Secret Cult in Ogun: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fojú afurasí ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn hàn ní Ijebu Ode

Awọn ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti safihan awọn afurasi ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun mọkanla, ti wọn lo gbẹmi awọn araalu mẹẹdọgbọn nilu Ijebu Ode nikan ati agbegbe rẹ.

Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun lo sisọ loju isẹlẹ yii lasiko to n safihan awọn afurasi ọdaran naa nibi ipadepẹlu awọn alẹnulọrọ lori eto aabo lẹkun ileesẹ ọlọpaa to wa nilu Ijebu Ode.

Ajogun ni ileesẹ ọlọpaa yoo tẹsẹ bọ sokoto kannaa pẹlu awọn ẹlẹgbẹ okunkun, to si ni awọn ti wọn se afihan wọn yii pẹlu awọn mii to si ti na papa bora, lo lọwọ ninu pipa awọn eeyan mẹẹdọgbọn naa.

Àkọlé fídíò, Itaniji: Oluwo sọ ìtàn bí Orunmila ṣe jìyà nílùú Iwo àti ayọ̀ tó gbẹ̀yìn rẹ̀ torí sùúrù

O wa n kọminu lori ija ojoojumọ to n waye nilu Ijebu Ode ati agbegbe rẹ lori ija agba laarin awọn ẹlẹgbẹ okunkun, to si fọwọ gbaya pe, ileesẹ ọlọpaa yoo kọju oro si wọn.

Bakan naa lo fikun pe ọwọ sinku ọlọpaa ti ba eeyan mẹrindinlogun, ti wọn si ba awọn ohun ija oloro lọwọ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ksmisana ọlọpa fikun pe wọn ti gbe awọn afurasi ọhun lọ sile ẹjọ lori ẹsun ipaniyan, idigunjale ati sise ẹgbẹ okunkun.

Afurasí agbébọn 47 bọ́ sọ́wọ̀ ikọ̀ 'Operation Burst' l'Oyo

Awọn ohun ija oloro

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force

Afurasi agbebọn mẹtadinlaadọta ni ọwọ sinkun ikọ digboluja Operation Burst ti tẹ nilu Igangan, nipinlẹ Oyo.

Agbarijọpọ awọn ọlọpaa, ọmọ ogun ni wọn jijọ sisẹ naa, ti wọn si ri awọn nkan ija oloro gba lọwọ awọn afunrasi yii.

Owurọ kutu ọjọ Aiku ni operation Burst ri wọn mu lẹ́gbẹ odo Ofiki loju ọna Tapa /Igangan ni ijọba ibilẹ ariwa Ibarapa nipinlẹ Oyo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin kan ti ko fidi mulẹ lo ni awọn agbegbọn naa n korajọpọ lati gbẹsan ikọlu to waye si wọn lati ọwọ ikọ Amotẹkun lagbegbe naa lọjọ Abamẹta to kọja.

Iroyin naa ni ibi ti wọn pejọ si naa ni ikọ Operation Burst ti hu gbọ nipa rẹ, to si ko gbogbo awọn agbegbọn ọhun si ahamọ.

Awọn ologun Operation Burst ninu ọkọ wọn

Oríṣun àwòrán, Oyo State Government

Amọtẹkun, ninu ọrọ rẹ ni oun ati awọn fijilate Miyetti Allah, awọn ọlọdẹ pẹlu awọn awọn mii, ni wọn dijọ se ikọlu naa eyi to wa lati mu awọn agbegbọn to n dunkooko mọ alaafia ilu.

Olugbenga Fadeyi, tii se agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fidi ọrọ yii mulẹ, to si ni awọn ti ko awọn afurasi agbebọn naa lọ si ileesẹ ọtẹlẹmuye ọlọpaa to wa ni Iyaganku fun iwadii to munadoko.

O ni ''A n tẹsiwaju pẹlu iwadii wa bo tilẹ jẹ pe awọn agbegbọn naa ni awọn n tọ pinpin awọn ajinigbe kan to fẹ gba owo lọwọ mọlẹbi eeyan ti wọn ji gbe ni''

Àkọlé fídíò, LASU Best Graduating Student: Wákàtí kan péré ni mo fi ń kàwé lójúmọ́, èmi kìí ṣe igi ìwé

Amọ sa, oludari awọn ọmọ ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Oyo, Rotimi Oluomo sọ fun ileesẹ Punch pe awọn afurasi yi gan lo ji eeyan gbe, ti awọn OPC to pẹlu Operation Burst si jẹri si ọrọ yi.

Bakan naa ni oludari OPC ni agbegbe Ibarapa sọ pe inu ọkọ bọọsi mẹta ni wọn ti mu awọn afurasi naa to digun mọra.

"Afurasi ti Àmọ̀tẹ́kùn bá lu lálù bẹ́, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ò ni gbàá sátìmọ́lé"

Oyo Amotekun:Afurasi ti Àmọ̀tẹ́kùn bá lu lálù bẹ́, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ò ni gbàá sátìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Ondo

Saaju la ti sọ fun yin pe, ní òwúrọ̀ ojó Ajé ni adarí ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn ẹka Ibadan North, Oyinwola Simeon ti sàlàyé pé, ilé iṣẹ ọlọpàá méjì kọ̀ láti gba àwọn ọdaran ti àwọn mú si agọ́ wọ́n.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lo ti sàlàyé pé, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kọ̀ láti fi àwọn ọ̀daran méjì tí àwọn mú, ti wọ́n si ka ǹkan ìjà mọ́ lọ́wọ́ lọ́jọ́ Sátidé mọ́lé.

Nínú ìfọ̀rọ̀wanilẹnuwò pẹ̀lú oníròyìn ni ọ̀gbẹ́ni Simeon ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àgọ́ ọlọ́pàá Iyaganku àti Mọkola ni wọ́n kó àwọn ọdaran náà lọ, ti wọn sì kọ̀ láti gbà wọ́n si atimole.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó ní wọ́n sàlàyé pé àwáwí tí wọ́n ń sọ ni pé, kò si ọgá kankan nitòsí láti mójú tó ọ̀rọ̀ náà.

Afurasi ti Àmọ̀tẹ́kùn bá lu lálù bẹ́, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò ni gbàá sátìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Amotekun

" A mú àwọn olè méjì ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ní ǹkan bi aago méjì lágbègbè Inálende nílùú Ibadan, lẹ́yìn àyẹ̀wò, a ri ìbọn ibílẹ̀ gba lọwọ wọn.

Wọn sì jẹ́wọ́ pé àwọn jí ǹkan tí a bá lára wọn ni, àti pé àwọn máa n jalè lágbègbè Iwo Road, Inalende ati gbogbo agbegbe rẹ̀.

Àwọn ǹkan ti a rí lára wọn ni aago ọwọ́, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlóde àti àwọn ǹkan míran."

Gẹ́gẹ́ bi alákoso náà ṣe sọ, ní kété ti wọ́n mú wọ́n tan ti wọ́n sì fọ̀rọ̀ wá wọ́n lẹ́nu wò, ni wọn mórílé àgọ́ ọlọpàá Mokọla sùgbọ́n ti àwọn ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀ kọ̀ láti gbà wọ́n.

Afurasi ti Àmọ̀tẹ́kùn bá lu lálù bẹ́, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò ni gbàá sátìmọ́lé

Oríṣun àwòrán, Oyo Affair

O ni awọn ọlọpaa naa ni kò sí DPO nílé, wọn sì ni kí wọ́n maa lọ si àgọ́ ọlọ́pàá Iyaganku.

" Bákan náà ni ńkan ti wọ́n sọ níbẹ̀, "kò sí ọgá kankan nílé, gbogbo wọn lo ti rìnrìn àjò, a ò sì le gba ẹnikẹni sí inú ọgbà wa"

Ẹ̀wẹ̀, ìwádìí BBC lọ́wọ́ agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo Olugbenga Fadeyi lórí ọ̀rọ̀ náà ló ti sàlàyé pé, ó jọ bi ẹni pé, ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kun fẹ́ràn láti máa fi àwọn oníròyin bá ọlọ́pàá jà.

Fadeyi sàlàyé pé, alábaṣiṣẹ́ pọ̀ lóyẹ ki ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn àti ọlọ́pàá jẹ́, nítorí náà, kò sí ìdí tí ọlọ́pàá yóò fi ṣe ẹsun ti wọ́n fi kan wọ́n.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Ó sàlàyé pé òun yóò túbọ̀ sàlàyé lórí ọ̀rọ̀ náà ti ìwádìí bá parí, sùgbọ́n ó fi kun pé, "àwọn Àmọ̀tẹ́kùn ń lo ìbọ̀n, kò si ni bójú mu ki wọ́n ti ṣe ọdaran léṣe tan, kí wọn wá gbé e wá si agọ́ ọlọ́pàá, kí ọ̀daràn lọ ku síbẹ̀"

Fadeyi ni "wọn kò lé gbé ọdaran tí wọ́n ti ṣe léṣé, tí o sì ti ku ẹ̀mí kan lẹ́nu rẹ̀ wá sí àgọ́ ọlọ́pàá, ọlọ́pàá ko ni gbà a, àwọn lo mọ bí wọ́n ṣe mú wọ́n, ta ló fẹjọ́ sùn wọ́n, ọlọ́pàá kìí ṣe iṣẹ́ wọn bẹ́ẹ̀"