Kafayat Sanni: Jíjẹ ọmọ ogun Nàìjíríà mú mi ṣàwárí ara mi!

Awakọ baalu ologun ofurufu

Oríṣun àwòrán, hqnigerianairforce

Àkọlé àwòrán, Awọn wọnyi ni wọn ṣẹṣẹ pari ẹkọ nipa wiwa baalu.

Lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2019 ni ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijria yoo fami ẹyẹ da awọn ọmọ awakọ baalu ofurufu mẹtala tuntun lọla.

Awọn wọnyi ni wọn ṣẹṣẹ pari ẹkọ nipa wiwa baalu.

Toun ti bi ko ti ṣe jẹ nkan tuntun pe awọn awakọ yi n gbami ẹyẹ, ohun iwuri nla kan ti yoo ṣẹlẹ nibẹ ni bi awọn awakọ baalu obinrin mẹta kan yoo ṣe fi itan lọlẹ nibẹ.

Lara wọn la ti ri Kafayat Sanni to jẹ awakọ baalu ologun ofurufu obinrin akọkọ.

Awakọ baalu ologun ofurufu

Oríṣun àwòrán, @foluoladipo

Àkọlé àwòrán, Awọn wọnyi ni wọn ṣẹṣẹ pari ẹkọ nipa wiwa baalu.

Ọmọ ọdun mejilelogun ni Kafayat Sanni ti wọn si gba a wọle si ile ẹkọ ologun NDA lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2012.

Ọdun 2019 lo pari ẹkọ rẹ ti o si di obinrin akọkọ to n wa ọkọ baalu ologun ofurufu ni Naijiria.

Kafayat ninu fọnran fidio kan ti ileeṣẹ ologun gbe sita sọ pe ohun ''fẹran lati ma a dan agbara wo laarin awọn okunrin.''

Ọmọ Sanni tun sọ pe ''Mo maa n gbiyanju lati ri bi emi naa yoo ti ṣe figagbagba pẹlu awọn ọkunrin. Jijẹ ọmọ ologun si mu mi ṣawari ara mi''

Yatọ si Kafayat awọn ọmọbinrin meji miran yoo gbami ẹyẹ lara awọn awakọ baalu mẹtala.

Awakọ baalu ologun ofurufu

Oríṣun àwòrán, hqnigerianairforce

Àkọlé àwòrán, Tolulope Arotile ninu ọkọ baalu ofurufu hẹlikọpta

Tolulope Arotile ati Grace Garba lorukọ awọn meji to ku.

Tolulope ni awakọ baalu hẹlikọpta obinrin akọkọ ti yoo jade lati ileeṣẹ ọmọ ologun Naijiria.

Bakan naa ni Grace Garba si jẹ ọmọ ogun ofurufu obinrin akọkọ ti yoo gba ipo Warrant Officer.

Àkọlé fídíò, David Adiatu oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú ìṣó àti òwú
Àkọlé fọ́nrán ohùn, Inú mi dùn pé ọmọ obinrin nìkan ni mo bi