EndSARS protest: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko pàdánù N2.5bn lẹ́yìn nǹkan bíi ọgọ́rùn ún ọjọ́ ti wọ́n ti Lekki Toll Gate pa

Toll Gate

Oríṣun àwòrán, @DeeOneAyekooto

Ko din ni biliọnu meji atabọ naira, ti ijọba ipinlẹ Eko ti padanu lati igba ti wọn ti ti iloro Lekki Toll Gate ati toll Plaza, to wa ni afara Ikoyi lati nnkan bi oṣu mẹta sẹyin.

Owo ti ijọba ọhun ti padanu lo jẹyọ nitori iye owo ti awọn iloro naa maa n pa wọle lojojumọ ati loṣoṣu, eyi ti ileeṣẹ Lekki Concesion, LCC, n ṣakoso rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Fun apẹrẹ, iloro to wa lori afara Lekki-Ikoyi yẹ ko pa owo ti ko din ni miliọnu mẹwaa naira lojumọ, nigba ti Lekki Toll Gate yẹ ko pa nnkan bii miliọnu mẹrindilogun naira lojumọ.

Lekki

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eyi to n tumọ si pe, afara Lekki-Ikoyi ti padanu nnkan bii biliọnu kan din diẹ naira, nigba ti Lekki Toll Gate ti padanu nnkan bii biliọnu kan aabọ naira.

Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin Punch ti kọkọ sọ pe, ijọba ipinlẹ Eko padanu miliọnu ojilerugba o din mẹfa naira, (N234m) laarin ọjọ mẹsan an ti iwọde EndSARS waye.

Lẹyin ti awọn janduku ja iwọde EndSARS naa gba, ni gbogbo nnkan dojuru, ṣugbọn iloro ọhun ṣi wa ni ṣiṣi.

Lẹyin rogbodiyan to tẹlẹ iwọde naa ni igbimọ oluwadii ti ijọba ipinlẹ Eko gbe kalẹ, lati ṣe ọfintoto iwa familete ki n tutọ ti wọn fi kan awọn oṣiṣẹ SARS, paṣẹ pe ki awọn iloro ọhun di titi pa titi wọn yoo fi pari iṣẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

Oludari ileeṣẹ LCC, Abayomi Omomuwa sọ fun igbimọ oluwadii naa pe, oun ko le sọ iye owo ti iloro naa ti padanu.

Ṣaaju ni agbẹjọro fun ijọba ipinlẹ Eko, Olukayode Enitan dabaa pe, ki wọn ṣi iloro naa pada fun atunṣe.

Ṣugbọn alaga igbimọ ọhun, adajọfẹyinti Doris Okuwobi sun ọrọ naa siwaju, titi di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kinni, ọdun 2021.