọn wọ́gilé Amotekun, Sunday Igboho yarí
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
- Sunday Igboho yarí, ó fohùn ránsẹ́ sáwọn èèyàn tó ń pẹ̀gàn rẹ̀
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- Ìlànà ‘Referendum’ nìkan la fi le gba orílẹ̀èdè Oduduwa, kìí ṣe ìwọ́de
Igboho, to tun jẹ alaga ayẹyẹ naa, sọrọ nipa idasilẹ awọn eto idagbasoke to jẹ tilẹ Kaarọ Oojire.
O ni "Awọn kan n fẹ atunto Naijiria, awọn si n fẹ iyipada orilẹede wa, ṣugbọn ni ti emi o, idagbasoke ati ominira Yoruba ni mo n fẹ, o si damiloju pe yoo ṣeṣe nitori ọdun yii jẹ tawọn ọmọ Yoruba yoo wa ni ọkan."
O fi kun pe pupọ ninu awọn eeyan to wa ni ipo to ga ju ninu ijọba to n tukọ orilẹ-ede yii lọwọ lo wa lati apa oke ọya, ti awọn ẹya to ku ko si rọwọ mu.
Igboho ni awọn kan to wa nipo agbara n lo ipo ti wọn wa lai bikita fun abo ẹmi ati dukia awọn araalu.
Ajafẹtọ ẹni naa fi kun pe "kii ṣe pe mo n ja fun ominira Yoruba nitori mo n wa ipo tabi orukọ fun ara mi, ṣugbọn mo fẹ jẹ ọkan lara awọn to ja fun isọkan ati irẹpọ Yoruba."
O ṣalaye pe awọn agbagba, awọn lọbalọba atawọn oloṣelu to lamilaaka nilẹ Yoruba to yẹ ko ja fun ominira naa ni wọn n ṣe bi pe ọrọ ọhun ko kan wọn.
Igboho wa rọ awọn ọdọ Yoruba lati duro fun isọkan ilẹ wọn, ati lati ṣetan lati sisẹ fun irẹpọ.














