Iwo ritual killining: Monsuru ní ọtí lòun fi owó mu lẹ́yìn tí òun bá ta ẹ̀yà ara àwọn tí òun bá pa

Ọwọ afunrasi kan ninu ahamọ

Oríṣun àwòrán, dailypost nigeria

Awọn agba bọ, wọn ni bi a ba n rin irinajo ki a wo ẹni ti a n ba lọ, nitori ati ile ati ode ni apani wa.

Iroyin nipa Monsuru Tajudeen ẹni ọgbọn ọdun kan ti ọwọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun tẹ lori ẹsun pe o n pa eniyan ti o si n ta ẹya ara wọn fawọn to n fi eniyan ṣetutu ọla.

Ilu Iwo lọwọ awọn agbofinro ti ba Monsuru ti o si jẹwọ pe eeyan meji ni oun ti pa. O ni ọrẹbinrin oun ti orukọ rẹ njẹ gan wa lara awọn eeyan ti oun ti pa.

Bakan naa, ọkan lara awọn ọrẹ, Hamzat Akeem ẹni ọdun marundinlọgbọn to jẹwọ pe oun loun tan Gafari ọkan lara awọn ọrẹ oun lọ si ile Mọnsuru nibi ti wọn ti gba ẹmi rẹ.

O ni ẹgbẹrun marun naira ni wọn fun oun ninu owo naa.

Awayewaṣere Yusuf ti o n ra awọn ori eeyan lọwọ Mọnsuru naa jẹwọ pe ẹgbẹrun lsna ogun naira ni oun maa n san fun ori kọọkan ti oun ba ra lọwọ mọnsuru lati fi ṣe etutu ọla.

Bakan naa ni Lukman Garuba, ẹni ọdun mọkanlelogbọn ti wọn mu pẹlu rẹ naa ṣalaye pe ẹya ara eeyan ni oun maa n ra lọwọ Mọnsuru ati pe ẹgbẹrun meji naira loun maa n san fun un.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Mọnsuru ni: "Ohun ti a ma n ṣe nipe a ma n fun awọn to ba ko si wa lọwọ lọrun pa ni, lẹyin ti wọn ba ti ni igbagbọ ninu wa tan.

Nigba miran, a ti ba wọn lopo tan ni alẹ, ki a to wa fun wọn ni ọrun pa ki ilẹ to mọ, ti a o si ge ara wọn si wẹlẹwẹlẹ lati lọ ta wọn."