Orisabunmi: Mọ̀lẹ́bí kan ní kíì ṣe Coronavirus ló pa ẹ̀gbọ́n àti àbúró ìyá òòṣà

Orisabunmi, ẹgbọn ati aburo rẹ

Oríṣun àwòrán, Bukola Janet

Awọn agba bọ, wọn ni eti to ba gbọ alọ, o yẹ ko gbọ abọ.

Eyi lo mu ki awọn mọlẹbi akinkanju osere tiata lobinrin to di oloogbe, Folake Aremu, ti ọpọ eeyan mọ si Orisabunmi se fesi lori ọrọ to n ja rain-rain lawujọ.

Orisabunmi ẹni to jade laye lọsẹ kan sẹyin ni ẹgbọn rẹ ọkunrin ati aburo rẹ obinrin ku lẹyin rẹ, laarin ọjọ mẹta sira wọn.

Idi si ree ti awọn eeyan kan to gbọ nipa isẹlẹ naa se n pariwo pe itankalẹ arun Coronavirus lo mu ẹmi awọn alaisi mẹtẹẹta lọ.

Orisabunmi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Toyosi Adesanya

Awọn eeyan miran ni nibi ayẹyẹ kan ti Orisabunmi lọ lọjọ aisun ọdun Keresi, nibi to ti n jo ninu fidio kan to gbalẹ lori ayelujara niwaju olorin ẹmi kan, Esther Igbekele, ni osere tiata naa ti ko arun Coronavirus.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa lo ni awọn apẹrẹ aisan to se Orisabunmi to fi jade laye, ti ko si le mi daadaa ati ikọ to n hu, fi ara jọ arun Coronavirus, to si see se ko ti ko arun naa ran awọn ẹbi rẹ.

Koda, awọn eeyan miran lawujọ min tun woye pe, iku awọn eeyan naa le jẹ akufa, ti ọwọ aye si wa ninu rẹ.

Orisabunmi ati obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Instagram/themakingstv

Sugbọn nigba ti wọn n fesi lori ero awọn eeyan awujọ naa, ọkan lara ẹbi Orisabunmi salaye pe irọ to jinna sootọ ni ọrọ naa.

"Eti wa ti kun nipa awọn ahesọ ọrọ to lu igboro pa pe awọn etẹgbọn-taburo to ku ninu ẹbi wa, jade laye lati ipasẹ arun Coronavirus.

Amọ mo n mu da yin loju pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ni ahesọ ọrọ naa, yoo si dara ki awọn eeyan kọ ẹyin si.

Orisabunmi, ẹgbọn ati aburo rẹ

Ko ye mi ohun ti awọn eeyan to n tan ahesọ ọrọ naa nipa ẹbi Onisola fẹ gba nidi rẹ, nitori ilu Ibadan ni Orisabunmi ati anti Bukky, aburo rẹ ku si, nigba ti ẹgbọn wọn ku silu Ilorin."

O tun salaye siwaju si pe sababi lasan ni iku awọn mẹtẹẹta to waye lasiko kanna jẹ, kii si se arun Coronavirus lo pa wọn.

O fikun pe "awọn iku wọn kan se pẹki n pẹki ni, eyi ti kii se ohun ta n gbadura fun, a si ti n gbadura pe ki Ọlọrun dawọ iru isẹlẹ ibi bayii duro ninu ẹbi wa."

Àkọlé fídíò, LASU Best Graduating Student: Wákàtí kan péré ni mo fi ń kàwé lójúmọ́, èmi kìí ṣe igi ìwé

Bakan naa, ninu ifọrọwerọ ti BBC Yoruba se fun ajihinrere Obaloluwa Hephzibah, to jẹ ẹni to gbe lọdọ aburo Orisabunmi, o ni kii se arun Coronavirus lo mu ẹmi arabinrin Bukola Janet, tii se aburo Orisabunmi lọ.

Hephzibah, ninu ifọrọwerọ naa ni bi wọn se tufọ iku Orisabunmi fun aburo rẹ, ni irẹwẹsi ọkan ba a, ti ọkan rẹ ko si lagbara to lati gba iroyin iku ẹgbọn rẹ naa mọra.

Àkọlé fídíò, Nigeria Car Innovator: Olatunde Ibitoye ní ọdún mẹ́ta ní òun fi ṣe ọkọ̀ náà torí ọ̀dá owó

O fikun pe Bukola Janet ti n wo aisan ẹjẹ ruru tẹlẹ, ki iroyin ojiji nipa iku ẹgbọn rẹ to wọle de.