Ahmad Lawal: Ojúṣe olórí ni láti pèsè ààbò fáráàlú, kìí ṣe àwáwí

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, @Presidency

Aarẹ ile aṣofin agba niluu Abuja, Sẹnẹtọ Ahmad Lawan ti rọ awọn olori ni Naijiria pe, ki wọn ye ṣe awawi nipa ipenija ti wọn n doju kọ.

Sẹnẹtọ Lawan sọrọ yii nibi ayẹyẹ ranpẹ ọjọ ibi ọdun kejilelọgọta rẹ lọjọ Iṣẹgun niluu Abuja.

"Ojuṣe gbogbo awa olori ni lati wa nnkan se sí awọn ipenija to n dojuko kọ awọn ọmọ Naijiria," Lawan lo woye bẹẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ Sẹnẹtọ Lawan ni "kii ṣaaba rọrun nigba mii ṣugbọn awọn araalu maa n ro pe eremọde ni, ẹni to ba de ibẹ lo maa mọ pe ko rọrun."

Ṣugbọn aarẹ ile aṣofin agba ni ko gbọdọ si awawi kankan.

Ọkọ ijun fawọn ologun

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianarmy

Sẹnẹtọ Lawan sọ pe, oun ni igboya ninu ile igbimo aṣofin agba l'Abuja lati ṣe awọn ofin ti yoo wa ojutuu si iṣoro to n doju kọ orilẹede Naijiria.

Sẹnẹtọ Lawan ko ṣai gboṣuba fawọn aṣofin fun iṣọkan to wa laarin wọn bo tilẹ jẹ pe ọtọọtọ lẹgbẹ oṣelu wọn.

O kii wọn ku iṣẹ ribiribi ti wọn n ṣe nipa ṣiṣe ofin ti yoo mu ilọsiwaju ba Naijiria.

Gbogbo awọn sẹnẹtọ akẹgbẹ rẹ to wa nibi ayẹyẹ naa, lo ki aarẹ ile aṣofin agba ku oriire ọjọ ibi ọdun kejilelọgọta rẹ.

Ẹ́ ràgà bo ìṣọ̀kan Nàíjíríà, ìyàpà le mú ìṣẹ́ àwọn akọni wa já sásán - Osinbajo

Awọn ọmọ ogun Naijiria

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti gba gbogbo ọmọ Naijiria nimọran lati mu isọkan orilẹede yii lọkunkundun nitori ninu irẹpọ ni Naijiria ti le lagbara si.

Osinbajo, ẹni to parọwa naa ni lai fi ti ẹya, ẹsin, ẹgbẹ oselu tabi iyapa miran se, ifẹ nikan lo le gbe Naijiria ro.

Igbakeji aarẹ parọwa bẹẹ nibi akanse isin alajumọse lati bẹrẹ ọsẹ iranti awọn ologun eyi to waye lọjọ Aiku nile ijọsin National Christian Centre, nilu Abuja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Osinbajo, ti akọwe ijọba, Boss Mustapha soju fun fikun pe gbogbo orilẹede to ba ni iyapa ẹya ati ẹsin lo maa n ja fitafita lati lati jere to wa ninu iyapa wọn.

Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, @ProfOsinbajo

O wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ara wọn jin fun ifẹ ati isọkan orilẹede yii ati idagbasoke awujọ wa, lọna ati bu ọla fun awọn ologun to ti sun soju ija.

"Awọn akọni ologun to ti sun loju ija yii lo fi ẹmi wọn lelẹ fun isẹ idoola awọ nilẹ yi ati nibi gbogbo, iranti wọn si la jẹjẹ lati bọwọ fun ninu orin orilẹede wa to ni 'isẹ awọn akọni wa ko ni ja si asan.'

A seleri pe ẹjẹ wọn ti wọn ta silẹ ko ni ja si ofo, eyi si jẹ ajaga ti awọn alaaye gbọdọ maa ru kiri."

Tolulope

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Airforce

Bakan naa ni Igbakeji Aarẹ tun kọrin re ki oloogbe Tolulope Arotile, ẹni to se ise akọni losu kẹwa ọdun 2019, nigba to di obinrin akọkọ ti yoo wa baalu ijagun ninu itan idasilẹ ẹka ologun ofurufu Naijiria.

"Bi o tilẹ jẹ pe wọn ge ẹmi rẹ kuru amọ o mu ala rẹ sẹ, eyi to wa lati daabo bo isọkan naijiria, alaafia rẹ ati ipese aabo to peye.