Homosexual: Uganda yóò dá ẹ̀wọǹ gbére fún obinrin tabi okunrin tó bá fẹ́ ara wọn

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba ilẹ Uganda ti bẹrẹ igbesẹ lati gbogun ti iwa pe ki ọkunrin meji tabi obinrin meji maa fẹ arawọn.
Ẹni ti o jẹ Minisita fun eto iwa amuyẹ ni ilẹ naa,lo sọrọ igbesẹ ti wa lati mu amuto ba ofin naa ti ile ẹjọ gbegi le ni ọdun 2014.
Simon Lokodo sọ fun awọn eniyan pe ti gbogbo eto ba ti to tan, ẹwọn gbere ni fun ẹnikẹni ti ade ọrọ naa ba ṣi mọ lori.
- Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn òfegè ni pé Buhari fẹ fẹ́ Sadiya, síbẹ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣètò ìyàwò náà lórí ayélujára
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin
- Dino Melaye fìdí rẹmi, Smart borí nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn
- Olùkọ́ àgbà tó fipá bá ọmọ ọdún 13 lò yóò fojú ba ilé ẹjọ́ ni Benue
Lokodo ni wọn yoo jẹ ko ye gbogbo eniyan pe ẹnikẹni tabi eeyan keeyan to ba tasẹ agẹrẹ si ofin yii, yoo dara rẹ lẹbi ti yoo si gba idalẹbi.
Ko ṣai mẹnu baa wi pe, o jẹ ohun ajeji pata gbaa si ilẹ Uganda ki okunrin meji tabi obinrin meji maa ni ajọsepọ.
Ni ọdun 2014 ni Aarẹ Yoweri Museveni ti fọwọ si abadofin naa ṣugbọn ti ile ẹjọ ko gbaa wọle fun idi kan tabi omiran pe ki wọn pa ẹni ba dan iru rẹ wo.
- Ìbéèrè àti ìdáhùn pẹ̀lú Seyi Awolowo ti BBNaija lórí BBC Yorùbá
- Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó ran àjọ ọ̀tẹlẹ̀mùyẹ́ CIA lọ́wọ́ láti rí Bin Laden mú?
- A fẹ́ kí a máa tẹ àwọn afipábánilòpọ̀ lọ́dàá ni báyìí - Ìjọba Ekiti
- Donald Trump ní àwọn ọmọ ogun IS yi wà lára àwọn tó burù julọ nínú ìkọlù
- Ìran Yorùbá: Àṣà ju àṣà lọ!
Lokodo ti wa ṣalaye pe ofin tuntun naa ti gba ifọwọ si Aarẹ ati ọga Ọlọpaa pe wọn ti ṣetan lati fi iya jẹ iru ẹni bẹẹ ati ohunkohun to ba ṣẹlẹ lẹyin rẹ.
Pepe Julian Onziema ti o wa lati ẹya to kere ju ni ilẹ Uganda ti ṣalaye pe ẹru paapaa n ba awọn ọmọ ẹgbẹ oun ti ọpọ ẹniyan si ti salọ kuro ni ilẹ naa gẹgẹ bi atipo.
Onziema ṣalaye pe ni ọdun yii nikan, wọn ti pa ọkunrin mẹta ati obinrin kan ti wọn lọwọ ninu iru iwa yii, pe ni ọsẹ to kọja ni wọn pa ọmọkunrin kan ti o jẹbi iru ẹsun bẹẹ.
Awọn Orilẹ ede ti o tako iru iwa bẹẹ ti wọn si gba pe iku ni ere ẹṣẹ ẹni bẹẹ ni;
- Somalia
- Sudan
- Saudi Arabia
- Pakistan
- Afghanistan
- Iran
- Iraq
- Mauritania
- Qatar
- Yemen
Bakan naa ni apa ila Oorun orilẹ ede Nigeria, okuta ni wọn maa n ju pa iru ẹni ti ade ọrọ naa ba ṣi mọ lori.















