Nollywood: Ẹ fura o, ẹnìkan ti n fi orúkọ mi ṣe gbájúẹ̀ lórí ayélujára fún Kóló tí mò n tà - Tawa Ajisefinni

Tawa Ajisefini

Oríṣun àwòrán, Instagram/Tawa Ajisefini

Oṣerebinrin, Tawa Ajisefinni Alli ti ke gbajare sita lori bi eeyan kan ṣe n lu awọn onibaara rẹ ni jibiti lori ayelujara.

Ajisefinni to sọ ọrọ pẹlu ẹ̀dùn ọkan ninu fidio kan to fi si ori ayelujara Instagram rẹ sọ pe o jẹ ibanujẹ fun oun pe ẹnikan ń parọ gba owó lọwọ àwọn to fẹ ẹ ra ọja ti oun n ta.

Yatọ si pe o jẹ osere, Tawa tun n ta kóló, to jẹ apoti oni kọ́kọ́rọ́ ti ẹni to ba ra a le ma fi owo pamọ si.

Piggy bank ni wọn n pe ni ede Gẹẹsi.

Ori ayelujara Instagram si lo ti n ta a.

Ninu fidio naa, Ajisefinni sọ pe ọpọlọpọ eeyan ni ẹni naa ti fi orukọ oun gba owo kóló lọwọ wọn, lai fun wọn ni ojà ti wọn fẹ ẹ ra.

Ori ayelujara WhatsApp ni 'onijibiti' naa ti ma n ba awọn to fẹ ẹ ra Kolo sọrọ, ti yoo si fun wọn ni nọ́mbà akanti banki ti ẹ lati sanwo si.

Akiyesi ni pe nọ́mbà naa ti Tawa Ajisefinni fi sita jẹ ti orilẹ-ede America.

Sugbọn ṣa, Arabinrin Tawa ti ki awọn onibaara rẹ ni lọ, lati kọkọ ma a ba oun sọrọ l'ori Instagram tabi WhatsApp, ki wọn o to san owo lati ra kolo ti oun n ta.

Bakan naa lo tun fi oriṣiriṣi epe ati ọrọ buruku ránṣẹ si ẹni naa to fi ẹsun kan pe o fẹ ẹ ba okoowo oun jẹ.